2014
Di Ìwọ Fúnraàrẹ Dídára Jùlọ— Bíbẹ̀rẹ̀ Nísinsìnyí
Oṣù Kínní Ọdún 2014


Ọ̀dọ́

Di Ìwọ Fúnraàrẹ Dídára Jùlọ—Bíbẹ̀rẹ̀ Nísinsìnyí

Ààrẹ Uchtdorf kọ́ni pé “awọn ìlépa ti ara ẹni le mú dídára jùlọ tí ó wà nínú wa jáde wá.” Ronú nipa títo awọn ìlépa díẹ̀ kalẹ̀ ninu awọn agbègbè méjì tàbí mẹ́ta ti ìgbé ayé rẹ, bí irú ìlera nipa ti ara, ìlera nipa tí ẹ̀mí, ati awọn ọ̀rẹ́ dídá, fún àpẹrẹ. Awọn àṣeyọrí wo ni ìwọ yío fẹ́ lati ní nínú awọn agbègbè wọ̀nyí ní ọdún yĩ? Bí o ṣe ń fi tàdúrà tàdúrà ronú nipa awọn ìlépa díẹ̀, rĩ dájú pé wọ́n jẹ́ ohun tí ó ṣẽṣe ṣùgbọ́n tí yío nílo pé kí o dàgbà. Nínú ìwé àkọpamọ́ rẹ, ṣe àpéjúwe awọn ìlépa rẹ ní àsọyé kí o le baà rí ìtẹ̀síwájú rẹ nígbàtí ọdún kan bá kọjá.