Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ, nihin ni ìdí tí ẹ kò níláti jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Kíni ohun tí ẹ̀ nbẹ̀rù fún? Onírurú ìgbòkègbodò? Kílásì Ìṣiró? Gbígbìyànjú láti ní òye Ìsàíàh?
Báwo ni ti ìrònúpìwàdà? Bí èrò ríronúpìwàdà bá mu yín fẹ́ láti sápamọ́ sí abẹ́ àwọn ìbora yín tàbí ẹ̀ njẹ ṣokoléètì púpọ̀ jù, àtẹ̀kọ yí wà fún yín.
“Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe bẹ̀rù tàbí sún ìrònúpìwàdà síwájú,” ni Ààrẹ Russell M. Nelson wí. Àti pẹ̀lú èrèdí rere. Nihin ni àwọn ohun díẹ̀ tí ìrònúpìwàdà jẹ́ àti tí kò jẹ́, gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ti sọ.
Ẹ tẹ́wọ́gba Ẹ̀bùn Pípé Ọlọ́run
Nítorínáà, njẹ́ ẹ ṣetán láti gbẹ́kẹ̀lé Olùgbàlà láti borí ẹ̀rù ìrònúpìwàdà yín? Ẹ kò ní kabamọ rẹ̀.
Ààrẹ Nelson wípé: “Nítorípé ayé nílò gbígbàlà, àti nítorípé ẹ̀yin àti èmi nílò gbígbàlà, [Baba Ọ̀run] rán Olùgbàlà kan sí wá.
“… Ẹ jẹ́ kí a tẹ́wọ́gba ẹ̀bùn pípé àti iyebíye ti Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn àjàgà àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ibi ẹsẹ̀ Olùgbàlà kí a sì ní ìrírí ayọ̀ tí ó nwá láti inú ìrònúpìwàdà àti ìyípadà.”