2018
Dámọ̀ràn nipa àwọn Àìní Wọn.
Oṣù Kẹsán 2018


ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2018

Dámọ̀ràn nipa àwọn Àìní Wọn.

Ẹ kò ní láti dá nìkan ṣe èyi. Dídámọ̀ràn lè pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ẹ nílò láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

Ọlọ́run ti pe yín láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹnìkan tàbí ẹbí ninú wọ́ọ̀dù tàbí ẹ̀ka yín gẹ́gẹ́bí àìní wọn. Báwo ni ẹ ó ṣe ṣe àwájáde ohun tí àwọn àìní wọnnì jẹ́? Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ dídámọ̀ràn, èyí tí ó ti jẹ́ irú ìfojúsùn kan nínú ìjọ, jẹ́ kókó.

Lẹ́hìn sísọ̀ ohun tí a lè gbèrò dídámọ̀ràn nípa rẹ̀, a o tupalẹ̀:

  1. Dídámọ̀ràn pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run.

  2. Dídámọ̀ràn pẹ̀lú ẹnìkan àti ẹbí tí a fúnni-níṣẹ́ rẹ̀.

  3. Dídámọ̀ràn pẹ̀lú ojúgbà wa.

  4. Àti dídámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí a yàn sí irú ẹnìkan tàbí ẹbí kan náà.

Didámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn olórí wa ṣe pàtàkì bákannáà. Àwọn nkan Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ojọ́ iwájú nínú Liahona ni yío tú dídámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn olórí palẹ̀ bákannáà bí ojúṣe àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ètò náà.

Ohun tí à Ndáni Nímọ̀ràn nípa rẹ̀

Níní òye àwọn àìní ṣe pàtàkì sí síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa. Ṣùgbọ́n kíni àwọn ọ̀nà tí àwọn àìní wọnnì lè gbà, àti pé njẹ́ ohun kan wà tí ó ju àwọn àìní tí a gbọ́dọ̀ wá jáde?

Awọn àìní lè wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Àwọn wọnnì tí à nsìn lè dojúkọ àwọn ìpènija tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, ọ̀rọ̀ ìnáwó, ti ara, ìkẹ́kọ̀ọ́, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn àìní kan ṣe kókó ju àwọn míràn lọ. A ó ní ipá láti ṣe ìrànwọ́ pẹ̀lú àwọn kan; àwọn míràn lè mú kí àwa fúnra wa dúró fún ìrànlọ́wọ́. Nínú àwọn ìlàkàkà wa láti ṣe ìrànwọ́ láti bá àwọn àìní ti ara pàdé, ẹ máṣe gbàgbé pé ìpè wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wà pẹ̀lú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìlọsíwájú ní ẹ̀gbẹ́ ipá ọ̀nà májẹ̀mú, mímùrasílẹ̀ fún àti gbìgba àwọn ìlànà oyè-álùfáà tí o ṣe pàtàkì fùn ìgbéga.

Ní àfikún sí dídámọ̀ràn nípa àìní ti ẹ̀nìkan tàbí ti ẹbí, a gbọ́dọ̀ wá láti kọ́ nípa àwọn okun wọn. Kíni àwọn ohun tí wọn kò nílò ìrànlọ́wọ́ fún? Kíni àwọn agbára àti ẹ̀bùn tí wọ́n ní tí ó lè bùkún àwọn ẹlòmíràn. Báwo ni wọ́n ṣe wà ní ìbámu àrà-ọ̀tọ́ tó ní ìbamu láti ṣe ìrànlọ́wọ́ gbé ìjọba Ọlọ́run ga? O le jẹ́ pàtàkì láti ní òye àwọn okun ẹ̀nikan bíi ti àwọn àìní rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin

Dídámọ̀ràn pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run

Ọ̀kan lára àwọn ààrin gbùngbùn ìlànà ti ìgbàgbọ́ wa ni pé Baba Ọ̀run nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀ (wo Articles of Faith 1:9). Nígbàtí a bá gba ìfúnni-níṣẹ́ṣe titun kan láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹnìkan, a gbọ́dọ̀ dámọ̀ràn pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run nínú àdúrà, ní wíwá ìmọ̀ àti òye sí inú àwọn àìní àti okun wọn. Ètò dídámọ̀ràn náà nípasẹ̀ àdúrà gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú nínú gbogbo ìfúnni-níṣẹṣe iṣẹ́ ìránṣẹ wa.

Dídámọ̀ràn pẹ̀lú Àwọn Ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan àti Àwọn Ẹbí

Bí a ti ṣe àti ìgbà tí a sètò àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí tí a pè wá láti sìn lè yàtọ̀ ní dídá lórí àwọn ipò, ṣùgbọ́n dídámọ̀ràn tààrà pẹ̀lú enì náàtàbí ẹbí ṣe pàtàkì fún mímú àwọn ìbáṣepọ̀ dàgbàsókè àti níní òye àwọn àìní wọn, àti bí wọ́n ṣe fẹ́ láti gba ìrànlọ́wọ́. Àwọn ìbèèrè kan lè níláti dúró títí tí a fi mú ìbáṣepọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ gbèrú si. Ní ìgbàtí kò sí ọ̀nà kan tí ó tọ́ láti ṣe èyíinì, ẹ gbèrò àwọn tí wọ́n tẹ̀lé wọ̀nyí:

  • Ẹ wá ìdí báwo ni àti ìgbàwo ni wọ́n fẹ́ láti bá yín pàdé.

  • Ẹ kọ́ nípa àwọn ohun tí wọn fẹ́ràn àti àtilẹ̀wá wọn.

  • Ẹ wá pẹ̀lú àwọn àbá dídá nípa bí ẹ̀yin ṣe le ṣèrànwọ́, kí ẹ sì bèèrè fún àwọn àbá dídá tiwọn.

Bí a ṣe nmú ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ dàgbà, ẹ gbèrò sísọ̀rọ̀ àwọn aìní ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹbí. Ẹ bèèrè àwọn ìbèrè bí Ẹmí Mímọ́ bá ṣe fún yín ní ìṣílétí.1 Fún àpẹrẹ:

  • Kíni àwọn ìpèníjà tí wọ́n ndojúkọ?

  • Kíni àwọn àfojúsùn ẹbí tàbí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn? Fún àpẹrẹ, ṣe wọ́n ní ìfẹ́ láti dára si ní ṣíṣe ìpàdé ìrọ̀lẹ́ ẹbí nílé déédé, tàbí ní igbárale-araẹni si?

  • Báwo ni a ṣe lè rànwọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àfojúsùn àti ìpèníjà wọn?

  • Kíni àwọn ìlànà ìhìnrere tí ó nfẹ́ wá sí ìfarahàn nínú ìgbé ayé wọn? Báwo ni a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀?

Rántí láti fúnni ní ìrànlọ́wọ́ kan pàtó, bí irú, “Alẹ́ wo ni kí a gbé oúnjẹ́ wá fún yín ní ọ̀sẹ̀ yí?” Ìfúnni tí kò fẹsẹmúlẹ̀, bíi, “Ẹ jẹ́ kí a mọ̀ bí ohunkóhun bá wà tí a lè ṣe,” kò ṣe ìrànlọ́wọ́ tó.

Dídámọ̀ràn pẹ̀lú ojúgbà wa

Nítorípé ẹ̀yin àti ojúgbà yín lè máa fi ìgbàgbogbo wà papọ̀ nígbàtí ẹ bá nbá ẹnì náà tàbí ẹbí sọ̀rọ̀, ó ṣe pàtàkì láti jùmọ̀ ṣe àti láti dámọ̀ràn papọ̀ bí ẹ ó ṣe máa wá ìmísí bí ojúgba kan. Níhín ni àwọn ìbèèrè díẹ̀ kan láti gbèrò:

  • Báwo ni àti yío ti jẹ́ léraléra tó tí ẹ̀yin yíò maa bárasọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ojúgbà kan?

  • Báwo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín ṣe lè lo okun ẹnìkọ̀ọ̀kan yín láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn àìní ti ẹbí tàbí ti ẹnìkọ̀ọ̀kan?

  • Awọn ohun wo ni ẹ ti kọ́, àwọn ìrírí wo ni ẹ ti ní, àti pé àwọn ìṣílétí wo ni ẹ ti gbá láti ìgbà tí ẹ ti sọ̀rọ̀ gbẹ̀hìn nípa ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹbí náà?

Dídámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn Ẹlòmíràn tí a fiṣẹ́-fún

Ó lè dára láti ìgbà dé ìgbà láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlómíràn tí wọ́n ti gba ìfiṣẹ́-fún láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí irú ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹbí tí ẹ̀ nṣe.

Ẹ Bárasọ̀rọ̀ láti Yanjú àwọn Ìpèníjà

Alàgbà Chi Hong (Sam) Wong ti Àádọ́rin lo ìkọni láti inú Mark 2 sí ọjọ́ wa láti ṣe àpèjúwe bí dídámọ̀ràn papọ̀ ṣe mu kí ó ṣeéṣe fún àwọn ènìyàn mẹ́rin kan láti mọ̀ bí wọ́n ṣe lè gba ọkùnrin kan pẹ̀lú àrùn ẹ̀gbà láàye láti wà níwájú Jésù.

“O lè ṣẹlẹ̀ bí èyí,” ni Alàgbà Wong sọ. “Àwọn ènìyàn mẹ́rin nmú ìfúnni-níṣẹ ṣe láti ọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀pù láti ṣe ìbẹ̀wò, ní ilé rẹ̀, ọkùnrin kan tí ó nṣe àárẹ̀ pẹ̀lú àrùn ẹ̀gbà. … Nínú ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù tí kòpẹ́ ràrá jùlọ, lẹ́hìn dídámọ̀ràn papọ̀ nípa àwọn àìní nínú wọ́ọ̀dù, bíṣọ́ọ̀pù ti fúnni ní àwọn ìfúnni-níṣẹ́ ‘gbígbanilà.’ Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí ni a fún-níṣẹ́ láti ran arákùnrin yí lọ́wọ́. …

“[Nígbàtí wọ́n dé ilé náà níbití Jésù wà,] yàrá náà ti kún jù. Wọn kò lè wọlé láti ẹnu ọ̀nà. Ó dá mi lójú pé wọ́n tiraka ohun gbogbo tí wọ́n lè ronú nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè rí àyè ṣaa ni. … Wọ́n dámọ̀ràn papọ̀ lórì ohun tí ó kàn láti ṣe—bí wọn ṣe lè gbé ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì fún ìwòsàn. … Wọ́n wá pẹ̀lú ètò kan—ọ̀kan tí kò rọrùn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣiṣẹ́ lée lórí.

“… Wọ́n ṣí òrùlé ibi tí ó wà: nígbàtí wọ́n ti ṣi sókè, wọ́n gbé ibùsùn sọ̀kalẹ̀ níbití aláìsàn ẹ̀gbà sùn sí’ (Mark 2:4). …

“… ‘Nígbàtí Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún aláìsàn ẹ̀gbà pé, Ọmọkùnrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́’ (Mark 2:5).”2

Ìpè láti ṣe ìṣe

Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá rọni pé, “E dámọ̀ràn papọ̀, ẹ lo gbogbo ohun èlò tí ó wà ní àrọ́wọ́tó, ẹ wá ìmísí ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ bèèrè lọ́wọ́ Olúwa fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ Rẹ̀, àti nígbànáà ẹ ká apá èwù yín sókè, kí ẹ sì lọ ṣiṣẹ́.

“Mo fún yín ní ìlerí kan: tí ẹ bá tẹ̀lé àwòṣe yí, ẹ̀yin yíò gba ìtọ́sọ́nà pàtó nípa tani, kíni, nígbàwo, àti níbo ti pípèsè ní ọ̀nà ti Olúwa.”3

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. wo Ẹ Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà kan sí Iṣẹ́ Ìsìn Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ (2004), 183.

  2. Chi Hong (Sam) Wong, “Gbígbàlà nínú Irẹ́pọ̀,” Liahona, Nov. 2014, 14–15.

  3. Dieter F. Uchtdorf, “Pípèsè ní Ọ̀nà Olúwa,” Liahona, Nov. 2011, 55.