“Njẹ́ A Nílò Láti Jẹ́ Pípé Nísisìyí?” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Ìkejì 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejì 2023
Njẹ́ A Nílò Láti Jẹ́ Pípé Nísisìyí?
Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwàá 2017 kan.
A kọ àwọn ìwé-mímọ́ láti bùkún àti láti gbà wá níyànjú, àti pé dájúdájú wọ́n nṣe èyí. Ṣùgbọ́n ṣe ẹ ti kíyèsi pé ní gbogbo ìgbà ẹsẹ kan nfarahàn tí ó nrán wa létí pe a n kùnà díẹ̀? Fún àpẹrẹ: “Nítorínáà kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ pípé, bí Baba yín … ní ọ̀run ti jẹ́ pípé” (Matteu 5:48). Pẹ̀lú òfin náà, a fẹ́ láti padà sí ibùsùn kí a sì fa àwọn ìbora sí orí wa. Irú àfojúsùn ti sẹ̀lẹ́stíà kan báyi dàbí ẹnipé ó kọjá ìnawọ́sí wa. Síbẹ̀ ó dájú pé Olúwa kò ní fún wa ní òfin kan tí Òun mọ̀ pé a kò ní lè pamọ́ láéláé.
“Bẹ́ẹ̀ni, ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì, kí a sì sọ yín di pípé nínú rẹ̀,” Moroni bẹ̀bẹ̀. “Ẹ fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè àti ipá yín, nígbànáà … nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ẹ̀yin lè di pípé nínu Krístì” (Moroni 10:32; àfikún àtẹnumọ́). Ìrètí wa kanṣoṣo fún pípé òtítọ́ wà nínú gbígbà á bí ẹ̀bùn kan láti ọ̀run—a kò lè “ṣiṣẹ́” rẹ̀.
Yàtọ̀ sí Jésù, kò tíì sí àwọn ìṣe àìlábàwọ́n nínú ìrìnàjò ilẹ̀ ayé tí à nlépa yí, nítorínáà nígbàtí a wà láyé ikú ẹ jẹ́ kí a tiraka fún ìlọsíwájú déédé kí a sì yẹra fún àwọn ìrètí púpọ̀jù nípa ti ara wa àti àwọn elòmíràn.
Bí a bá nífaradà, nígbànáà níbìkan ní ayérayé ìtúnṣe wa yíò jẹ́ ṣíṣetán àti àṣepé—èyí tí ó jẹ́ ìtumọ̀ inú Májẹ̀mú Titun nípa jíjẹ́ pípé.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejì 2023. Language. 18910 779