2022
Ábráhámù àti Sáràh
Oṣù Kejì (Èrèlé) 2022


“Ábráhámù àti Sáràh,” Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì Oṣù Ìkejì (Èrèlé) 2022

“Ábráhámù àti Sáràh”

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì Oṣù Kejì (Èrèlé) 2022

Ábráhámù àti Sáràh

Ábráhámù àti Sáràh nínú àgọ́ kan

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ábráhámù jẹ́ wòlíì nlá kan. Ọlọ́run dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábráhámù àti aya rẹ̀, Sarah.

Ábráhámù àti Sáràh bànújẹ́

Ọlọ́run ṣèlérí láti bùkún wọn. Ó wí fún wọn pé wọn yío bí àwọn ọmọ. Ábráhámù àti Sáràh ṣèlérí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.

Ábráhámù àti Sáràh

Ábráhámù àti Sáràh pa ìlérí wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọn kò bí àwọn ọmọ fún ìgbà pípẹ́. Wọ́n dàgbà wọ́n sì dàgbà síi.

Ábráhámù àti Sáràh pẹ̀lú ọmọ ọwọ́ Ísákì

Níkẹ̀hìn, nígbà tí Ábráhámù jẹ́ ọgọ́rùn ọdún tí Sáràh sì jẹ́ ẹni àádọ́rùn ọdún, wọ́n bí ọmọkùnrin kan. Wọ́n sọ ọ́ ní Ísákì. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ti bùkún wọn.

Ọmọ ngbìn àwọn èso

Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run. Nígbà míràn àwọn ìbùkún kìí wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa npa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́ nígbàgbogbo.

Ojú-ewé Kíkùn

Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run

ọmọ ngbàdúrà

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Báwo ni Baba Ọ̀run ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yin nígbàtí ẹ bẹ̀rù tàbí banújẹ́?