Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Mò Ngbé “Irú Ìgbé Ìdùnnú bí”?
Oṣù Kejì 2024


“Mò Ngbé ‘Irú Ìgbé Ìdùnnú bí’?,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejì. 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, , Oṣù Kejì 2024

2 Néfì 9:18

Mò Ngbé “Irú Ìgbé Ìdùnnú bí”?

Nihin ni àwọn èrò díẹ̀ fún yín láti gbé ní ọ̀nà tí Néfì wípé àwọn ènìyàn rẹ̀ gbé.

ọ̀dọ́

Ìjúwe láti ọwọ́ Alyssa Gonzalez

Láìpẹ́ lẹ́hìn yíyapa kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Lámánì, Néfì wípé àwọn ènìyàn òun gbé “irú ìgbé ìdùnnú” (2 Néfì 5:27). Ní ṣíṣe àyẹ̀wò pé àwọn ẹgbẹ́ ènìyàn míràn wà tí wọ́n nfẹ́ láti pa wọ́n (wo 2 Néfì 5:1–6, 14), tí ó lè yanilẹ́nu. Báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè ní ìdùnnú lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀?

Ní àkọ́kọ̀ jùlọ, kíyèsi pé “à ngbé irú ìgbé ìdùnnú” kò túmọ̀ sí pé “gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan ará Néfì ní ìdùnnú ní gbogbo ọjọ́.” Ó túmọ̀ sí pé wọ́n ngbé ní irú ọ̀nà kan, kí wọ́n sì ṣe irú àwọn ohun, tí ó máa ndarí lọ sí ìdùnnú nígbàgbogbo. Níparí gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìpènijà wọn, ó jẹ́ ìgbà ìdùnnú.

Nítorínáà kíní “irú ìgbé ìdùnnú náà”? Báwo ni a fi lè ṣe ẹ̀dà rẹ̀ nínú ìgbé ayé ti arawa, èyí tí ó ní àwọn ìpènijà pẹ̀lú? Ẹ jẹ́ kí a wòó!

  • Ẹ jẹ́ olùgbọ́ran. “À nṣe àkíyèsí láti pa … àwọn òfin Olúwa mọ́” (2 Néfì 5:10).

    Gbígbé ìhìnrere ni Ìgbésẹ̀ kínní. Ẹ lè ní ìdùnnú ránpẹ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kò ní pẹ́. Mímọ̀ọ́mọ̀ ṣe àìgbọ́ran sí Ọlọ́run kìí ṣe “irú ìgbé ìdùnnú” (wo Álmà 41:10).

  • Ṣe àwárí àwọn ìwé mímọ́ “Èmi, Néfì, ti … mú àwọn ìwé ìrántí nì èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ wá” (2 Néfì 5:12). “A … ṣe àwárí wọn a sì ri pé wọ́n yẹ ní fífẹ́; bẹ́ẹ̀ni, àní wọ́n jẹ́ iye nlá fún wa” (1 Néfì 5:21).

    Àwọn ènìyàn Néfì ní àwọn ìwé mímọ́. Wọn kò sì ni wọn lásán—wọ́n ṣe àwárí wọn.

  • Ẹ fetísílẹ̀ sí àwọn olórí onímisi. “Èmi, Néfì, ya Jákọ́bù àti Jósẹ́fù sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ lórí … àwọn ènìyàn” (2 Néfì 5:26).

    Àwọn olùkọ́ wọ̀nyí lo àwọn ìwé-mímọ́ bí atọ́nà wọn (wo 2 Néfì 4:15; 6:4).

  • Lọ sí tẹ́mpìlì (àti àwọn ibi mímọ́ míràn). “Èmi, Néfì, kọ́ tẹ́mpìlì kan” (2 Néfì 5:16).

    Ó ṣe pàtàkì láti ní àwọn ibi mímọ́ bíi àwọn ilé ìjọsìn àti tẹ́mpìlì fún àwọn ọmọlẹ́hìn láti kórajọ àti láti sìn. (A lè lérò wípé àwọn Néfì kò kàn tẹ́mpìlì kan lásán—wọ́n lò ó lódodo.) Bí ẹ bá lè lọ sí tẹ́mpìlì fúnra yín, ẹ lè ṣe iṣẹ́ àkọọ́lẹ̀ ìtàn ẹbí nígbàgbogbo.

  • Jẹ́ aláápọn gidi. “Èmi sì kọ́ àwọn ènìyàn mi láti kọ́ àwọn ilé, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́. … [Èmi] sì mú kí àwọn ènìyàn mi jẹ́ akíkanjú, àti láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ wọn” (2 Néfì 5:15, 17).

    Apákan ti “irú ìgbé ìdùnnú” ni níní ohunkan láti ṣe! Ìyànsíṣẹ́ kan, iṣẹ́ kan, ojúṣe kan—ohunkan tí ó nfún yín ní ìfojúsùn àti èrèdí (pẹ̀lú àkokò tótọ́ láti simi, bẹ́ẹ̀ni). Ó nira láti ní ìdùnnú bí ó bá nrẹ̀ yín nígbogbo ìgbà.

Ṣe ẹ̀yín yíò wípé ẹ̀ ngbé lọ́wọ́lọ́wọ́ ní irú ìgbé ìdùnnú? Bí bẹ́ kọ́, bóyá àpẹrẹ Néfì lè fún yín ní àwọn èrò díẹ̀ nípa bí ẹ̀ ó ti gbèrú si.