“Oúnjẹ Olúwa Ìkínní,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹfà 2023, 46–47.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù kẹfà 2023
Àwọn Ìtàn Ìwé Mímọ́
Oúnjẹ Olúwa Ìkínní
Ṣíwájú kí Ó tó kú, Jésù Krístì pàdé pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀. Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa.
Jésù já búrẹ́dì ó sì fi fún wọn. Ó ní kí wọn jẹ ẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún wọn láti rántí pé Òun fi ẹ̀mí Rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.
Nígbànáà Jésù fún wọn ní ago kan. Ó ni kí wọ́n mu nínú rẹ̀. Yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí Rẹ̀ bákannáà.
Àní lẹ́hìn tí Jésù kò sí pẹ́lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀ mọ́, oúnjẹ Olúwa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú nípa Rẹ̀. Wọn lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ kí wọ́n sì rántí láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.
Kíkùn Ojú-ewé
Mo Lè Jẹ Oúnjẹ Olúwa
Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott
Nígbàtí mo bá jẹ́ oúnjẹ Olúwa, mo lè rántí Jésù àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún mi.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹfà 2023. Language. 19026 779