“Jésù Wo Obìnrin kan Sàn,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2023
“Jésù Wo Obìnrin kan Sàn”
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2023
Jésù Wo Obìnrin kan Sàn
Ní ọjọ́ kan Jésù rìn lọ sí ìsàlẹ̀ òpópónà kíkún kan. Nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀-èrò ni obìnrin kan wà tí ó ti nṣàárẹ̀ fún ọdún méjìlá.
Obìnrin náà ní ìgbàgbọ́ pé Jésù lè wò ó sàn. Ó nawọ́ jáde ó si fọwọ́kan aṣọ Rẹ̀. Lọ́gán ó gba ìwòsàn!
“Tani ó fọwọ́kan aṣọ mi?” Jésù bèèrè. Ẹ̀rù ba obìrin náà. Ó kúnlẹ̀ ní iwájú Jésù ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Ún.
Jésù jẹ́ olùfẹ́ni. Ó wípé, “Tújúká.” Ó wí fún pé ó gba ìwòsàn nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Èmi lè ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Ìfẹ́ Rẹ̀ lè ràn mí lọ́wọ́ kí ó sì mú àláfíà wá fún mi.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2023. Language. 18910 779