2021
Mo Fẹ́ Tẹ̀lé Jésù
Oṣù Kẹ́ta 2021


“Mo Fẹ́ Tẹ̀le Jésù”, Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹta 2021

Àwọn ìtàn Jésù

Mo Fẹ́ Tẹ̀lé Jésù

Àwòrán
Jésù Krístì ńkọ́ni látinú ọkọ̀ ojú-omi

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ní ọjọ́ kan Jésù wọnú ọkọ̀ ojú-omi. Ó ní kí àwọn apẹja jú ù sínú omi. Ó dúró nínú ọkọ̀ ojú-omi, ó sì kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní etí-omi.

Àwòrán
Àwọn àpóstélì fa àwọ̀n tó kún fọ́fọ́ fún ẹja jáde

Lẹ́hìnnáà Jésù sọ fún apẹja kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Pétérù láti jú àwọ̀n rẹ̀ sínú omi. Pétérù ní òun kò í tì mú ẹja Kankan láti òwúrọ̀, àmọ́ òun yíò gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansí. Lákokò yí, Pétérù kó ẹja púpọ̀ tó kún ọkọ̀ ojú-omi méjì!

Àwòrán
Jésù Krístì ńkọ́ àwọn Àpóstélì

Jésù ní kí àwọn apẹja fi ọkọ̀ ojú-omi wọn sílẹ̀ kí wọ́n tẹ̀lé Òun. Ó fẹ́ kí wọ́n di ọmọlẹ́hìn Òun.

Àwòrán
Àwọn Àpóstélì ti Jésù ńṣe ìdáwọ́léni fún ìwòsàn

Àwọn Àpóstélì ńfi etísílẹ̀ bí Ó se ńìkọ́ni nipa Baba Ọ̀run. Wọ́n ńwo Jésù bí ó ti nse ìwosàn aláìsàn tí ó sì ńfi ìfẹ́ hàn sí áwọn míràn. Lẹ́hìn tí Jésù kú, àwọn ọmọlẹ́hìn se ohun tí wọ́n rí tí Jésù tiṣe. Wọ́n kọ́ni, woni sàn, wọ́n sì fì ìfẹ́hàn.

Àwòrán
Ọmọdébìnrin ntu ọmọdébìnrin tó ńsọkún nínú

Mo lè kọ́ àwọn míràn nipa Jésù nípasẹ̀ ohun tí mo bá sọ tàbí ṣe. Mo lè wo ọgbẹ́ ọkàn àwọn ènìyàn sàn pẹ̀lú ìnúrere. Mo lè sèrànwọ́ láti tọ́jú àwọn ènìyàn tí ó ṣàárẹ̀ tàbí tálàkà. Èmi ó fi ìfẹ́ hàn, bíiti Jésù.

Kíkun Ojú-ewé

Títẹ̀lé Jésù Nmú Inú Mi Dùn

Àwòrán
1 full-page b&w line art illustration based on theme "Following Jesus Makes Me Happy" A young boy shows his younger brother a picture of Jesus.

Tẹ̀