“Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2024, 26–27.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́jọ 2024
Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun
Àwọn ènìyàn tí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kọ́ nfẹ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Wọ́n ri àwọn ohun ìjà wọn mọ́lẹ̀ wọ́n sì ṣe ìlérí fún Ọlọ́run pé wọn kò ní jà mọ́ láéláé.
Ṣùgbọ́n láìpẹ́ wọ́n nílò láti dá ààbò bo àwọn ẹbí wọn. Àwọn baba tí wọ́n ti ri àwọn ohun ìjà wọn mọ́lẹ̀ kò fẹ́ já ìlérí wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorínáà àwọn ọmọkùnrin wọn múrasílẹ̀ láti jà ní ipò wọn. A pè wọ́n ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin jagunjagun ẹgbẹ́rún méjì. Sírípílínì túmọ̀ sí “ọ̀dọ́mọkùnrin.”
Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Jagunjagun náà kò tíì ja nínú ogun rí. Ṣùgbọ́n àwọn ìyá wọn ṣèrànwọ́ láti múra wọn sílẹ̀ wọ́n sì kọ́ wọn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run.
Wọ́n yan Hẹ́lámánì láti jẹ́ olórí wọn. Wọ́n jẹ́ olùgboyà, Ọlọ́run sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Gbogbo wọn ní ìpalára, ṣùgbọ́n wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́. Ọlọ́run ran ìgbàgbọ́ wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ye!
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2024. Yoruba. 19290 779