“Jésù Súre fún ní Ọ̀kàn sí Ọ̀kan,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹwa 2024, 26–27.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹwa 2024
Jésù Súre fún ní Ọ̀kàn sí Ọ̀kan
Àwọn Wòlíì kọ́ àwọn ará Néfì nípa àwọn àmì ikú Jésù Krístì. Nígbàtí Ó kú, òkùnkùn wà ní ilẹ̀ náà fún ọjọ́ mẹ́ta. Lẹ́hìnnáà, àwọn ènìyàn gbọ́ ohùn Baba Ọ̀run tí Ó nsọ̀rọ̀ láti ọ̀run.
Baba Ọ̀run wípé, “Ẹ kíyèsí Àyànfẹ́ Ọmọ mi” (3 Nefi 11:7). Jésù farahàn sí àwọn Ará Néfì. Ó ti jínde! Ó kọ́ àwọn ará Néfì ní àwọn ohun púpọ̀. Jésù wí fún wọn láti ronúpìwàdà kí wọ́n sì tẹ̀lé Òun.
Ó ní kí àwọn ènìyàn gbé àwọn wọnnì tí wọ́n nṣe àìsàn wá sọ̀dọ̀ Rẹ̀ láti gba ìwòsàn. Ó súre fún wọn.
Bákannáà ó súre fún gbogbo àwọn ọmọdé ní ọ̀kan sí ọ̀kàn. Àwọn ángẹ́lì yí àwọn ọmọdé ká.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹwa 2024. Yoruba. 19291 779