2020
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípa àwọn Ṣíṣe Ìṣe Ìjọ
Oṣù Keje 2020


“Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípa àwọn Ìṣe Ìjọ,” Làíhónà, Oṣù Kéje 2020

iṣẹ́ ìránṣẹ́

Àwòrán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ngbé àgọ́ kalẹ̀ nípasẹ̀ Bud Corkin; áwòrán ọmọdébìnrin tí ó ngbé tábìlì kalẹ̀ nípasẹ̀ Price McFarland; àtilẹ̀wá láti ọwọ́ Àwòrán ti Getty

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kéje 2020

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípa àwọn Ìṣe Ìjọ

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́ Olùtẹ̀wé: Nkan yí ni a dá sílẹ̀ ṣíwájú àjàkálẹ̀ àrùn, COVID-19. Àwọn àbá kan nísàlẹ̀ kò ní ṣeélò ní àwọn ìgbà jíjìnà síra ìbákẹ́gbẹ́ ṣùgbọ́n yíò di lílò lẹ́ẹ̀kansi tí àwọn ìpàdé Ìjọ àti ṣíṣe Ìjọ bá bẹ̀rẹ̀. Tí nínílò bá wà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbá àwọn àbá wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ìtọ́sọ́nà ìjọba àti Ìjọ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ọ̀nà kan tí a fi lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọlàkejì ọmọ wọ́ọ̀dù wa, aladugbo, àti ọ̀rẹ́ ni nípasẹ̀ àwọn ṣíṣe ìṣe Ìjọ . Bóyá ẹ ṣètò ṣíṣe kan yíká àwọn ìnílò tàbí ìfẹ́ ẹnìkan tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí tàbí tí ẹ pè wọ́n láti kópa nínú àwọn ṣíṣe tàbí ànfàní iṣẹ́ ìsìn sí àwọn ẹlòmíràn, àwọn ṣíṣe ní wọ́ọ̀dù, èèkàn, tàbí àní ọ̀pòlọpọ̀-èèkàn lè pèsè àwọn ọ̀nà onítumọ̀ àti ìyánilórí láti mú ìrẹ́pọ̀ àti ìfúnnilókun àwọn ọmọ Ìjọ.

Àwọn ṣíṣe Ìjọ bákannáà lè ṣí ilẹ̀kùn ọnírurú ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Fún àpẹrẹ, àwọn ṣíṣe Ìjọ lè pèsè àwọn ànfàní láti kópa nínú àwọn iṣẹ́ ìsìn tí ó nbùkún àwọn ẹlòmíràn àti tí ó ngbé àwọn ìbáṣepọ̀ ga nínú ìletò. Àwọn ṣíṣe Ìjọ bákannáà lè jẹ́ ààyè láti nawọ́ jáde sí àwọn ọmọ Ìjọ tí kìí wá déèdé àti sí àwọn ọ̀rẹ́ ti ìgbàgbọ́ míràn tàbí àwọn ọ̀rẹ́ láìsí ìsopọ̀ ẹ̀sìn kankan.

Fífi Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sínú àwọn ṣíṣe-ìṣe Ìjọ ndá ànfàní kan sílẹ̀ fún Olúwa láti bùkún àti láti fún àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ká wa lókun, àwọn aladugbo wa, àti àwọn ìletò.

Mímú Àwọn Ìbáṣepọ̀ tí ó Nítumọ̀ Dàgbà sóké

Ìgbà òtútù nbọ̀, àti pé David Dickson kò ní èrò bí yìó ṣe lè pa ẹbí rẹ̀ mọ́ ní lílọ́.

David, ìyàwó rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin méjì ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sí ìlú nlá ti Fredonia, Arizona, USA, ibi ìpatì-gíga kan tí òkè pupa ọlọ́lá, sagebrush, àti aláwọewé kan yíká.

Ilé tí àwọn Dickson ti yágbé gbẹ́kẹ̀lé sítófù igi-jíjó bíi kókó orísun ìgbóná. David kẹkọ kíákíá pe kíkó igi ìdáná jọ jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì nítorí ìgbà òtútù ní Fredonia kún fún yìnyín àti omi dídì.

“Èmi kò ní igi ìdáná kankan tàbí agégi tàbí àní ìmọ̀ bí èmi ó ṣe lo ọ̀kan!” David wípé. “Èmi kò mọ ohun tí èmi ó ṣe.”

Àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù kan bèèrè lọ́wọ́ David bí ẹbí rẹ̀ bá ní igi tó tó láti mú wọn la ìgbà òtútù kọjá. “Kò pẹ́ tí wọ́n ti damọ̀ pé èmi kò ní,” ni David wí. “Àwọn alàgbà iyejú láìpẹ́ gbà láti ran mi lọ́wọ́ láti kó igi jọ. Ní ìbòmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìmoore, mo tẹ́wọ́gba ìfúnni wọn.”

David láìpẹ́ ri pé ìrìnàjò kíkó igi jọ jẹ́ ọ̀kannáà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣètò-dáadáa, ìtòsílẹ̀-dáadáa, àti lílọ-dáadáa sí àwọn ṣíṣe-ìṣe wọ́ọ̀dù. Òwúrọ̀ Sátidé kan, David, àwọn alàgbà iyejú, àti àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù míràn doríkọ òkè ní kárávánì àwọn ọkọ̀ akẹ́rù àti ọkọ̀ tírélà.

“Ní ọ̀sán kanṣoṣo, ọpẹ́ fún àwọn ohun èlò wọn àti níní-òye, àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù pèsè ìsopọ̀-igi fún ẹbí mi tí a lò pẹ́ fún púpọ apákan ìgbà òtútù méjì,” ni David wí. ”Àní ní pàtàkì síi, a kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo nílò láti mọ̀ nípa kíkójọ igi fúnra mi. Ní ìgbà tí mo fi Fredonia sílẹ̀, mo mọ̀ bí èmi ó ṣe di ẹ̀rọ-agegi mú, mo ṣèrànwọ́ pẹ̀lú ṣíṣe ìkójọ̀-igi fún àwọn wọ́ọ̀dù síi ju bí mo ṣe lè kà lọ.”

Irú àwọn ṣíṣe-ìṣe wọ́ọ̀dù kìí gbé àwọn ìbáṣepọ dáadáa ga ní àárín àwọn ọmọ Ìjọ nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó ngbé àwọn ìbáṣepọ̀ dáadáa ga pẹ̀lú gbogbo ènìyàn nínú ìletò.

”Mo rántí obínrin kan, kìí ṣe ọmọ Ìjọ, ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé àgbegbè náà,” ni David wí. ”Òun ti dínkù ní jíjó igi kíkójọ látinú ilé rẹ̀ láti wà ní lílọ́. Nígbà tí a kọ́ nípa àníyàn rẹ̀, a mu dájú pé ó ní igi-ìdáná tó tó láti la ìgbà òtútù kọjá. Ó dúpẹ́ dé bi pé ó fẹ́rẹ̀ má lè sọ̀rọ̀.”

Ìtiraka Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ ní Fredonia mudájú pé gbogbo ènìyàn dúró láìléwu àti ní lílọ́ ní ìgbà òtútù.

Nínawọ́ Jáde Sí àwọn Ẹlòmíràn

Nígbàtí mò nsìn ní Míṣọ̀n Romania, Meg Yost àti ojúgbà rẹ̀ bẹ ẹbí kan tí kò wá sí ilé-ìjọsìn fún ìgbà pípẹ́ wo léraléra. “Àwọn Stanica wà ní ara àwọn ọmọ Ìjọ àkọ́kọ́ ní Romania,” Meg wípé, “àti pé a nifẹ wọn.”

Nígbàtí àkokò yá láti ṣètò àti láti ṣe ìtò ṣíṣe-ìṣe ẹ̀ká kan, àwọn olórí pinnu pé ẹ̀ká yíò ní “Alẹ́ Olùlànà” kan. Èyí yíò jẹ́ ìrọ̀lẹ́ kan láti ṣayẹyẹ àwọn olùgboyà olùlànà tí wọ́n sọdá United States láti dé Àfonífojì Salt Lake. Yíò jẹ́ ànfàní bákannáà láti buọlá fún àwọn olùlànà Ìjọ ní Romania.

“A ròó pé yíò jẹ́ ọ̀nà nlá fún àwọn ọmọ ìjọ kan láti jẹ́ ẹ̀rí nípa ìyípadà-ọkàn wọn àti bí wọ́n ṣe ri tí Ìjọ ndàgbà ní Romania,” ni Meg wí. “Lọ́gán a ròó pé ẹbí Stanica gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ si. A pè wọ́n láti kópa, inú wọn sì dùn!”

Ní alẹ́ ọjọ́ ṣíṣe-iṣe, àwọn Stanica kò tíì dé nígbàtí àkokò tó láti bẹ̀rẹ̀.

“A nídàmú pé wọn kò tíì wá,” Meg rantí. “Ṣùgbọ́n ní àkokò, wọ́n rìnwọlé látẹnu ilẹ̀kùn. Àwọn Stanica jẹ́ ẹ̀rí dídára nípa ìhìnrere àti Ìjọ. Bákannáà wọ́n ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ míràn ẹnití wọn kò rí fún ìgbà pípẹ́.”

Àwọn ọmọ ẹ̀ká náà na ọwọ́ wọn ní ìkínni káàbọ̀ sí àwọn Stanica. Ọjọ́ Ìsinmi tó tẹ̀le, ó ya Meg lẹ́nu dáadáa láti rí Arábìnrin Stanica ní Ìjọ.

“Nígbàtí mo bẹ ẹ̀ka náà wò ní oṣù díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ó ṣì nwá!” Meg wípé. “Mo ronú pé ààyè láti jẹ́ ẹ̀rí rẹ̀ àti láti nímọ̀lára ìlọ́wọ́sí àti ìnílò ní ẹ̀ka náà ràn an lọ́wọ́ nítòòtọ́.”

Àwọn èrò mẹ́rin nípa àwọn Ṣíṣe-ìṣe Ìjọ

  • Ṣètò àwọn ṣíṣe ìṣe tí ó bá àwọn ìnílò mu: Àwọn ṣíṣe-ìṣe jẹ́ ọ̀nà nlá láti bá àwọn ìnílò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pàdé. Wọ́n lè máà ṣètò wọn láti bá àwọn ìnílò ti ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹgbẹ́ pàdé. Bákannáà wọ́n gbọ́dọ̀ bá àwọn ìnílò àwọn wọnnì tí wọ́n kópa pàdé, bóyá ìnílò náà ni láti mọ ara wọn dáradára si, kẹkọ si nípa ìhìnrere, tàbí nímọ̀lára Ẹ̀mí.

  • Pe gbogbo ènìyàn: Bí ẹ ti nṣètò àwọn ṣíṣe, ṣe ìtiraka pàtàkì kan láti pe àwọn ẹni tí yíò jèrè látinú kíkópa. Ẹ rántí àwọn ọmọ ìjọ titun, àwọn ọmọ ìjọ tí kìí wá déédé, àwọn ọ̀dọ́, àwọn àgbà àdánìkanwà, àwọn ènìyàn pèlú àìlera, àti àwọn ènìyàn ìgbàgbọ́ míràn. Nawọ́ ìpè pẹ̀lú ìfẹ́ wọn tojùlọ lọ́kàn, kí ẹ sì fi bí ẹ ó ṣe nifẹ pé kí wọ́n wa hàn.

  • Ẹ gbani-níyànjú kíkópa: Àwọn wọnnì tí ẹ pè yíò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi nínú àwọn ṣíṣe-ìṣe tí wọ́n bá ní ànfàní láti kópa. Ọ̀nà kan láti gbani-níyànjú kíkópa ni láti jẹ́ kí àwọn ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan lo àwọn ẹ̀bùn wọn, iṣẹ́, àti tálẹ́tì nínú ṣíṣe-ìṣe náà.

  • Ẹ kí gbogbo ènìyàn káàbọ̀: Bí àwọn ọ̀rẹ́ yín bá lọ sí ibi ṣíṣe-ìṣe kan, ẹ ṣe ohun gbogbo ti ẹ lè ṣe láti mú wọn nímọ̀láraìkíni-káàbọ̀. Bákannáà, bí ẹ bá rí àwọn ènìyàn tí ẹ kò mọ̀, ẹ bá wọn ṣọ̀rẹ́ kí ẹ sì kí wọn káàbọ̀ pẹ̀lú!