2015
Ẹ̀rí àti Ìyípadà
February 2015


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kejì Ọdún 2015

Ẹ̀rí àti Ìyípadà

Ààrẹ Henry B. Eyring

Ìyàtọ̀ wà láárín gbígba ẹ̀rí ti òtítọ́ kan àti yíyípadà nítòótọ́. Fún àpẹrẹ, Àpọ́stélì ńlá Pétérù jẹ́ ẹ̀rí rẹ̀ sí Olùgbàlà pé òun mọ̀ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run.

“[Jésù] sọ fún wọn pé, ṣùgbọ́n tani ẹ̀yin nfi mí pè?

“Símónì Pétérù sì dáhùn wípé, Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alààyè ni ìwọ í ṣe.

“Jésù sì dáhùn ó sì wípé fún un pé, Alábùkún-fún ni ìwọ Símónì Ọmọ Jona: kì í ṣe ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ní ó sá fi èyí hàn ọ́, ṣùgbọ́n bàbá mi tí ńbẹ ní Ọ̀run” (Máttéù 16:15–17).

Àti pé síbẹ̀síbẹ̀ lẹ́hìn náà, nínú ìyànjú Rẹ̀ sí pétérù, Olúwa fún un àti àwa ní ìtọ́sọ́nà láti di ẹni ìyílọ́kànpadà nítòótọ́ ati lati fa ìyípadà náà gùn fún gbogbo ìgbà ìgbé ayé. Jésù sọ ọ́ ní ọ̀nà yí: “Nígbàtí ìwọ bá sì yípadà, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le” (Lúkù 22:32).

Jésù kọ́ Pétérù pé ìyípadà ńlá kan ṣì wà síbẹ̀ tí ó gbọ́dọ̀ kọjá níní ẹ̀rí kan láti lè ronú, ní ìmọlọ́kàn, àti láti ṣe bí ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì tí ó yípadà nítòótọ́. Èyínì ni yíyípadà ńlá tí gbogbo wa nwákiri. Ní kété tí a bá gbàá, a nílò yíyípadà náà láti tẹ̀síwájú títí dé ìparí ti ìdánwò ayé ikú wa (wo Álmà 5:13–14)

A mọ̀ láti inú ìrírí ti ara wa àti láti inú ṣíṣe àkíyèsí àwọn míràn pé níní àwọn àsìkò ńlá díẹ̀díẹ̀ ti agbára ẹ̀mí kò lè tó. Pétérù sẹ́ wípé òun kò mọ Olùgbàlà àní lẹ́hìn tí ó ti gba ẹ̀rí kan nípa Ẹ̀mí pé Jésù ni Krístì. Àwọn ẹlẹ́rí mẹ́ta sí Ìwé Mọ́rmọ́nì ní ẹ̀rí tààrà tí a fi fún wọ́n pé Ìwé Mọ́rmọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ lẹ́hìn náà wọ́n kọsẹ̀ nínú agbára wọn láti ṣe ìmúdúró Joseph Smith bíi Wòlíì ti Ìjọ Olúwa.

A nílò ìyípadà kan nínú ọkàn wa, gẹ́gẹ́bí ìwé ti Álmà ti ṣe àpèjúwe: “Gbogbo nwọn sì kéde fún àwọn ènìyàn náà ohun kan náà—pé ọkàn nwọn ti yí padà; pé nwọn kò ní ìfẹ́ láti ṣe búburú mọ́” (Álmà 19:33; wo Mosiah 5:2 bákan náà)

Olúwa kọ́ wa pé nígbàti a bá yípadà nítòótọ́ sí ìhìnrere Rẹ̀, ọkàn wa yíò yí kúrò ní awọn àníyàn ìmọtaraẹni nìkan yíò sì yí sí apá ọ̀dọ̀ iṣẹ́ ìsìn láti gbé àwọn ẹlòmíràn sókè bí wọ́n ṣe ńgòkè lọ sí ìyè ayérayé. Láti gba ìyípadà náà, a lè gbàdúrà kí a sì ṣiṣẹ́ nínú ìgbàgbọ́ láti di ẹ̀dá titun tí Ètùtù Ti Jésù Krístì mú kí ó ṣeéṣe.

A lè bẹ̀rẹ̀ nípa gbígbàdúrà fún ìgbàgbọ́ láti ronúpìwàdà kúrò nínú ìmọtaraẹni nìkan àti fún ẹ̀bùn ti ṣíṣe ìtọ́jú fún àwọn ẹlòmíràn ju ara wa lọ. A lè gbàdúrà fún agbára láti gbé ìgbéraga àti ìlara ti sí ẹ̀gbẹ́ kan.

Àdúrà yíò jẹ́ kọ́kọ́rọ́ àti bákannáà fún gbígba ẹ̀bùn ti ìfẹ́ kan fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fún ìfẹ́ ti Krístì (wo Mórónì 7:47–48). Àwọn méjèèjì wá papọ̀ Bí a ṣe ńkà, jíròrò, àti gbàdúrà lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó wá láti fẹ́ràn rẹ̀. Olúwa ń fi í sínú ọkàn wa. Bí a ṣe ńní ìmọ̀ara ìfẹ́ náà, a ó bẹ̀rẹ̀ sí ńní ìfẹ́ Olúwa síi àti púpọ̀ síi. Pẹ̀lú èyíinì ní ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn yíò wá tí a nílò ní ètò láti fún àwọn wọnnì lókun awọn ẹnití Ọlọ́run ti gbé sí ipa ọ̀nà wa.

Fún àpẹrẹ, a lè gbàdúrà láti mọ àwọn wọnnì tí Olúwa yíò fẹ́ kí àwọn oníṣẹ́ ìrànṣẹ́ Rẹ̀ kọ́. Àwọn oníṣẹ́ ìrànṣẹ́ ní kíkún lè gbàdúrà láti mọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí ohun tí wọn ní láti kọ́ àti jẹ́rí sí. Wọ́n lè gbàdúrà nínu ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run yíò jẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀lọ́kàn ìfẹ́ Rẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n bá pàdé. Àwọn oníṣẹ́ ìrànṣẹ́ ní kíkún kò ní mú gbogbo ènìyàn tí wọ́n bá pàdé lọ sínú omi ìrìbọmi àti lọ gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n lè ní Ẹmí Mímọ́ gẹ́gẹ́bí olùbárìn kan. Nípa iṣẹ́ ìsìn wọn àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́, nígbànáà àwọn oníṣẹ́ ìrànṣẹ́ yíò, yípadà nínú ọkàn wọn nígbà tí ó bá yá.

Ìyípadà náà yíò di sísọdọ̀tun lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi bí àwọn àti àwa bá ṣe ńfi àìnífẹ́tiaraẹni nìkan tẹ̀síwájú ní gbogbo ìgbà ìgbé ayé láti rìn nínú ìgbàgbọ láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun pẹ̀lú ìhìnrere ti Jésù Krístì. Ìyílọ́kànpadà kò ní jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̃kanṣoṣo tàbí ohun kan tí yíò pẹ́ títí fún àsìkò kan lásán ní ìgbé ayé, ṣùgbọ́n yíò jẹ́ ètò kan tí yío maa tẹ̀síwájú. Ìgbé ayé lè di dídán si títí di ọjọ́ pípé, nígbàtí a ó rí Olùgbàlà àti láti ri pé àti dà bíi Rẹ̀. Olúwa ṣe àpèjúwe ìrìn àjò náà lọ́nà yí. “Èyí náà tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run ni ìmọ́lẹ̀, àti pé ẹni tí ó bá gba ìmọ́lẹ̀, tí ó sì tẹ̀síwájú nínú Ọlọ́run, gba ìmọ́lẹ̀ síi; àti pé ìmọ́lẹ̀ náà ńgbèrú ní dídán àti ní dídán síi títí ọjọ́ pípé náà” (D&C 50:24).

Mo ṣe ìlérí fún yín pé ó ṣeéṣe fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.