Fríẹ́ndì
Árọ́nì Kọ́ Ọba
Oṣù Keje 2024


“Árọ́nì Kọ́ Ọba,” Fríẹ́ndì , Oṣù Kéje 2024, 26–27.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kéje 2024

Árọ́nì Kọ́ Ọba

Àwòrán
Árọ́nì nkọ́ àwọn ènìyàn; Árọ́nì ndúró ní iwájú ọba

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Árọ́nì ni ọ̀kan lára àwọn ọmọ Mòsíà. Ó jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere kan. Ó kọ́ ọba àwọn Lámánì lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

Àwòrán
Árọ́nì nsọ̀rọ̀ sí ọba

Árọ́nì bèèrè lọ́wọ́ ọba bí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ọba wípé òun ó gbàgbọ́ bí Árọ́nì bá wí fún òun pé Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́. Ó ni kí Árọ́nì wí fún òun nípa Ọlọ́run síi.

Àwòrán
Árọ́ni nkọ́ni pẹ̀lú àtilẹ̀bá ti àwọn ọ̀run.

Árọ́nì ka àwọn ìwé mímọ́ sí ọba. Ó kọ́ni nípa ìṣẹ̀dá ilẹ̀-ayé. Ó kọ́ni nípa ètò Ọlọ́run. Ó wí fún ọba nípa Jésù Krístì.

Àwòrán
Ọba àwọn ará Lámánì kúnlẹ̀; Árọ́nì nṣe ìrìbọmi fún àwọn ènìyàn.

Lẹ́hìnwá, ọba gbàdúrà. Ó bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run bí ohun tí Árọ́nì wí bá jẹ́ òtítọ́. Ọba gbà ìdáhùn pé òtítọ́ ni!

Ọba gbà ohun tí Arọ́nì kọ́ gbọ́. Gbogbo àwọn ènìyàn nínú agbogb-ilé rẹ̀ gbàgbọ́ bákannáà. Wọ́n ṣe ìrìbọmi wọ́n sì yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo Lè Tẹ̀lé Jésù nípa Fífi Ìfẹ́ Hàn

Àwòrán
Kíkùn ojú-ewé àwọn ọmọdé àti ọkàn nlá

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

Báwo ni ẹ ṣe le fi hàn pé ẹ fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn?

Tẹ̀