Ọ̀rọ̀ Ìkíni Káàbọ̀
Ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò àti sí ànfàní láti gbọ́ ohùn Olúwa.
Ẹ̀yin arákùnrin, arábìnrin, àti ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n káàkiri àgbáyé, mo fi ìkíni káàbọ̀ araẹni mi sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí fún yín. A kórajọ bí ẹbí nlá àgbáyé ní ìfẹ́ láti jọ́sìn Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. E ṣe fún dídarapọ̀ mọ́ wá.
Ọdún tó kọjá yí jẹ́ ọkàn fún àwọn ìwé àkọsílẹ̀. Kò sí iyèméjì pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ti kọ́ àwọn ohun tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ tí mo ti mọ̀ ṣíwájú ni a ti kọ́ sí ọkàn mi ní àwọn ọ̀nà titun àti ìkọ́ni.
Fún àpẹrẹ, mo mọ̀ dájú pé Olúwa ndarí àwọn ètò Ìjọ Rẹ̀. Ó wípé, “Èmi yíò fi hàn [yín] pé èmi lè ṣe iṣẹ́ ara mi.”1
Nígbàkugbà, awọn olùdámọ̀ràn mi àti èmi ti wo nípasẹ̀ omije ojú kíkú bí Ó ti dásí nínú àwọn ipò ìpènijà líle lẹ́hìn tí a ti sa ipá wa tí a kò lè ṣe ohunkóhun mọ́. A dùró ní gbogbo ìyanu nítòótọ́.
Bákannáà mo ní òye dídára si nisisìyí ohun tí ó túmọ̀ sí nígbàtí ó wípé, “Kíyèsi, Èmi yíò yára síṣẹ́ mi ní àkokò rẹ̀.”2 Lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi mo ti láyọ̀ bí Ó ti ndarí tí ó sì nṣe ìyára sí Iṣẹ́ Rẹ̀—àní ní ìgbà àjàkàlẹ̀ àrùn.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, okun Ìjọ dálé àwọn ìtiraka àti àwọn ẹ̀rí ọmọ ìjọ tí ó ndàgbà si títí. Àwọn ẹ̀rí ni a ntọ́jú jùlọ ní ilé. Ní ọdún tó kọjá yí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ti ní àlékún àṣàrò ihìnrere si kíákíá nínú ilé yín. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, àti pé àwọn ọmọ yín yíò dúpẹ́ lọ́wọ́ yín.
Iṣẹ́ títóbi láti tun Tẹ́mpìlì Salt Lake ṣe ntẹ̀síwájú. Láti ibi-iṣẹ́ mi mo ní ijoko ilà-iwájú láti wo iṣẹ́ tó nlọ ní plásà tẹ́mpìlì.
Bí mo ti nwo àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ngbẹ́ gbòngbò igi àtijọ́ jáde, páìpù omi, síso iná, àti orísun omi tó njò, mo ti ronú lórí ìnilò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa mú, àwọn ìdọ̀tí àtijọ́ nínú ayé wa, kúrò pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà.
Ìhìnrere Jésù Krístì ni ìhìnrere ìrònúpìwàdà.3 Nítorí Ètùtù Olùgbàlà, ìhìnrere Rẹ̀ pèsè ìfipè kan láti pa ìyípadà, ìdàgbà, àti dída mímọ́ si mọ́. Ìhìnrere ìrètí, ìwòsàn, àti ìlọsíwájú ni. Báyìí, ìhìnrere ni ọ̀rọ̀ ayọ̀kan! Àwọn ẹ̀mí wa yayọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìṣìsẹ̀ kékèké tí a gbé síwájú.
Ara ìkórajọ Ísráẹ́lì àti ara pàtàkì gan, ni àṣẹ fún wa bí ènìyàn kan láti jẹ́ yíyẹ àti fífẹ́ láti ṣèrànwọ́ ní mímúra ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa.
Bí a ṣe nfetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ múrasílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn olórí wa lábẹ́ ìdarí Ẹ̀mí Mímọ́, mo pè yín láti gbàdúrà láti dá àwọn ìdọ̀tí tí ẹ níláti mú kúrò nínú ayé yín mọ̀ kí ẹ lè di yíyẹ si.
Mo ní ìfẹ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo jẹri pé Baba wa Ọ̀run àti Olólùfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ mọ̀ wọ́n sì nifẹ yín níkọ̀ọ̀kan. Wọ́n ṣetán ní ìdúró láti ti yín lẹ́hìn ní gbogbo ìṣísẹ̀ tí ẹ gbé síwájú. Ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò àti sí ànfàní láti gbọ́ ohùn Olúwa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.