Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kejìlá 2024
Ìbí Náà
Kẹkọ nípa dídámọ̀ ìran Kérésìmesì yí àti bí ó ti nrànwálọ́wọ́ láti fojúsùn sí Olùgbàlà.
Bẹ́thlẹ́hẹ́mù
Bẹ́thlẹ́hẹ́mù túmọ̀ sí “ilé búrẹ́dì” ní Hébérù. A máa npè é ní ìlú Dáfídì nígbàmíràn, látinú ìrandíran ẹnití a ti sọtẹ́lẹ̀ pé Mèsíàh níláti wá (wo Jeremiah 23:5; Jòhánnù 7:42). Sámúẹ́lì fi àmì òróró yan ọba Dafídì ní Bẹ́thlẹ́hẹ́mù (wo 1 Sámúẹ́lì 16:1–13). A ti sọ̀tẹ̀lẹ̀ pé a ó bí Mèsíàh níbẹ̀ (wo Micah 5:2).
Ilé-ìgbàlejò
Ọ̀rọ̀ Greek fún ilé-ìgbàlejò lè túmọ̀sí ibùgbé ránpẹ́, pẹ̀lú yàrá àlejò. Màríà “tẹ́ [Krístì Ọmọ náà] sílẹ̀ ní ibùjẹ-ẹran; nítorí kò sí yárá kankan fún wọn ní inú ilé-ìgbàlejò” (Lúkù 2:7). (Ìyírọ̀padà-èdè ti Joseph Smith wípé “àwọn ilé-ìgbàlejò.”) “Kò sí yàrá kankan” lè túmọ̀ sí pé a dá wọn padà tàbí pé kò sí ibi tí wọ́n ìbá ti lè dúró sí tí ó ní àyè láti gba ẹ̀bí ọmọ-ọwọ́ kan. Ní ọ̀nàkọnà, wọ́n lọ sí ibìkan níbití ibùjẹ-ẹran kan wà.
Ibùjẹ-ẹran
Ibùjẹ-ẹran kan ni àpòtí gíga tàbí ibi-ìmumi tí ó ndi oúnjẹ mú fún àwọn ẹran. Ní Jùdéà àtijọ́, ìwọ̀nyí ni a ṣe púpọ̀jùlọ pẹ̀lú òkúta. Àwọn ilé-ìgbàlejò ní gbúngbun ẹ̀hìnkùnlé pẹ̀lú ibùjẹ-ẹran, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé bákannáà tí ó ní àwọn ibùjẹ́-ẹran ní yàrá títóbi gan an kí a lè pa àwọn ẹranko mọ́ mọ́jú níbẹ̀.
Àwọn Aṣọ Yíyímọ́ra
Àwọn ìyá tí nyí aṣọ mọ́ ọmọ-titun lára (yíyí wọn mọ́ inú ìbora tàbí aṣọ) fún ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún. Èyí nmú wọn dákẹ́ ó sì ntù wọ́n lára lẹ́hìn ìjayà fífi ilé-ọmọ wọn sílẹ̀. Aṣọ èyí tí Màríà lò lè ti ní àmì pàtàkì kan tí kò láfiwé sí ẹbí náà.
Màríà àti Jósẹ́fù
Wọ́n jẹ́ ènìyàn rere àti olódodo, àwọn méjèjì sì jẹ́ àtẹ̀lé Dáfídì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ti gba íbẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ ángẹ́lì ní ìmúrasílẹ̀ fún ìbí Olùgbàlà (wo Máttéù 1:18–25; Lúkù 1:26–38). Wọ́n rin ìrìnàjò ọgọrun sí ogoje kilómítà (ọgọ́ta sí aadọwa máìlì) sí Bẹ́thlẹ́hẹ́mù. Màríà wà nínú oyún nínú ìrìnàjò náà.
Àwọn Olùṣọ́-àgùtàn
Àwọn olùṣọ́-àgùtàn nṣètójú àwọn ẹran wọn nítòsí Bẹ́thlẹ́hẹ́mù. Ní ìbámu sí àwọn ọ̀kàwé kan, àwọn àgùtàn tí ó yẹ fún ìrúbọ tẹ́mpìlì ni a fi àyè gba kí a tọ́ nítòsí ìlú náà. Nítorínáà àwọn olùṣọ́-àgùtàn wọ̀nyí lè ti ṣètọ́jú àwọn àgùtàn náà tí yíò ṣe aṣojú ìrúbọ Jésù Krístì fún wa (wo Mósè 5:6–7). Wọ́n fi àwọn agbo-ẹran wọn sílẹ̀ láti rí Mèsíàh, ẹnití ìrúbọ ètùtù rẹ̀ yíò mú ìrúbọ pẹ̀lú àwọn àwọn ẹrànko kúrò.
Krístì Ọmọ Náà
Jésù Krístì ni gbùngbun àwòrán ti ìran Ìṣẹ̀dá—àti ìgbésí-ayé wa.
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹjìlá 2024. Yoruba. 19346 779