“Fìtílà sí Ẹsẹ̀ Wa,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́jọ 2022.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́jọ 2022
Fìtílà sí Ẹsẹ̀ Wa
Ohun ìwọ́pọ̀ kan fún àwọn Ará Ísráẹ́lì àtijọ́ lè kọ́ wa bí Olúwa ṣe ntọ́ wa sọ́nà.
Àwọn Òtítọ́
Ní ìgbà Májẹ̀mú Láéláé, àwọn ènìyàn nlo àwọn fìtílà òróró láti gbé ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn nínú òkùnkùn. Púpọ̀ lára àwọn fìtílà wọ̀nyí ní kókó ohun-èlò mẹ́ta:
-
Bóòlù amọ̀ kan láti di òróró ìtura mú; máa nkerè tó láti dìmú nínú àtẹ́lẹwọ́ ọwọ́ enìkan.
-
Flààsì wíìkì kan láti tànná lẹ́hìn tí ó bá ti fa òróró mu.
-
Ìdìmú kan tàbí ojú-títú láti di wíìkì mú.
Àwọn fìtílà olóòróró ìrọ̀rùn pẹ̀lú wíìkì kan lásán yíò mú ìmọ́lẹ̀ wá fún ìṣísẹ̀ díẹ̀ yíka wọn. Bí a bá lòó nígbàtí à nrìnká, wọn yíò mú ìmọ́lẹ̀ wá tó láti rí ìgbésẹ̀ níwájú ara wa kí a lè fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ rìn kiri nínú òkùnkùn.
Ohun Tí A Lè Kọ́
Ọ̀rọ̀ Olúwa lè tàn ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa nínú òkùnkùn àti ìdàmú tí ó yí wa ká nínú ayé.
Olúwa ti ní kí a máṣe bo ìmọ́lẹ̀ wa mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n kí a gbé ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere pẹ̀lú wa kí àwọn ẹlòmíràn lè ri (wo Máttéù 5:14–16).
Ó kù sí wa lọ́wọ́ láti mu dájú pé àwọn fìtílà wa kún fún òróró (wo Máttéù 25:1–13). À nṣe èyí nípa àdúrà, àṣàrò ìwé-mímọ́, iṣẹ́-ìsìn, títẹ̀lé wòlíì, àti àwọn ìṣe ìgbàgbọ́ míràn àti ìfọkànsìn (wo Spencer W. Kimball, Ìgbàgbọ́ Nṣíwájú Iṣẹ́-ìyanu [1972], 256).
Bí a bá lo ìgbàgbọ́, Olúwa nígbàmíràn nfi ìmọ́lẹ̀ sí ipa-ọ̀nà wa tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ fún wa láti gbè ìgbésẹ̀ kan si (wo Boyd K. Packer, “Àbẹ́là ti Oluwa,” Ensign, Jan. 1983, 54).
© 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́jọ 2022. Yoruba. 18316 779