2022
Ẹ Kọ́ ẹ̀kọ́ Nípa Jésù Krístì kí ẹ sì Ní Ààyè sí Agbára Rẹ̀
Oṣù Kẹsan 2022


“Ẹ Kọ́ ẹ̀kọ́ Nípa Jésù Krístì kí ẹ sì Ní Ààyè sí Agbára Rẹ̀,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹsan 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹ́san 2021.

Ẹ Kọ́ ẹ̀kọ́ Nípa Jésù Krístì kí ẹ sì Ní Ààyè sí Agbára Rẹ̀

Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan ti Oṣù Kẹ́rin 2017.

Èmi yíò fẹ́ láti ṣe àbápín a ṣe lè fa agbára Olùkọ́ni àti Olúwa wa, Jésù Krístì wá sínú ayé wa.

À nbẹ̀rẹ̀ nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀.1 “Ó ṣòrò fún [wa] láti ní ìgbàlà nínú àìmọ̀kan” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 131:6). Bí a ṣe nní òye ẹ̀kọ́ Olùgbàlà si àtì ohun tí Òun ṣe fún wa, bí a ti mọ̀ si pé Òun lè pèsè agbára tí a nílò fún ìgbé-ayé wa.

Bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a ntọ́ka sí iṣẹ́-ìránṣẹ́ Rẹ̀ bí Ètùtù Jésù Krístì, èyí tí ó mú kí àjinde jẹ́ òtítọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ó sì mú kí ìyè ayérayé ṣeéṣe fún àwọn tí wọ́n ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n sì npa àwọn ìlànà àti májẹ̀mú pàtàkì mọ́.

Lábẹ́ ètò ayérayé nlá ti Baba, Olùgbàlà ni ẹnití ó jìyà. Olùgbàlà ni ẹnití ó já àwọn ìdè ikú. Olùgbàlà ni ẹnití ó san iye fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìrékọjá wa tí ó sì nu wọ́n kúrò ní orí ipò ti ìrònúpìwàdà wa. Olùgbàlà ni ẹnití ó gbà wá là kúrò lọ́wọ́ ikú ara àti ẹ̀mí.

Àwọn gbólóhun ọ̀rọ̀ mímọ́ bí Ètùtù àti Àjínde júwe ohun tí Olùgbàlà ṣe, gẹ́gẹ́bí ètò ti Baba, kí a lè gbé pẹ̀lú ìrètí nínú ayé yí kí a sì jèrè ìyè ayérayé ní ayé tó nbọ̀.

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ẹ lè ṣe àṣàrò Ìtọ́nisọ́nà Àkòrí tàbí Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn atọ́ka Ìwé-mímọ́ fún àkọlé “Jésù Krístì” àti “Krístì Alààyè Náà: Ẹ̀rí àwọn Àpóstélì,” ChurchofJesusChrist.org.

Tẹ̀