2014
Àkókò tí ó Dára Jùlọ lati Gbin Igi kan
Oṣù Kínní Ọdún 2014


Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kínní 2014

Àkókò tí ó Dára Jùlọ lati Gbin Igi kan

Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf

Ní Rómù àtijọ́, Janus jẹ́ ọlọrun awọn ìbẹ̀rẹ̀. Wọn mã ń sãbà ṣe àpèjúwe rẹ̀ pẹ̀lú ìwò ojú méjì—ìkan ńwo ẹ̀hìn sí ohun tí ó ti kọjá, ìkan yõkù ńwo ọ̀kánkán sí ọjọ́ iwájú. Àwọn èdè díẹ̀ sọ orúkọ oṣù kínní ní àpèmọ́ rẹ̀ nítorípé ìbẹ̀rẹ̀ ọdún jẹ́ àkókò fún ìronúsẹ́hìn bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni ó sì jẹ́ ti ìpalẹ̀mọ́.

Ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ọdún lẹ́hìnnáà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ìṣẹ̀dálẹ̀ jákèjádò àgbáyé gbé àṣà ṣíṣe awọn ìpinnu fún ọdún tuntun tẹ̀síwájú. Dájúdájú, ṣíṣe awọn ìpinnu rọrùn—pípa wọn mọ́ jẹ́ ohun tí ó yàtọ̀ ju gbogbo rẹ̀ lọ.

Ọkùnrin kan ẹnití ó ti ṣe ìtòlẹ́sẹ̃sẹ gígùn ti awọn ìpinnu Ọdún Titun ní ìmọ̀lára rírẹwà dáradára nipa ìtẹ̀síwájú rẹ̀. Ó ronú si ara rẹ̀, “Titi di ìsinsìnyí, mo ti jẹ ohun tí ó yẹ nìkan, emi kò tĩ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mú mi bínú, mo ti pa ètò ìṣúna mi mọ́, emi kò sì tĩ ráhùn nipa ajá aládũgbò mi. Ṣùgbọ́n òní ni ọjọ́ kejì oṣù kínní ati pé àlãmù ṣẹ̀ṣẹ̀ dákẹ́ ni àkókò yí nì fúnmi lati dìde kúrò lórí ibùsùn. Yío gba iṣẹ́ ìyanu lati le jẹ́ kí nmã bá ìlàsílẹ̀ mi lọ.”

Bíbẹ̀rẹ̀ Ní Àkọ̀tun

Ohun kan wà bi irọ ṣugbọn ti ó ní ìrètí nípa àkọ̀tun ìbẹ̀rẹ̀. Mo wòye pé ní ìgbà kan tàbí òmíràn gbogbo wa ti fẹ́ lati tún bẹ̀rẹ̀ ní àkọ̀tun pẹ̀lú àlàsílẹ̀ tí ó mọ́.

Mo mã ń fẹ́ràn lati ní ẹ̀rọ kọ̀mpútà tuntun pẹlu líle agbára inú rẹ̀ kan tí ó mọ́. Fún ìgbà kan yío ṣe iṣẹ́ dáradára. Ṣugbọn bi awọn ọjọ́ ati awọn ọ̀sẹ̀ ṣe ń kọjá tí a sì n fi púpọ̀ ati púpọ̀ síi awọn ìlànà iṣẹ́ sí inú rẹ̀ (díẹ a jẹ́ àmọ̃mọ̀ ṣe, díẹ̀ a sì jẹ́ èyítí a kò fi bẹ̃ mọ̃mọ̀ ṣe), ní ìgbẹ̀hìn kọ̀mpútà náà á bẹ̀rẹ̀ sí dára dúró, awọn ohun tí ó ti mã ńṣe ní kíákíá ati dáradára á di pẹ̀lú ìlọ́ra. Nígbà míràn kìí ṣiṣẹ́ rárá. Àní jíjẹ́ kí ó bẹ̀rẹ̀ le di iṣẹ́ kan bí líle agbára inú rẹ̀ ṣe di ìdàrúdàpọ̀ pẹlú awọn oríṣiríṣi awọn àìlétò ati awọn pàntí ohun èlò tí nlo iná. Awọn ìgbà míràn wà tí ó jẹ́ pé ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo ni lati tún inú kọ̀mpútà náà ṣe kí ó sì bẹ̀rẹ̀ ní àkọ̀tun.

Bákannáà awọn ènìyàn le di ìdàrúdàpọ̀ pẹlú awọn ẹ̀rù, awọn ìyèméjì, ati ẹ̀bi wíwúwo. Awọn àṣìṣe tí a ti ṣe (èyítí a mọ̃mọ̀ ati èyítí a kò mọ̃mọ̀) le wọ̀n lórí wa títí tí yíó fi dàbí ẹnipé ó le lati ṣe ohun ti a mọ̀ pé a níláti ṣe.

Nípa ti ẹ̀ṣẹ̀, ìlànà àtúnṣe ìyanu kan wà tí a npè ní ìrònúpìwàdà èyìtì ó ń gbàwá lãyè lati palẹ̀mọ́ awọn líle inú wa kúrò lọ́wọ́ ìdàrúdàpọ̀ tí ó ndá ẹrù pa awọn ọkàn wa. Ìhìnrere, nípasẹ̀ Ètùtù Ẹ̀ṣẹ̀ ti Jésù Krístì tí ó jẹ́ oníyanu ati alãnú, fi ọ̀nà hàn wá lati wẹ awọn ọkàn wa mọ́ kúrò lọ́wọ́ àbàwọn ẹ̀ṣẹ̀ ati pé lẹ́ẹ̀kansĩ kí a di titun, àìlábùkù, ati àìlẹ́bi bĩ ọmọ kékeré.

Ṣùgbọn nígbà míràn awọn ohun míràn a mã mú wa lọ́ra ati fà wá sẹ́hìn, tí ó mã ń fa awọn ìrònú àìlérè ati awọn ìgbésẹ̀ tí ó mã ń jẹ́ kí ó le fún wa lati bẹ̀rẹ̀.

Mímú Dídárajùlọ inú Wa Jáde

Ṣíṣe ìlàsílẹ̀ awọn ìlépa jẹ́ àdáwọ́lé kan tí ó yẹ. A mọ̀ pé Bàbá wa Ọ̀run ní awọn ìlépa nitorípé Ó ti sọ fún wa pé iṣẹ́ Rẹ̀ ati ògo ni “lati jẹ́kí àìkú ati ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ” (Moses 1:39).

Awọn ìlépa ti ara wa le mú dídárajùlọ inú wa jade. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ̃, ìkan nínú awọn ohun tí ó mã ń mú awọn akitiyan wa bàjẹ́ nínú ṣíṣe ati pípa awọn ìpinnu mọ́ ni sísún àtiṣe síwájú. Nígbàmíràn a mã ńṣe ìdádúróo bíbẹ̀rẹ̀, ní dídúró fun àkókò tí ó tọ́ lati bẹ̀rẹ̀—ọjọ́ kìnní nínú ọdún tuntun, ìbẹ̀rẹ̀ ti ìgbà ooru, nígbàtí wọ́n bá pè wá bĩ bíṣọ́pù tàbí ààrẹ Ẹgbẹ́ Arannilọ́wọ́, lẹ́hìn tí awọn ọmọ bá wọ ilé ìwé, lẹ́hìn tí a bá fẹ̀hìn tì.

Ẹ kò nílò ìfìwépè kan kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sísún sí ìhà ọ̀nà awọn ìlépa ti òdodo yin. Ẹ kò nílò lati dúró fún ìyọ̀nda lati di ẹni náà tí a ti gbèrò yin lati jẹ́. Ẹ kò nílò lati dúró kí a pè yin lati sìn nínú Ijọ.

Nígbà míràn a le sọ awọn ọdún nù ninu ìgbé ayé wa ní dídúró lati jẹ́ yíyàn (see D&C 121:34–36). Ṣùgbọ́n èyíinì jẹ́ ayédèrú ìpìlẹ̀. A ti yàn ọ́ ná!

Ní awọn akókò kan ní ìgbé ayé mi mo ti lo awọn òru ní àìlesùn ní títiraka pẹ̀lú awọn kókó ọ̀rọ̀ kan, awọn àìdánilójú, tàbí awọn ìbànújẹ́ ti ara ẹni. Ṣùgbọ́n bí òru nã ti wù kí ó dúdú tó, nígbà gbogbo ni mo mã nní ìgbìyànjú nipa ìrònú yĩ: ní òwúrọ̀ õrùn yío yọ.

Pẹ̀lú olukúlùkù ọjọ́ tuntun, ìtànsán õrùn tuntun mã ńwá— kìí ṣe fún ilẹ̀ ayé nìkan ṣùgbọ́n fún wa bákannáà. Ati pẹ̀lú ọjọ́ tuntun kan ni ìbẹ̀rẹ̀ tuntun mã ńwá— ànfãní lati tún bẹ̀rẹ̀ lẹ̃kansíi.

Ṣùgbọn Bí A Bá Kùnà Nkọ́?

Nígbà míràn ohun tí ó mã ń fà wá sẹ́hìn ni ẹ̀rù. Ẹ̀rù lè mã ba wá pé a kò ní ṣe àṣeyọrí, pé a ó ṣe àṣeyọrí, pé wọn lè dójú tì wá, pé àṣeyọrí le tún wa ṣe yàtọ̀, tàbí pé ó lè tún awọn ènìyàn tí a nífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀.

Àti pé nitorinã a mã ndúró. Tàbí kí a pa á tì

Ohun míràn tí a nílò lati rántí nigbati ó bá kan títò lẹ́sẹ̃sẹ awọn ìlépa nìyí: Ó fẹ́rẹ̀ dájú pé a ó kùnà— ó kéré jù nínú àsìkò kúkúrú. Ṣùgbọ́n dípò kí á rẹ̀wẹ̀sì, a lè di ríró ní agbára nitoripé níní òye èyí yío mú ìṣòro dídi pípé ní ìsisìnyí gan an kúrò. Ó gbã wọlé lati ìbẹ̀rẹ̀ pé ní ìgbà kan tàbí òmíràn, ó ṣẽṣe kí á ní ìkùnà. Mímọ̀ eléyĩ ṣãjú ń mú púpọ̀ nínú ìyàlẹ́nu ati ìrẹ̀wẹ̀sì ti ìjákulẹ̀ kúrò.

Nigbati a bá súnmọ́ awọn ìlépa wa ní ọ̀nà yí, ìjákulẹ̀ kò nílati dá ìwọ̀n wa. Ẹ rántí, àní bí a bá kùnà lati dé òpin, ibi tí a fẹ́ nínú ìlépa wa ní ojú ẹsẹ̀, a ó ti ní ìtẹ̀síwájú ní ojú ọ̀nà tí yío tọ́ni lọ sí ibẹ.

Ati pé èyínì ṣe pàtàkì—ó ní ìtùmọ̀ púpọ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣẽṣe kí á kùnà lati dé ìlà ìpárí wa, kí a kàn tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò náà lè sọ wá di ńlá jù bí a ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ.

Àkókò tí ó Dára Jùlọ lati Bẹ̀rẹ̀ Ni Ìsinsìnyí

Àgbà òwe kan sọ pé, “Àkókò tí ó dára jùlọ lati gbin igi kan ni ogún ọdún sẹ́hìn. Àkókò tí ó dára jùlọ ṣìkejì ni ìsisìnyí.”

Ohun kan wà tí ó kún fún ìyanu ati ìrètí nipa ọ̀rọ̀ náà ìsisìnyí. Ohun kan wà tí ó róni ní agbára nipa òótọ́ pé bí a bá yàn lati pinnu nísisìnyí, a lè sún síwájú ní ìṣẹ́jú yìí gan an.

Ìsisìnyí ni àkókò tí ó dára jùlọ lati bẹ̀rẹ̀ dídi irú ẹni náà tí a fẹ́ lati dà ní ogún ọdún sí ìsisìnyí nìkan kọ́ ṣùgbọn fún gbogbo ayérayé bákannáà.

Ìdánilẹ́kọ́ láti Iṣẹ́ Yìí

Ààrẹ Uchtdorf ṣe àlàyé pé nigbatí a bá kùnà lati dé ibi awọn ìlépa wa, “a lè di ríró ní agbára. … Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣẽṣe kí á kùnà lati dé ìlà ìpárí wa, kí a kàn tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò náà lè sọ wá di ńlá jù bí a ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ.” Béèrè lọwọ awọn mọlẹ́bí lati ṣe àbápín awọn ìrírí nínú èyítí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ síi lati inú ìlànà ìṣe ju bí wọ́n ṣe kọ́ ẹ̀kọ́ lati ara àyọrísí, bí irú ṣíṣe àṣeyọrí lati ilé ìwé tàbí gbígba àmì ẹ̀yẹ kan.