2022
Olùgbàlà Tó Njìyà
Oṣù Kẹrin 2022


“Olùgbàlà Tó Njìyà,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́rin 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹrin 2022

Olùgbàlà Tó Njìyà

Ọgọgọ́ọ̀rún àwọn ọdún kí Jesu tó dé, Isaiah rí ìjìyà Rẹ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ́ wa ṣíwájú.

ìkẹ́gàn àti ìkọ̀sílẹ̀

Àwòrán
A de àwọn ọwọ́ Jesu

Nígbà tí Jésù wá sí ilé-ayé, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn gbàgbọ́ nínú Rẹ̀, ṣùgbọ́n púpọ̀jùlọ kò gbàgbọ́. Wọ́n tilẹ̀ fojú kéré Rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì kórira Rẹ̀. Ní òpin rẹ̀, àwọn ènìyàn yàn láti fi ìyà jẹ Ẹ́ wọn sì paá. (Wo 1 Néfì 19:9.)

ó ti ru ìkáánú wa

Àwòrán
Jésù Kristi kúnlẹ̀ ní Gẹ́thsémánì

Jesu Kristi gba gbogbo ìnira, àìsàn àti àìlera wa sórí ara rẹ̀. Ó ṣe èyí kí ó lè ṣe àánú fún wa àti kí ó lè mọ bí yíò ṣe rànwá lọ́wọ́. (Wo Álmà 7:11–13.)

A ṣá a lọ́gbẹ́ nitori àwọn írékọjá wa

Àwòrán
Jesu Kristi lórí igi àgbélèbú

Jesu Kristi jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó ṣe èyí kí a lè rí idáríjì bí a ṣe nronúpìwàdà. (Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:11; 19:15–19.)

pẹ̀lú àwọn ìna rẹ̀ ati mú wa láradá

Àwòrán
àwọn ènìyàn ní ìmọ̀lára ọwọ́ àjínde Jésù Kristi

“Ìnà rẹ” ni àwọn ọgbẹ́ Rẹ̀. Èyí dúró fún gbogbo ìyà tí Ó ti faradà, pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀ Rẹ̀ àti ikú Rẹ̀. Nítorí Jésù Krístì jìyà fún wa, a lè di pípé lẹ́ẹ̀kan sí. Ìrúbọ Rẹ̀ mú ṣeéṣe láti ní ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Bí a ṣe nronúpìwàdà tí a sì ngbìyànjú láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Ó nwò wá sàn Ó sì nyí wa padà. (Wo Mòsíàh 3:7-11; Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:3.)

Tẹ̀