Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù “Mose àti Mánà náà” Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́rin 2022
“Mósè àti Mánà náà”
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì Oṣù Kẹ́rin 2022
Mósè àti Mánà náà
Ábráhámù jẹ́ wòlíì kan. Ó darí àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ sí ilẹ̀ ìlérí. Wọ́n rìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọjọ́.
Ebi npa àwọn ènìyàn. Wọn kò ní oúnjẹ. Nítorínà Olọ́run rán oúnjẹ sí wọn láti ọ̀run. A pèé ni mánà.
Nì òwòwúrọ̀, àwọn ènìyàn npéjọpọ̀ láti jẹ mánà. Ṣùgbọ́n kì í dúro ní titun di òru-mọ́jú. Wọn níláti kó púpọ̀ jọ si ní ọjọ́ kejì.
Mánà náà rán wa létí nípa Jesu Kristi. Ọlọ́run rán mánà láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là. Bákannáà Ó rán Jésù wá sí ayé láti gbà wá là. A nílò Jesu lójojúmọ́, gẹ́gẹ́ bí a ṣe nílò oúnjẹ lójojúmọ́.
Èmi yíò tẹ̀lé Jésù Òun yíò fún mi ní okun yíó sì rànmí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ Rẹ̀ lójojúmọ́.
© 2022 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ́ndì Oṣooṣù, Oṣù Ìkínní 2022. Yoruba 18314 779