“Nísisìyí Ni Krístì Jínde,” Fún okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹsan 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹsan 2023.
Nísisìyí Ni Krístì Jínde
Ẹ kọ́ ohun tí Àpóstélì Páùlù kọ́ni nípa Àjínde Jésù Krístì.
nísisìyi ni Krístì jínde kúrò nínú òkú
Jésù Krístì kú lórí agbelebu, a tẹ́ ẹ sí ibojì, ó sì jínde kúrò nínú òkú ní ọjọ́ kẹ́ta.
àwọn àkọ́so àwọn tí wọ́n sùn
Ọ̀rọ̀ Greek tí a lò nihin fún àwọn àkọ́so túmọ̀sí àwọn ohun ọ̀gbìn tí a tètè jáde nínú ọdún. Ó jẹ́ àkọ́kọ́ láti kórè—àkọ́kọ́ nínú púpọ̀ tó nbọ̀.
Gbólóhùn náà àwọn tí wọ́n sùn túmọ̀sí “àwọn tí wọ́n ti kú.”
Jésù Krístì ni àkọ́kọ́ láti jínde, àti pé lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀, a ó mú gbogbo ènìyàn jínde.
nípa ènìyàn ní ikú wá.
Èyí nsọ̀rọ̀ nípa Ádámù. Ìṣubú rẹ̀ túmọ̀sí pé gbogbo ènìyàn tí yíó wá sínú ayé yíò kú. (Wo Mósè 1:39.)
nínú Krístì ni a ó mú gbogbo wa wà láàyè
Nítorí Àjínde Jésù Krístì, a ó mú gbogbo ènìyàn jínde. Èyí túmọ̀sí pé gbogbo ẹni tí ó ti gbé rí tàbí tí yíò gbé láé ni a ó mú jínde. Àwọn ẹ̀mí wa yíò parapọ̀ pẹ̀lú àwọn ara wa, a ó sì sọ àwọn ara wa di pípé àti àìkú. (Wo Álmà 11:43–45.)
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padàti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹsan 2023. Language. 19047 779