Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kejìlá 2018
Fihàn Pé Ó Nṣìkẹ́
Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà tí a fi lè fihàn pé à nṣìkẹ́, pàtàkì ní àkokò Kérésìmesì. A lè sọ ọ́, ṣe àtẹ̀jíṣẹ rẹ̀, kọ ọ́, fúnni, pín in, gbàdúrà rẹ̀, yan án, dìmọ́ ọ, ṣeré rẹ̀, gbìn ín, tàbí tún un ṣe. Fi pẹ̀lẹ́kùtù gbìyànjú rẹ̀.
Fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn wà ní oókan àyà ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Jean B. Bingham sọ pé: “Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ òtítọ́ njẹ́ àṣeyege ní ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ gẹ́gẹ́bí ohun ìwúnilórí. … Pẹ̀lú ifẹ́ gẹ́gẹ́bí ohun ìwúnilórí, àwọn iṣẹ́ ìyanu yíò ṣẹlẹ̀, a ó sì rí àwọn ọ̀nà láti mú àwọn arábìnrin àti arákùnrin wa tí wọ́n ti ‘ṣákolọ’ wá sínú àpapọ̀ ìgbanimọ́ra ti ìhìnrere Jésù Krístì.”1
Jíjẹ́ kí àwọn míràn mọ̀ pé à nṣìkẹ́ wọn jẹ́ ohun pàtàkì fún mímú ìbáṣepọ̀ araẹni gbèrú si. Ṣùgbọ́n àwọn onírurú ènìyàn ngba ọ̀rọ̀ náà ní àwọn oníruru ọ̀nà. Nítorínáà báwo ni a ṣe le fi ìfẹ́ wa hàn dáradára fún àwọn míràn ní àwọn ọ̀nà tí yío yé wọn tí wọn yíò sì mọ iyi rẹ̀? Nihin ni àwọn ọ̀nà láti bánisọ̀rọ̀ pé à nṣìkẹ́, ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èrò díẹ̀ kan láti bẹ̀rẹ̀ rírònú ti ara wa.
Sọ Ọ́
Ní àwọn ìgbà míràn kìí sí ìrọ́pò fún sísọ bí a ṣe nní ìmọ̀lára sí nípa ẹnìkan . Nígbàtí èyí lè túmọ̀ sí sísọ fún ẹnìkan pé o ní ìfẹ́ wọn, ó ní ṣíṣe àbápín nínú ohun tí o fẹ́ràn nípa wọn bákannáà tàbí ṣíṣe oríyìn lódodo. Irú àtẹnumọ́ yí nṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú àwọn ìbáṣepọ̀ ní okun si. (Wo Éfésù 3:19.)
-
Wá ànfàní kan láti jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ bí ẹ ṣe fẹ́ràn ọ̀kan lára àwọn okun arákùnrin tàbí arábìnrin náà tó.
-
Yà wò ó, pè é, tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ ayélùjára, àtẹ̀ránṣẹ́, tàbí káàdì ránṣẹ́ tí ó nsọ fún ẹni náà pé ẹ̀ nronú nípa wọn.
Bẹ̀wò
Wíwá àkokò láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àti láti fi etí sílẹ̀ sí ẹnìkan jẹ́ ọ̀nà alagbára kan láti fi bí arákùnrin tàbí arábìnrin náà ṣe níyì tó síi yín hàn. Boyá ẹ ṣe ìbẹ̀wò ní ilé, ní ilé ìjọsìn, tàbí ibikíbi, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà tí wọ́n nílò ẹnìkan tí wọ́n lè bá sọ̀rọ̀. (Wo Mòsíàh 4:26; D&C 20:47.)
-
Ní ìbámu sí àwọn àìní ẹnì náà, ẹ ṣètò ìbẹ̀wò kan. Lo àkokò láti fetísílẹ̀ ní tòótọ́ kí ẹ sì ní òye àwọn ipò arákùnrin tàbí arábìnrin náà.
-
Níbí tí ó bá ti lè ṣòro láti ṣe ìbẹ̀wò sí ilé nítorí ọ́ná-jíjìn, àwọn ohun àṣà, tàbí àwọn ipò míràn, gbèrò wíwá àkókò papọ̀ lẹ́hìn àwọn ìpàdé Ìjọ.
Sìn Pẹ̀lú Èrò kan
Fi ọkàn sí ohun tí ẹni náà tàbí ẹbí nílò. Pípèsè iṣẹ́ ìsìn tí ó nítumọ̀ nfihàn pé ẹ̀ nṣìkẹ́. Ó nṣe àpapọ̀ àwọn ẹ̀bùn iyebíye ti àkokò àti ìtiraka tí ó níyì. ““Àwọn ìṣe ìrọ̀rùn ti iṣẹ́ ìsìn lè ní àbájáde tí ó jinlẹ̀ lórí àwọn ẹlòmíràn,” ni Arábìnrin Bingham sọ.2
-
Fúnni ní iṣẹ́ ìsìn tí ó nfún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ẹbí wọn ní okun, bíi bíbojútó àwọn ọmọ kí àwọn òbí lè lọ sí tẹ́mpìlì.
-
Wá àwọn ọ̀nà láti mu ẹrù fúyẹ́ nígbàtí ìgbé ayé bá munilómi, bíi nínu àwọn fèrèsé, mímú ajá rìn, tàbí ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ nínú ọgbà.
Ẹ jọ Ṣe Àwọn Nkan Papọ̀
Àwọn kan wà tí wọn kìí ní ìsopọ̀ nipa àwọn ìbánisọ̀rọ̀ tí ó jinlẹ̀. Fún àwọn ènìyàn kan, àwọn ìsopọ̀ máa njẹ́ síṣe nípa wíwá àwọn ohun tí ó wọ́pọ̀ tí wọ́n jọ ní ìfẹ́ sí àti lílo àkokò papọ̀ ní ṣíṣe àwọn ohun wọnnì. Olúwa rọni pé kí a “wa pẹ̀lú, kí a sì fún (D&C 20:53) àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lókun”.
-
Lọ fún ìrìn, ṣe ètò alẹ́ ìṣere kan, tàbí ṣe àgbékalẹ̀ àkokò láti ṣe ere-ìdárayá papọ̀ déédé.
-
Sìn papọ nínú iṣẹ́ ílú kan tàbí ti Ìjọ.
Fúnni ní Ẹ̀bùn kan
Ní àwọn ìgbá miràn àkokò tàbí àwọn ànfàní láti báraṣeré nlópin. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà, fífúnni ní àwọn ẹ̀bùn jẹ́ àmì ìtọ́jú àti ṣíṣe àánú. Àní ẹ̀bùn ìrọrùn ẹ̀kọ̀ọ̀kan, lè fi ìfẹ́ yín hàn láti mú ibáṣepọ̀ dídára dàgbàsókè. (Wo Proverbs 21:14.)
-
Mú wọn lọ fún ìgbádùn alárinrin kan tí wọ́n fẹ́ràn.
-
Ṣe àbápín àyọsọ kan, ìwé mímọ́, tàbí ọ̀rọ̀ míràn tí ẹ ní ìmọ̀lára pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inu rẹ̀.
Iṣẹ́ Ìfẹ́ kan
Bí ẹ ṣe nmọ àwọn ẹni wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìranṣẹ́ sí àti ẹni tí ẹ̀ nwá ìmísí fún, ẹ̀yin yíò kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípàtàkì bí ẹ ó ṣe fi ifẹ́ àti ìtọ́jú yín hàn sí wọn níkọ̀ọ̀kan.
Kimberly Seyboldt of Oregon, USA, sọ ìtàn wíwá ìmísí àti fífúnni ní àwọn ẹ̀bùn láti fi ìfẹ́ hàn:
Nígbàtí mo bá ríi pé ayé bá nmú ìrẹ wẹ sì wá mo máa ndìde mo sì máa nṣe búrẹ́dì zucchini, nígbàmíràn bíi àkàṣù mẹ́jọ. Ohun èlò pàtàkì mi ni àdúrà ìdákẹ́jẹ́ tí mò máa nṣe bí mo ṣe ndáná láti mọ àwọn ẹnití wọ́n nílò àwọn àkàṣù búrẹ́dì wọnnì. Mo ti mọ àwọn aladugbo tí wọ́n yí mi ka dáradára síi bí búrẹ́dì zúcchíní ṣe jẹ́ ìfipè mi sínu ilé àti ìgbé ayé wọn.
“Ní ọjọ́ kan ní ìgba ìrúwé, mo dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbí kan tí wọ́n nta àwọn èso blackberries ní ẹ̀gbẹ́ òpópónà. Èmi kò nílò blackberries si, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́, ọmọdékùnrin tínrín ní ibùdó náà ní inú dídùn láti rí mi, ní ríronú pé èmi ni olùbárà rẹ̀ tí ó kàn. Mo ra blackberries díẹ̀, ṣùgbọ́n bákannáà mo ní ẹ̀bùn kan fún un. Mo fún ọmọdékùnrin náà ní àkàṣù búrẹ́dì méjì. O yípadà sí bàbá rẹ̀ fún àṣẹ, nígbànáà ó sọ wípé,’Wòó, Bàbá, nísisìyí a ní ohunkan láti jẹ ní òní.’ Inú mi kún fún ìmoore fún ànfàní yí láti fi ìfẹ́ hàn ní ọ̀nà ìrọrùn.”
Alàgbá Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bẹ̀bẹ̀ “pé gbogbo ọkùnrin àti obìnrin—àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n dàgbà— yíò [ni] … ìfọkànsìn jíjinlẹ̀ sí ìtọ́jú àtọkànwá fún ara wọn, tí ìwúnilórí rẹ̀ nwá nípasẹ̀ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ti Krístì nìkan láti ṣe bẹ́ẹ̀. … Njẹ́ kí a lè ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Olúwa ọgbà àjàrà, ní fífún Ọlọ́run àti Bàbá gbogbo wa ní ọwọ́ ìrànnilọ́wọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ takun-takun Rẹ̀ ti dídáhùn àwọn àdúrà, pípésè ìtùnú, nínu àwọn omijé, àti fífún àwọn eékún áìlera lokun.”3
Jésù Krístì Nṣìkẹ́
Lẹ́hìn tí Jésù Krístì jí Lásárù dìde nínú òkú, “Jésù sọkún.
“Nítorínáà àwọn Júù wípé, Ṣáà wòó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” Jòhánnù 11:35-36
“Mo ní ìyọ́nú fún yín,” Krístì sọ fún àwọn ará Nífáì. Nígbànáà Ó pè fún àwọn aláìsàn àti olùpọ́njú wọn, arọ àti afọ́jú wọn, “ó sì wò wọ́n sàn” (wo 3 Nephi 17:7–9).
Olùgbàlà gbé àpere náà kalẹ̀ fún wa bí Òun ṣe ṣìkẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Ó kọ́ wa:
“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ, fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Èyí ni èkínní àti òfin nlá.
““Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Matthew 22:37–39).
Tani ó nílò ìtọ́jú yín? Báwo ni ẹ ṣe lè fihàn pé ẹ̀ nṣìkẹ́ wọn?
© 2018 by Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́ A tẹẹ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì 6/17. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/17. Àyípadà èdè ti Ministering Principles, December 2018. Yoruba. 15056 779