“Gẹ́tsémánì,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2023.
Àwọn ibìkan láti inú Àwọn Ìwé-mímọ́
Gẹ́tsémánì
Kẹkọ si nípa ibi tí àwọn ìjìyà Olùgbàlà ti bẹ̀rẹ̀ ní ìtìlẹhìn wa.
Ibo Ló Wà?
Ní orí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Ólífì, ní ìlà-òrùn Jérúsálẹ́mù (ọ́wọ́ ọ̀tún nínú ìjúwé, tí a fi àmì sí nípa igi tí ìwọ̀n rẹ̀ tóbijù).
Kíni Ó Wà Níbẹ̀?
Igbó-ṣúúrú ti àwọn igi ólífì kan àti bóyá ìtẹ̀ kan fún gbígba òróró láti inú àwọn òlífì.
Kíní Ó Ṣẹlẹ̀ Nihin?
Lẹ́hin Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn, Jésù Krístì lọ pẹ̀lú mọ́kànlá nínú àwọn Àpóstẹ́lì Rẹ̀ sí Gẹ́tsémánì. Lẹ́hìnnáà Ó lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan láti gbàdúrà ó sì mú Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù pẹ̀lú Rẹ̀.
Ó “bẹ̀rẹ̀ sí ní ìyàlẹ́nú gidigidi, àti láti di rírẹ̀wẹ̀sì gan-an.” Ó wípé, “Ọkàn mi kẹ́dùn gidigidi dé ikú” (Márkù 14:33–34).
Ó gbàdúrà, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, gba ago yí lọ́wọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmí kọ́, bíkòṣe tìrẹ, ni kí a ṣe.
“Ángẹ́lì kan si yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ngbà á níyànjú.
“Bí ó sì ti wà ní ìwàyà-ìjà ó ngbàdúrà sí i kíkankíkan: òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ́ nlá, ó sì nkán sílẹ̀” (Luku 22:42–44).
Lẹ́hìn ìjìyà líle yí láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, a fi I hàn nípasẹ̀ Júdásì ó sì di mímú nípasẹ̀ àwọn olóye Júù àti ọ̀gbà àwọn ológun Rómù.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀pada ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2023. Language. 19026 779