2016
Bàbá Ọ̀run Bá Mi Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ìpàdé Àpapọ̀ kan
OṢù Ìgbé 2016


Ọdọ

Bàbá Ọ̀run Bá Mi Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ìpàdé Àpapọ̀ kan

Olùkọwé náà ńgbé ní Sergipe, Brazil

Mò nní iyèméjì nípa ẹ̀kọ́ tí èmi yíó kọ́ ní unifásitì. Ọ̀pọ ènìyàn sọ̀rọ̀ burúkú nípa ẹ́kọ́ iṣẹ́ tí mo fẹ́ múṣe, nítorínáà mo gbàdúrà sí Olúwa láti ríi bí ó bá faramọ́ ìpinnu mi.

Ìdáhùn mi wá ní ọjọ́ kejì nígbàtí mo nka ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò nínú Lìàhónà. Mo ní ìmọ̀lára bíi pé Bàbá Ọ̀run nsọ fún mi pé Òun kò lè yàn fún mi—èyí jẹ́ ìpinnu kan tí èmi yíò ní láti dá ṣe. Mo mọ̀ pé ohun yówù tí mo yàn, èmi yíò ní láti ṣe iṣẹ́ àṣekára láti ṣe àṣe yege.

Mo mọ̀ pé àdúrà mi ti gbà. Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti Ẹ̀mí Mímọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu kan. Mo ti kọ́ láti fi ìtiraka mi tí ó dárajù síi mo sì mọ̀ pé Bàbá Ọ̀run yíò ràn mí lọ́wọ́.