Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kejì Ọdún 2015
Àwọn ìhùwàsí ti Jésù Krístì: Láìsí ẹ̀ṣẹ̀
Fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí ẹ sì wá lati mọ ohun ti ẹ ó ṣe àbápín rẹ̀. Báwo ni níní òye ìgbé ayé ati àwọn ojúṣe Olùgbàlà ṣe nmú ìgbàgbọ́ yin ninu Rẹ̀ pọ̀si ati kí ẹ bùkún awọn tí ẹ nṣe ìṣọ́ lé lórí nipa ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, jẹ́ ẹnì kanṣoṣo tí ó ní agbára láti ṣe ètùtù fún gbogbo ènìyàn. “Jésù Krístì, ọ̀dọ́ àgùtàn láìní àbàwọ́n, fi tìfẹ́tìfẹ́ gbé ara Rẹ̀ sí órí pẹpẹ ìrúbọ ó sì san gbèsè fún ẹ̀ṣẹ̀ wa,” ni Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní sọ.1 Níní òye pé Jésù Krístì wà láì lẹ́ṣẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa pọ̀ si nínú Rẹ̀ kí a sì tiraka láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, ronúpìwàdà, kí a sì di mímọ́.
“Jésù jẹ́ … ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀mí, ṣùgbọ́n kò yọ̀ọ̀da ara Rẹ̀ fún ìdánwò (rí Mosiah 15:5),” ni Alàgbà Elder D. Todd Christofferson ti Iyejú àwọn àpọ́stélì Méjìlá sọ. “Àwa lè yí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ … nítorí Ó ní òyé. Ó ní òyé ìgbìyànjú náà, bákannáà Ó ní òyé bí a ó ṣe ṣẹ́gun ìgbìyànjú náà. …
“… Agbára Ètùtù Rẹ̀ lè nu awọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ nù kúrò nínú wa. Nígbàtí a bá ronúpìwàdà, oore ọ̀fẹ́ ètùtù Rẹ̀ dáwa láre ó sì wẹ̀ wá mọ́ (wo 3 Nífáì 27:16–20). Ó dàbíí pé a kò tíì juwọ́ sílẹ̀, bíi pé a kò tíì dẹra sílẹ̀ sí ìdánwò.
“Bí a ṣe ńṣapá wa lójoojúmọ́ àti lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti tẹ̀lé ipa ọ̀nà ti Krístì, ẹ̀mí wa ntẹnumọ́ títayọ rẹ̀, ogun làárín wa nwálẹ̀, àwọn ìdánwò ndáwọ́dúró láti dàni láàmú.”2
Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ́
Láti inú Àwọn Ìwé Mímọ́
Olùgbàlà san gbèsè àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nípasẹ̀ jíjẹ́ Ọmọ ti ọ̀run Rẹ̀, ayé àìlẹ́ṣẹ̀ Rẹ̀, ìjìyà Rẹ̀ àti títa ẹ̀jẹ̀ Rẹ sílẹ̀ nínú ọgbà Gẹ́tsémánì, ikú Rẹ̀ lórí àgbélébú àti Àjíìnde Rẹ̀ kúrò nínú isà òkú. Nípa Ètùtù ti Jésù Krístì, a lè di mímọ́ lẹ́ẹ̀kansi bí a bá ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Ọba Bẹ́njámìn kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa Ètùtù ti Jésù Krístì àti pé nígbànáà ó bèèrè bí wọ́n bá gbà àwọn ọ̀rọ̀ oun gbọ́. “Gbogbo wọn sì kígbe lóhùn kan, wípé: … Ẹ̀mi … ti mú ìyípadà ńlá bá wa, tàbí nínú ọkàn wa, tí àwa kò sì ní ẹ̀mí àti ṣe búburú mọ́, ṣùgbọ́n láti máa ṣe rere títí. …
“Àwa sì fẹ́ láti dúró lórí májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ṣe ìgbọ́ran sí àwọn òfin rẹ̀ nínú ohun gbogbo” (Mòsíàh 5:1–2, 5).
Àwa náà lè ni “yíyípadà nlá” bíi ti àwọn ènìyàn Ọba Benjamin, awọn ẹnití “wọn kò sì ní ẹ̀mí láti ṣe ibi mọ́, ṣùgbọ́n láti ṣe rere títí” (Mosiah 5:2).
© 2015 Nípa Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/14. Àṣẹ ìyírọ̀padà: 6/14. Ìyírọ̀padà ti Visiting Teaching Message, February 2015. Yoruba. 12582 779