2022
Àwọn Bàbánlá náà: Ẹni tí Wọ́n Jẹ́ àti Ìdí Tí Ó Fi Ṣe Kókó
Oṣù Kejì (Erele) 2022


“Àwọn Bàbànlá náà: Ẹni tí Wọ́n Jẹ́ àti Ìdí tí ó fi ṣe Kókó,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejì (Erele) 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Kejì (èrèlé) 2022.

Gẹ́nẹ́sísì 11– 50

Àwọn Bàbànlá

Àwọn Ẹni tí Wọ́n Jẹ́ àti Ìdí Tí Ó Fi Ṣe Kókó

Bóyá ẹ ti gbọ́ nípa Ábráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù. A máa ń kà nípa wọn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ó sì dájú pé ẹ ó gbọ́ púpọ̀ sí i nípa wọn bí ẹ ṣe ńṣe àṣàrò Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yí. Pẹ̀lú fífi àkíyèsí púpọ̀ sí wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ pàtàkì gan, àbí? Ṣùgbọ́n ẹ lè máa bi ara yín léèrè pé, “Kí nìdí tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n gbé ayé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn fi ṣe pàtàkì ní òní?” Ó dára, kọ́kọ́rọ́ sí ìdáhùn yẹn wà nínú àwọn májẹ̀mú ayérayé àti àwọn ìlérí ìbùkún tí Ọlọ́run fún wọn.

Ábráhámù

Ábráhámù

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Jarom Vogel

Ábráhámù jẹ́ wòlíì nlá kan. Ó jẹ́ olódodo ó sì gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run.

Ó ṣe ìrìbọmi, ó gba oyèàlùfáà, a sì fi èdìdì di pẹ̀lú aya rẹ̀ Sáràh fún ayérayé.

Ọlọ́run dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábráhámù pé ìrandíran rẹ̀ yíò pọ̀ wọn yíò sì ní àwọn ìbùkún kan náà tí òun ti gbà.

Wọn yíò mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhinrere Jésù Krísti lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè ayé.

Ísákì

Ísákì

Ísákì jẹ́ ọmọ Ábráhámù àti Sáràh.

Ọlọ́run wí fún Ábráhámù kí ó fi Ísákì rúbọ. Ábráhámù ní ìfẹ́ Ísákì ṣùgbọ́n ó yàn láti gbọràn sí Ọlọ́run. Kí Ábráhámù tó fi Ísákì rúbọ, ni áńgẹ́lì kan sọ fún Ábráhámù pé kí ó dáwọ́ dúró. Ìfẹ́ Ábráhámù àti Ísákì láti gbọràn sí Ọlọ́run jẹ́ àpẹẹrẹ Ètùtù ti Ọmọ Bíbí Kan Ṣoṣo Ọlọ́run.

A ṣe ìlérí àwọn ìbùkún kannáà fún Ísákì biití Ábráhámù.

Jákọ́bù

Jákọ́bù

Gẹ́gẹ́bí baba àti baba-àgbà rẹ, Jákọ́bù jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.

Nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀, Olúwa yí orúkọ Jákọ́bù padà sí Ísráẹ́lì, tí ó túmọ̀ sí “ẹni tí ó borí pẹ̀lú Ọlọ́run” tàbí “jẹ́ kí Ọlọ́run borí” (wo Ìtumọ̀ Bíbélì, “Ísráẹ́lì”).

Jákọ́bù bí àwọn ọmọkùnrin méjìlá. Àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí àti ẹbí wọn wá di ẹni tí a mọ̀ sí ẹ̀yà Ísráẹ́lì.

Májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú Ábráhámù ni a túndá pẹ̀lú Jákọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀.

Àwọn Bàbánlá àti Ẹ̀yin

Bí ọmọ Ìjọ kan, ẹ̀yin jẹ́ ara ìrandíran Ábráhámù, Ísákì, àti Jákọ́bù . Májẹ̀mú tí wọ́n bá Ọlọ́run dá nílò sí yín!

Ẹ ni ìbùkún àti ojúṣe láti jẹ́ ẹ̀ri yín nípa Olùgbàlà àti láti pín ìhìnrere.

Bákannáà a pè yín láti pe gbogbo ènìyàn láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ kí wọ́n sì gba àwọn ìlànà oyèàlùfáà. Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ pé gbogbo èyí jẹ́ ara ìkójọ Ísráẹ́lì, èyí tí “ó jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ó nṣẹlẹ̀ ní ayé ní òní” (“Ìrètí Ísráẹ́lì,” ìfọkànsìn àwọn ọ̀dọ́ jákèjádò ayé, Oṣù Kẹ́ta, 2018], 8, ChurchofJesusChrist.org).