Àwọn Ọmọdé
Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ̀rí yín Jó Mímọ́lẹ̀
Jíjèrè Ẹ̀rí kan dàbíi kíkó iná kan jọ. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe níláti ṣe àfikún igi láti mú kí iná máa jó, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà, ronúpìwàdà, sin àwọn ẹlòmíràn, ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, kí a sì pa àwọn òfin mọ́ láti ran ẹ̀rí wa lọ́wọ́ láti mọ́lẹ̀.
Láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa bí ẹ ṣe lè kó ẹ̀rí yín jọ, ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé mímọ́ tí a kọ sísàlẹ̀ yìí. Ya iná kan pẹ̀lú ọ̀wọ́ iná nlá márún. Kùn ní ọ̀wọ́ iná kan fún gbogbo ìwé mímọ́ tí ó bá ka. Bí ìwé mímọ́ tí ẹ kà bá ṣe pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ni iná yín yíò ṣe mọ́lẹ̀ tó—àti ẹ̀rí yín!