2019
Ṣé Ẹ̀ Npàdánù Apákan Pàtàkì Yí nípa Ṣíṣe-iṣẹ́-iránṣẹ́
Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2019


Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹwa 2019

Ṣé Ẹ̀ Npàdánù Kókó Apákan Pàtàkì Yí nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́?

Ṣíṣe-iṣẹ́-iránṣẹ́ ni láti “yayọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n nyayọ̀” gẹ́gẹ́bí ó ti wọ́pọ̀ láti “sọkún pẹ̀lú àwọn tó nsọkún”(Àwọn Ará Rómù 12:15).

ministering

Àwọn ìjúwe látọwọ́ Augusto Zambonato.

Nígbàtí a bá nronú nípa ṣíṣe-iṣẹ́-ìránṣẹ, ó rọrùn láti ronú nípa ríran àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àìní lọ́wọ́. A sọ̀rọ̀ nípa ìdákò fún opó, mímú oúnjẹ́ alẹ́ lọ fún aláìsàn, tàbí fífún àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka. A rántí ámọ̀ràn Páùlù láti “sọkún pẹ̀lú àwọn tó nsọkún,” ṣùgbọ́n njẹ́ a ní ífojúsí tó kúnjú-ìwọn ni ìṣíwájú ara ẹsẹ náà—láti “yayọ̀ pẹ̀lú àwọn tó nyayọ̀”? (Àwọn Ará Rómù 12:15. Yíyayọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí—bóyá ìyẹn túmọ̀sí ayẹyẹ àṣeyege wọn tàbí ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ ní àwọn ìgbà ìṣòro—jẹ́ apákan pàtàkì ti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Olùgbàlà yíò ti ṣe.

Nihin ni àwọn èrò mẹta tí ó lè ṣèrànwọ́ (àti ọ̀kan láti yẹra fún) bí a ṣe nwò láti fojúsí ire tí Ọlọ́run fi sínú ayé wa.

1. Ẹ Ṣọ́ra.

Bonnie H. Cordon, Ààrẹ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, rànwálọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ tí a nílò láti àwọn wọnnì tí à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ sí— máṣe rí àwọn àjàgà àti ìlàkàkà wọn nìkan ṣùgbọ́n bákannáà àwọn okun wọn, ẹ̀bùn, àti àṣeyege. Ó wípé a níláti jẹ́ “olùborí àti olùgbẹ́kẹ̀lé—ẹnìkan tí ó nífura àwọn ipò wọn tí ó sì ntì wọ́n lẹ́hìn nínú ìrètí àti ìgbìrò wọn.”1

Nínú òwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, Olùgbàlà wípé àwọn wọnnì tí a ó rí ní ọwọ́ ọ̀tún Òun yíò bèèrè: “Olúwa, nígbàwo ni a rí ọ́ nínú ẹbi, tí a kò bọ́ọ? tàbí nínú òhùngbẹ, tí a kò fún ọ́ mu?

“Nígbàwo ni a rí ọ lálejò, tí a kò mú ọ wọlé?” (Máttéù 25:37–38).

“Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, kókó ọ̀rọ̀ náà ni ríi,” ni Arábìnrin Cordon wí. “Àwọn olódodo rí àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àìní nítorí wọ́n nṣàkíyèsí. Àwa náà lè ní ojú ìfura láti ṣàtìlẹhìn àti láti tunininú, láti ṣayẹyẹ àní láti lá àlá.”2

2. Wá àwọn Èrèdí láti ṣayẹyẹ.

Ṣayẹyẹ àwọn àṣeyege nlá tàbí kékeré. Ó lè jẹ́ líla àrun jẹjẹrẹ já tàbí líla ìfira-ẹnisílẹ̀ kọjá, rírí iṣẹ́ titun tàbí rírí bàtà kan tó sonù, yíyọ nínú ewu pípàdánù olùfẹ́ni kan tàbí yíyọ nínú ewu ọ̀sẹ̀ kan láìsí ṣúgà.

Ẹ pè láti kíni kú oríre, ẹ fi káàdì kan sílẹ̀, tàbí jáde lọ fún oúnjẹ-ọ̀sán. Nípa ṣíṣe àbápín nínú àwọn ìbùkún wa papọ̀, gbígbé pẹ̀lú ímoore, àti ṣíṣe-ayẹyẹ àwọn ìbùkún àti àṣeyege àwọn ẹlòmíràn, a “níláti yayọ̀ nínú ayọ àwọn arákùnrin wa” (Álmà 30:34).

3. Rí Ọwọ́ Olúwa .

Nígbàmíràn yíyayọ̀ pẹ́lú àwọn ẹlòmíràn túmọ̀ sí ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn èrèdí láti yayọ̀—èyíówù irú ìṣòrokíṣòro tàbí ìdùnnú tí ó wọnú ayé wa. Òtítọ́ jẹ́jẹ́ pé Bàbá Ọ̀run mọ wá Ó sì ṣetán láti gbé wa ga lè jẹ́ orísun ayọ̀ tó le.

Ẹ lè ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti rí ọwọ́ Olúwa nínú ayé wọn nípa ṣíṣe àbápín bí ẹ ṣe ti ri nínú ayé ara yín. Ẹ fi gbogbo akitiyan ṣe àbápín bí Bàbá Ọ̀run ti ṣe ràn yín lọ́wọ́ nínú àwọn ìpènijà yín. Ẹ̀rí yí lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dámọ̀ àti lati jẹ́wọ́ bí Òun ti ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ (wo Mòsíàh 24:14).

4. Ẹ Máṣe Dẹ́kun Agbára Yín láti Yayọ̀.

Láìlóríre, a lè fìgbàmíràn dẹ́kun agbára ara wa láti yayọ̀ pẹ̀lú àwọn míràn, pàtàkì nígbàtí a bá nímọ̀lára ewu nípa ohun tí a níláti fúnni tàbí ibi tí a wà ní ayè. Dípò wíwá ayọ̀ nínú ìdùnnú àwọn míràn, a lè ṣubú sínú pàkúté àfiwé. Àti bí Alàgbà Quentin L. Cook ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ti kọ́ni: “Àfiwé àwọn ìbùkún ni ìdánilójú jùlọ láti lé ayọ̀ jáde. A kò lè ní ìmoore àti ìlara ní ìgbà kan náà.”3

“Báwo ni a ṣe lè borí irú ìwà kannáà tó wọ́pọ̀ nínú gbogbo ènìyàn?” ni Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bèèrè. “… A lè ka àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún wa kí a lè gbóríyìn fún àṣeyọrí àwọn ẹlòmíràn. Dídárajù gbogbo rẹ̀, a lè sin àwọn ẹlòmíràn, eré-ìdárayá tí ó dárajùlọ fún ọkàn tí a fúnni.”4 Dípò àfiwé, a lè gbóríyìn fún àwọn wọnnì tí à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí. Ẹ ṣé àbápín àtinúwá ohun ìmọyì nípa wọn tàbí àwọn ẹbí wọn.

Bí Páùlù ṣe rán wa létí, gbogbo wa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ara Krístì, àti pé nígbàtí “ọ̀kan nínú ọmọ ẹgbẹ́ bá gbayì, gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yíò yayọ̀ pẹ̀lú rẹ̀” (1 Kọ́ríntì 12:26). Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run, a lè nífura àwọn ìrírí ti àwọn ẹlòmíràn, ṣayẹyẹ àwọn àṣeyege nlá àti kékeré, rànwọ́n lọ́wọ́ láti da ọwọ́ Olúwa mọ̀, àti láti borí owú nítorí kí a lè yayọ̀ papọ̀ lódodo nínú àwọn ìbúkún, ẹ̀bùn, àti ìdùnnú àwọn ẹlòmíràn.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Bonnie H. Cordon, “Dída Olùṣọ́ Àgùntàn,” Liahona, Oṣù Kọkànlá (Belu). 2018, 75.

  2. Bonnie H. Cordon, “Dída Olùṣọ́ Àgùntàn,” 75.

  3. Quentin L. Cook, “Yayọ̀!” Ensign, Nov. 1996, 30.

  4. Jeffrey R. Holland, “Oninakuna Míràn,” Liahona, Oṣù Karun (Èbìbí). 2002, 64.