“Wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́ta 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹta 2023.
Wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀
Olùgbàlà npè wá láti gbé àjàgà wa lé E.
Wá sí ọ̀dọ̀ mi
A lè wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà nípa kíkọ́ ìhìnrere Rẹ̀, níní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, ríronúpìwàdà, ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́, àti títẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀.
ṣiṣẹ́ … ẹrù wúwo
Iṣẹ́ ti-ara àti àwọn ẹrù ti-ara lè mú kí ó rẹ̀ wá, ṣùgbọ́n bẹẹ́náà ni ọpọlọ, ẹ̀dùn-ọkàn, àti àwọn ti ẹ̀mí. Olùgbàlà fún wa ní àláfíà Rẹ̀, èyíówù irú àwọn ẹrù tí a lè rù.
àjàgà
Àjàgà kan ni ohun èlò fún pípa àwọn ẹranko méjì papọ̀ kí wọ́n le fa ẹrù papọ̀, bí irú ẹ̀rọ-ìtúlẹ̀ tàbí kẹ̀kẹ́ ẹrù. Àjàgà máa nní igi títàn lórí èjìká ẹranko kọ̀ọ̀kan, ní pínpín wíwúwo náà.
kẹkọ
A lè kọ́ nípa Jésù Krístì nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti àpẹrẹ Rẹ̀—àti nípa gbígbìyànjú láti tẹ̀lé wọn.
sinmi
Ìsinmi Olùgbàlà ni àláfíà Rẹ̀, èyítí ó nmú inú àti ẹ̀mí wa parọ́rọ́. Ó nràn wa lọ́wọ́ láti borí àwọn ìdàmú ti-ayé ó sì nfún wa ní okun ti-ẹ̀mí nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára àárẹ̀.
rọrùn … ìmọ́lẹ̀
Gbígba àjàgà Olùgbàlà lé orí wa túmọ̀ sí dídi arawa pọ̀ mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wa. Ó túmọ̀ sí fífi ọkàn wa fún Un àti iṣẹ́ Rẹ̀. Nígbàtí a bá ṣe èyí, àwọn ẹrù wa yíò di fífúyẹ́ nítorí Òun nràn wá lọ́wọ́.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọrọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2023. Language. 18905 779