Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, oṣù kẹ́rin ọdún 2016
Àsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn Araẹni
Ìjọ ti Jésù Krístì ní tòótọ́ ti di mímú padàbọ̀sípò ó sì wà ni orí ilẹ̀ ayé lónìí. Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ti fi ìgbàgbogbo jẹ́ dídarí nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpọ́stél, tí wọ́n ńgba ìtọ́sọ́nà léraléra láti ọ̀run.
Ètò ti ọ̀run náà jẹ́ òtítọ́ bákannáà ní àtijọ. A kọ́ nínú Bíbélì pé: “Dájúdájú Olúwa Ọlọ́run kì yíò ṣe ohun kankan, ṣùgbọ́n òun yíò fi àṣírí rẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àwọn wòlíì” (Amos 3:7).
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi ní ìgbà tiwa, nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith. Ó fi ìhínrere ti Jésù Krístì hàn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípasẹ Wòlíì Joseph. Ó mú oyè àlùfáà Rẹ̀ mímọ́ padàbọ̀sípò pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀tọ́, agbára, àti àwọn ojúṣe agbára mímọ́ ti oyè àlùfáà.
Ní ọjọ́ tiwa, a fún àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpọ́stélí ní àṣẹ láti sọ̀rọ̀, kọ̀ni, àti láti darí pẹ̀lú àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bàbá àti Olúwa Jésù Krístì. Olùgbàlà sọ fún Wòlíì pé, Ohun tí èmi Olúwa bá ti sọ, mo ti sọọ́, àti pé èmì kò yọ ara mi kúrò; àti pé bí ọ̀run àti ayé tilẹ̀ kọjá lọ, ọ̀rọ̀ mi kò ní kojá lọ, ṣùgbọ́n yíò di mímúṣẹ, bóyá nípa ohùn ti ara mi tàbí nípa ohùn àwọn ìrànṣẹ́ mi, ọ̀kan náà ni” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:38).
Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò ní ẹ́ẹ̀méjì lọ́dún kan, a di alábùkún fún pẹ̀lú ànfàní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa fún wa láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Eyíinì jẹ́ ànfàní kan tí ó kọjá ìdíyelé. Ṣùgbọ́n ìyì ànfàní náà dá lóríi boyá a gba àwọn ọ̀rọ̀ náà lábẹ́ ìmísí ti Ẹ̀mí kannáà nípa èyí tí a fi fún àwọn ìránṣẹ́ wọnnì (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 50:19–22). Gẹ́gẹ́bí wọ́n ti ngba ìtọ́sọ́nà láti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ fún wa. Èyí sì beerè fún irú ìgbìyànjú kannáà lati ọ́wọ́ wa.
“Ṣe Iṣẹ́ Àmúrelé Rẹ“
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bèèrè pé kí nka ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ kan tí ó ńpèsè sílẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò. Mo jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ kékeré ti iyejú náà. Mo ní iyì nípa ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ pé mo lè ràn òun lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa yíò fẹ́ kí ó sọ. “Ó sọ fún mi pẹ̀lú ẹ̀rín pé, “Ah, èyí ni ẹ̀dà kíkọ ìkejìlélógún ti ọ̀rọ̀ náà.”
Mo rantí ìmọ̀ràn tí olùfẹ́ni àti onínúrere Ààrẹ Harold B. Lee (1899-1973)ti fún mi ṣaájú pẹ̀lú ìtẹnumọ́ nlá: “Hal, bí ó bá fẹ́ ní ìfihàn, ṣe iṣẹ́ àmúrelé rẹ.”
Mo kàá, jíròrò, mo sì gbàdúrà lórí ẹ̀dà kíkọ ìkejìlélógún náà. Mo ṣe àṣàrò bí mo ṣe lè ṣe tó lábẹ́ agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìgbà tí ọmọ ẹgbẹ́ iyejú náà fúnni ní ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo ti ṣe iṣẹ́ àmúrelé mi. Kò dá mi lójú pé mo ṣe ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé mo ní ìyípadà nígbàtí mo gbọ́ tí a fi ọ̀rọ̀ náà fúnni. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ò wá sí ọ́dọ̀ mi tayọ kọjá àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti ka àti èyí tí ó sọ. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ní ìtumọ̀ tí ó tóbi jù àwọn tí mo ti ka nínú ẹ̀dà kíkọ. Àti pé ọ̀rọ̀ náà dàbíi pé ó wà fún mi, ó bá àwọn àìní mi mu.
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run a máa gbàwẹ̀ wọ́n a sì gbàdúrà láti gbá ọ̀rọ̀ tí Ó ní fún wọn láti fi wọ́n fún àwọn tí ó nílò ìfihàn àti ìmísí. Òhun tí mo kọ́ láti inú ìrírí náà, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òmíràn bíi rẹ̀, ni pé láti jèrè ànfàní nlá tí ó wà nínú gbígbọ́ àwọn wòlíì àti àpọ́stélì, a gbọ́dọ̀ san ẹ̀sàn gbígba ìfihàn fúnra wa.
Olúwa ní ìfẹ́ gbogbo ẹni tí yíó gbọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ó sì mọ ọ̀kàn àti ipò ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ó mọ irú àtúnṣe, irú ìgbani-níyànjú, ati irú òtítọ́ ìhìnrere tí yíò ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ jùlọ láti yan ọ̀nà rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin lọ ní ipá ọ̀nà sí ìyè ayérayé.
Àwa tí à ńfetísílẹ̀ tí a sì nwo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìpàdé gbogbogbòò máa ńfì ìgbà míràn roó lẹ́hìnnáà, “Kíni èmi rantí dáradára jùlọ?” Ìrètí Olúwa fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni pé ìdáhùn wa yíò jẹ́: “Èmi kò ní gbàgbé àwọn àsìkò nígbàtí mo ní ìmọ̀lára ohùn Ẹ̀mí ní inú mi àti ọkàn mi tí ó nsọ fún mi ohun tí èmí ó ṣe láti mú inú Bàbá mi Ọ̀run àti Olùgbàlà dùn.”
A lè gba ìfihàn araẹni náà nígbàtí a bá ngbọ́ àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́stélì àti bí a ṣe nṣiṣẹ́ nínú ìgbàgbọ́ láti gbàá, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Lee ti sọ pé a lè ṣe. Mo mọ̀ pé èyí jẹ́ òtítọ́ láti inú ìrírí àti nípasẹ̀ ẹ̀rí ti Ẹ̀mí.
© 2016 by Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. Atẹ̀ẹ́ ní USA Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/15. ÀṣẹÌyírọpadà 6/15. Àyípadà ọ̀rọ̀ ti First Presidency Message, April 2016. Yoruba 12864 779