2023
Jésù Krístì Mú Ìjì Parọ́rọ́
Oṣù Kẹ́ta 2023


“Jésù Krístì Mú Ìjì Parọ́rọ́,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2023, 46–47.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹta 2023

Jésù Krístì Mú Ìjì Parọ́rọ́

Jésù Krístì nsùn nínú ọkọ nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ nwo òkun

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ní alẹ́ kan Jésù Krístì àti àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ sọdá okun nínú ọkọ̀. O rẹ Jésù ó sì sùn lọ.

Ìjì kan nmi ọkọ̀ pẹ̀lú Jésù àti àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀

Ìjì kan wá. Ìgbì omi pọ̀si ó sì npọ̀si! Ẹ̀rù ba àwọn ọmọẹ̀hìn. Wọ́n jí Jésù dìde wọ́n sì ní kí Ó gbà wọ́n là.

Jèsù nmú òkun parọ́rọ́.

Jésù dìde dúró ó sì wípé, “Dákẹ́, jẹ́.” Afẹ́fẹ́ dúró. Omi sì parọ́rọ́

Ọmọdékùnrin ká ọwọ́ rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú ojú dídì

Ìgbàgbọ́ mi nínú Jésù Krístì lè mú àláfíà wá fún mi. Nígbàtí ẹ̀rù bá nbà mi, Jésù lè ràn mi lọ́wọ́ láti nímọ̀lára ìparọ́rọ́.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo fẹ́ràn láti kọ́ nípa Jésù

Kíkùn Ojú-ewé ti ọ̀dọ́mọdébìnrin tí ó nwo ìwé kan nípa Jésù

Ìjúwe láti ọwọ́ Patricia Geis

Kíni ẹ mọ̀ nípa Jésù?