“Ṣíse Iṣẹ́ Ìránṣe nípasẹ̀ Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa,” Làìhónà, June 2020
Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2020
Ṣíse Iṣẹ́ Ìránṣe nípasẹ̀ Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa
Ìpàdé oúnjẹ Olúwa npèsè àwọn ànfàní láti sopọ̀ pẹ̀lú kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn elòmíràn.
Ìpàdé oúnjẹ Olúwa ni àkokò kan fún ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí àti ríronú ti ara ẹni lórí Olùgbàlà àti Ètùtù Rẹ̀. Bí a ṣe nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, à ndi gbígbéga papọ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:110). Ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ nínú àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ká wa nmú àwọn àjàgà wíwúwo wá pẹ̀lú wọn tàbí wọn kò sí níbẹ̀ rárá.
Nihin ni àwọn ànfàní díẹ̀ fún bí a ṣe lè lo wákàtí mímọ́ náà látì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn kí a sì mú ìyàtọ̀ kan wá sí inú ayé wọn.
Ẹ Ṣe Ìrànwọ́ láti Mú Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa Dárasi fún àwọn Wọnnì Tí Ẹ̀ Nṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Sí
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú kíkọ́ bí ẹ ti le ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni láti mọ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ẹbí náà àti àwọn àìní wọn. Àwọn ọ̀nà lè wà tí ẹ fi lè ṣe ìrànwọ́ mú kí ìrírí ìjọsìn oúnjẹ Olúwa wọn dárasi nípa kí ẹ kàn fi ìrọ̀rùn kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa wọn.
Fún Mindy, ọ̀dọ́ ìyá kan ti àwọn ìbejì ọmọ-ọwọ́ , àwọn aápọn ìrọ̀rùn ṣíṣe ti arábìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ mú ìyàtọ̀ nlá wá nínú ìrírí rẹ̀ ní ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
“Nítorí ìlàsílẹ̀ iṣẹ́ ọkọ mi, mo máa ngbé àwọn ọmọbìnrin ìbejì wa lọ sí ilé-ìjọsìn fúnra mi ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀,” Mindy ṣe àlàyé. Ó jẹ́ ohun bíbonimọ́lẹ̀ lõtọ́ láti gbìyànjú láti la gbogbo ìpàdé oúnjẹ Olúwa kọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọwọ́ aláápọn méjì , ṣùgbọ́n aràbìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ mi ti gbàá lé ara rẹ̀ láti ràn mí lọ́wọ́.
“Ó máà njoko pẹ̀lú wa ó sì nràn mi lọ́wọ́ láti tọ̀jú àwọn ọmọdébìnrin mi ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. “Jijoko rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ mi ní ìtumọ̀ sí mi púpọ̀, ó sì nmú àníyàn mi rọrùn lõtọ nínú àkokò ìrunú tàbí ìdàlù wọn. Èmi kò rò pé òun lè mọ̀ bí ìṣe rẹ̀ ṣe ní ipá sí mi tó ní àkókò yí nínú ìgbé ayé mi. Ó rí àìní mi bí ọ̀dọ́ ìyá , tí ó kún fún àníyàn, ó sì ṣe ìrànwọ́ láti mú ilé-ìjọsìn jẹ́ alálàáfìà àti ibi aláyọ̀ fún gbogbo wa.”
Àwọn Èrò láti Ṣe Ìrànwọ́ fún Àwọn Wọnnì pẹ̀lú àwọn Àìní kan Pàtó.
-
Jíhìn padà sí iyejú àwọn alàgbà àti àwọn olórí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ nípa àwọn àìní àwọn ọmọ ìjọ.
-
Àwọn olórí máa nṣètò àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé oúnjẹ Olúwa látì rànwá lọ́wọ́ láti bá àìní àwọn ọmọ ìjọ pàdé. Bí àwọn wọnnì ti ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí yío bá jèrè láti inú gbígbọ́ ọ̀rọ̀ kan pàtó, ẹ pín èrò náà pẹ̀lú àwọn olórí yín.
-
Bí ẹ bá mọ̀ pé ẹnìkan ní àìlera kan tàbí ẹ̀hùn oúnjẹ tí ó ndí wọn lọ́wọ́ láti gbádùn àwọn ìbùkún oúnjẹ Olúwa, ẹ bèèrè lọ́wọ́ wọn ní kíníkíní àti irú àwọn àyè ìgbàmọ́ra tí a lè ṣe láti mú ìrírí ìjọ́sìn wọn gbèrú si. Ẹ pín ìwífúnni yí pẹ́lú áwọn olórí yín.
-
Bí ẹnìkan tí ẹ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí tàbí mọ̀ nípa rẹ̀ kò bá lè jáde ní ilé, bóyá ní pípẹ́-títí tàbí fún ìgbà díẹ̀ , ẹ bèèrè lọ́wọ́ bíṣọ́ọ̀pù yín tí a bá lè fún wọn ní oúnjẹ Olúwa ní ilé. Àní ẹ lè ṣe àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa kí ẹ sì pín wọn ní orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, nípa ìwé àtẹ̀ránṣẹ́ ayélujára, tàbi fúnra ẹni.
-
Bí ẹnìkan tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí bá ní àwọn ọmọdé, ẹ lè gbà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìpàdé oúnjẹ Olúwa.
-
Bí àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí kò bá wá sí ìpàdé oúnjẹ Oluwa déédé, ẹ gbìyànjú láti ní òye kí ẹ sì gbèrò àwọn ọ̀nà tí ẹ fi lè ṣe ìrànwọ́. Bí wọ́n bá nílò wíwọ ọkọ̀, ẹ lè gbà láti máa gbé wọn. Bí wọ́n bá ní ìmọ̀lára àìní-àtìlẹhìn láti ọ̀dọ̀ ẹbí wọn, ẹ lè pè wọ́n láti joko pẹ̀lú yín. Ẹ lè ṣe àwọn ìpè pàtàkì láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìwúrí àti fífẹ́ ní ibi ìpàdé oúnjẹ Olúwa.
Ẹ rántí, àwọn Ìṣesí Ìrọ̀rùn Máa Nlọ Jìnnà pẹ́ Títí
Sísọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, Arábìnrin Jean B. Bingham, Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Gbogbogbò, kọ́ni pé: “Nígbàmíràn a nró pé a níláti ṣe ohun ọlọ́lá àti ti akọni kan láti ‘kà’ bí sísin àwọn aladugbo wa. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ìṣe ìrọ̀rùn ti iṣẹ́ ìsìn lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí àwọn ẹlòmíràn—bíi ní orí ti ara wa pẹ̀lú.”1
Nínú wọ́ọ̀dù kékeré kan ní Belgium, Evita gbà láti ṣe àyípadà èdè fún àwọn àlejò àti àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nsọ Spanish nínú àwọn ìpàdé Ìjọ. Nígbà kan, a fi Evita han sí ẹnìkan láti Orílẹ̀-èdè Dominican ẹnití ó nkọ́ nípa Ìjọ. Ó mọ Èdè-gẹ̀ẹ́sì díẹ̀, ṣùgbọ́n Spanish jẹ́ èdè àbínibí rẹ̀. Nítorínáà Evita gbà láti ṣe àyípadà-èdè fún un jẹ́ẹjẹ́ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa nítorínáà ó ní ìmọ̀lára ìtura síi.
“Ṣíṣe àyípadà èdè lè fì ìgbàmíràn mú Ọjọ́-ìsinmi mi lè si díẹ̀,” Evita sọ. “Ṣùgbọ́n títẹ̀lé àwọn ìṣílétí láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n bá nílò olùyírọ̀padà kan dájúdájú nfún mi ní ìmọ̀lára ayọ̀ àti ìwúrí ní mímọ̀ pé mo lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí kí wọn ó sì gbàdùn àwọn ìpàdé wọn.”
Àwọn èrò láti Rànwá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn Ìṣesí Ìrọ̀rùn
-
Ẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí yín láti wo ẹni tí o lè nílò àfikún iṣẹ́ ìsìn kékeré ní àkókò ìpàdé oúnjẹ Olúwa. Tàbí tí ẹ bá mọ ẹnìkan tí ó nílò rẹ̀, ẹ ri dájú pé àwọn olórí yín mọ̀ nípa wọn.
-
Ẹ joko jẹ́jẹ́ bí ẹ ti ndúró fún ìpàdé láti bẹ̀rẹ̀. Èyí yíò ṣe ìrànwọ́ fún “àwọn ọkàn oníròbìnújẹ́ míràn àti àwọn ẹmí bíbanújẹ́ tí ó yí wa ká”2 tí wọ́n nílò àláfíà tí ó nwá nípasẹ̀ ọ̀wọ̀ nínú ibi mímọ́ kan.
-
Ní Ọjọ́-ìsinmi àwẹ̀, ẹ gbèrò yíya àwẹ̀ gbígbà àti àdúrà yín sí mímọ́ sí ẹnìkan tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí tí ó lè nílòàfikún ìtùnú.
-
Ẹ gbàdúrà láti mọ bóyá ẹnìkan wà tí ó lè jèrè nínú jíjoko yín ní itòsí tàbí ní ẹ̀gbẹ wọn ní àkókò ìpàdé oúnjẹ Olúwa tàbí tí àwọn ọ̀nà míràn bá wà tí ẹ fi lè ṣe ìrànwọ́.
Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa Lè jẹ́ Ibi Ìkínikáàbọ̀ fún Gbogbo Ènìyàn
Ààrẹ Joseph Fielding Smith (1876–1972) kọ́ni pé, “Ìpàdé oúnjẹ Olúwa ni ọ̀wọ̀ jùlọ, mímọ́ júlọ, nínú gbogbo àwọn ìpàdé ti Ìjọ.”3 Ní ọ̀nà bẹ́ẹ̀ pé , ó ṣe pàtàkì láti ri dájú pé gbogbo ẹnití ó nlọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ìmọ̀lára ìkínikáàbọ̀ àti bíbọ́ ti ẹ̀mí—nípàtàkì àwọn ọmọ ìjọ titun tàbí àwọn ọmọ ìjọ tí kò wá fún ìgbà díẹ̀.
Merania láti South Wales Titun, Australia, bá obìnrin kan tí ó nkọ́ nípa Ìjọ nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀ dá ọrẹ. “Ó ti di ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n nísisìyí,” ni Merania sọ. Mo nifẹ jijoko pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, àti pé mò nfi gbogbo ìgbà bèèrè bí òun ṣe nṣe àti bóyá ohun kan wà tí mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.” Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, ọ̀rẹ́ Merania ṣe ìrìbọmi Àwọn aápọn ti àwọn ọmọ ìjọ, àti bíi ti àyíká ìkínikáàbọ̀ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa, kó ipá nlá nínú ìpinnu rẹ̀.
Àwọn Èrò láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí Àwọn Tí wọ́n npadàbọ̀ tàbí àwọn Ọmọ Ìjọ Titun
-
Nígbàtí ẹ bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa, ẹ lè pe àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, àti àwọn ẹlòmíràn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ yín.
-
Ẹ lè wò fún kí ẹ sì ṣe ìkínikáàbọ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n dá wà tàbí tí wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́. Ẹ bèèrè bí ẹ bá lè joko nítosí wọn tàbí pè wọ́n láti joko pẹ̀lú yín.
-
Nígbàtí ìpàdé bá parí ẹ lè pe àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àti àwọn ẹlòmíràn sí àwọn ètò Ìjọ tí ó nbọ̀, sí tẹ́mpìlì, tàbí sí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbákẹ́gbẹ́ kan.
-
Bí ẹnìkan tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí bá nlọ ìpàdé oúnjẹ Olúwa ṣùgbọ́n tí kò wá fún ìgbà díẹ̀, ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ wọn tí wọ́n bá ní àwọn ìbèèrè nípa ohun tí a kọ́ni. Ẹ sọ fún wọn pé ààyè wà fún wọn nígbàgbogbo láti dé ọ̀dọ̀ yín fún ọ̀rọ̀, ìtàn, tàbí ẹ̀là ẹ̀kọ́ kan tí kò yé wọn. Ẹ lè jọ wo àwọn ìdáhùn papọ̀ tí ó bá ṣeéṣe.
© 2020 Láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹẹ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì 6/19. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/19. Àyípadà èdè ti Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2020. Yoruba. 16988 000