2023
Jésù fi ọ̀nà hàn wá.
Oṣù Kẹ́jọ 2023


“Jésù fi Ọ̀nà Hàn Wá,” Friend, Oṣù Kẹ́jọ 2023, 4–5.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́jọ 2023

Jésù Fi Ọ̀nà Hàn Wá.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Dan Burr

Jésù Krístì ni Ọmọ Baba Ọ̀run. Ó wá sí ilẹ̀-ayè láti fi hàn wá bí a ti lè padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run níjọ́kan. Jésù Ṣe Ìrìbọmi. Ó kọ́ni pé a níláti ṣe ìrìbọmi bákannáà.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Jésù fi bí a ó ti gbé hàn wá. Ó fẹ́ràn ó sì nran gbogbo ènìyàn lọ́wọ́. Ó nfẹ́ kí a tẹ̀lé E.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Jésù ní ìmọ̀lára gbogbo ìrora wa ó sì jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Lẹ́hìnnáà Ó kú fún wa. Èyí ni a pè ní Ètùtù Jésù Krístì. Ó ti jínde. Èyí túmọ̀ sí pé Ó wà láàyè ní òní! Nítorí Jésù Krístì, gbogbo wa yìó yè lẹ́ẹ̀kan si lẹ́hìn tí a bá kú.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Jésù ṣe gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí fún wa nítorí Ó fẹ́ràn wa. Nítorí Rẹ̀, a lè gbé pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run àti àwọn ẹbí wa níjọ́kan.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

A lè tẹ̀lé E lójojúmọ́ nípa dídi rírìbọmi. Bákannáà a lè tẹ̀lé E lójojúmọ́ nígbàtí a bá fẹ́ràn tí a sì nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ tí a sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Tẹ̀