Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Kí Ni Ohun Tí A Ṣe Ìlérí Rẹ̀ Gan Nígbàtí A Ṣe Ìríbọmi?
Oṣù Kẹfà 2024


“Kí ni ohun tí a ṣe ìlérí rẹ̀ gan nígbàtí a ṣe ìríbọmi?,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹfà 2024.

Kí ni ohun tí a ṣe ìlérí rẹ̀ gan nígbàtí a ṣe ìríbọmi?

ìrìbọmi

Ìrìbọmi, láti ọwọ́ Annie Henrie Nader

Àwọn ìwé-mímọ́ kọ́ wa pé nígbàtí a bá ṣe ìrìbọmi, a dá májẹ̀mú (tàbí ṣe ìlérí) láti fi ìfẹ́ gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wa, sin Ọlọ́run, kí a sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ (wo Mòsíà 18:10; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mu 20:37, 77).

Bákannáà a kọ́ nínú àwọn ìwé-mímọ́ pé ìrìbọmi nràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ wa “láti wà sínú agbo Ọlọ̀run, kí a sì pè yín ní ènìyàn rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ” (Mòsíà 18:8). Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, èrèdí kan tí a fi nṣe ìrìbọmi ni pé a fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ Ìjọ Jésù Krístì kí a sì gbádùn ìfẹ́ àti wíwàpẹ̀lú tí ó nwá látinú wíwà ní ìrẹ́pọ̀ nínú Krístì.

Ìfarasìn láti sin Olúwa àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ lẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ohun púpọ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Nígbàtí a bá ṣe ìrìbọmi, a ṣe ìlérí láti “ṣetán láti fi ara da ìnira ara yín, … sọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀; bẹ́ẹ̀ni, tu àwọn tí ó fẹ́ ìtùnú nínú, àti láti dúró gẹgẹbí àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti nibi gbogbo” (Mòsíà 18:9