Ọ̀dọ́
Yíyípadà ti Ọkàn Mi
Olùkọ̀wé náà ńgbé ní Fortaleza, Brazil
Nígbàtí mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì, mo ní ìmọ̀lọ́kàn Ẹ̀mí tó jẹ́rí nípa ti òtítọ́ rẹ̀. Nípa àdúrà, àní ẹ̀rí mi di dídájú si, mò sì gbèrò láti ṣe ìrìbọmi.
Láìpẹ́ lẹ́hìn ìrìbọmi mi, àwọn ènìyàn wọ́ọ̀dù mi bẹ̀rẹ̀ sí ńbèèrè lọ́wọ́ mi bí mo ṣe ní ìmọ̀lọ́kàn nipa sísìn ní míṣọ̀n. Láti jẹ́ olódodo, èmi kò mọ ohun pàtó tí mo lè sọ. Èrò ti fífi ẹbí mi sílẹ̀ àti ilé ìwé láti lọ sìn ní míṣọ̀n kan dàbíi ohun àjèjì.
Nígbànáà ní ọjọ́ kan mo bẹ̀rẹ̀ sí ńronu nípa ìyípadà mi. Mo ránti àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ tí wọ́n ti kọ́ mi, tí wọ́n ti fì sùúrù dáhùn àwọn ìbèèrè mi tí wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye ìhìnrere náà. Mo mọ̀ pé láìsí ìrànlọ́wọ́ wọn, èmi kì bá ti ṣe àwárí Ìjọ òtítọ́. Kété tí mo ní ìmọ̀ náà, ìfẹ́ láti sìn tàn nínú ọkàn mi. Mo lè ní ìmọ̀ara ti Ẹ̀mí tí ó ńsọ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ sin míṣọ̀n ní kíkún.
Mo mọ̀ pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ iṣẹ́ ti Bàbá wa Ọ̀run àti pé a lè ṣe ìrànwọ́ láti mú àwọn ẹ̀mí wá sí ìmọ̀ ìyanu ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere.