2020
Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni
Oṣù Kẹ́jọ 2020


“Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́jọ 2020.

ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹ́jọ 2020

Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni

Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ni pípèsè àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ọ̀ná ti Olúwa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ọmọ ẹbí wa, ọ̀rẹ́, àti aladugbo ní ìfẹ́ sí dída olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni si. Lílo ètò ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ti Ìjọ, àwọn ọmọ Ìjọ nrí àwọn ànfàní láti sìn, tọ́jú, àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí wọ́n ti nbùkún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ tí ó nmú “ìrètí títóbi jùlọ, àlàfíà, àti ìlọsíwájú wá.”1

“Èmi Wà Nílé”

Làti ọwọ́ Chrissy Kepler, Arizona, USA

Mò nlàkàkà nípa ìṣúná-owó nítítẹ̀lé ìkọrasílẹ̀ kan, ní ìgbìyànjú láti wá ọ̀nà mi padà sínú iṣẹ́-ṣíṣe lẹ́hìn jíjẹ́ ìyá olùdúró-sílé fún ọdún mẹ́jọ. Mo nlàkàkà níti-ẹ̀mí bákannáà, ní wíwa òtítọ́ àti ìgbàgbọ́, bíótilẹ̀jẹ́pé èmi kò tẹsẹ̀bọ̀ inù ilé-ìjọsìn kankan látìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́.

Ní Ọjọ́ ìsinmi kan mò nfọ aṣọ mi ní ilé arábìnrin mi àgbà, Priscilla, tí ó jẹ́ aláápọn ọmọ Ìjọ. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, Priscilla pè mí láti wá sí ìjọ pẹ̀lú ẹbí rẹ̀—ìpè àkọ́kọ́ mi ní ọdún máàrúndínlògún ó lé.

Mo lọ́ra lakọkọ, ṣùgbọ́n ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣíwájú, mo ti bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run láti fihàn mí bí èmi ó ṣe súnmọ́ Ọ. Lẹ́hìn níní ìmọ̀lára ìjàkadì kan nínù, mo parí pé, “Kílódé tí ó kò lọ láti ríi funrarẹ bí àgbà pẹ̀lú ọkàn àti ojú ara rẹ?”

Nígbàtí a wà ní ìpàdé oúnjẹ Olúwa, mo ṣàkíyèsí ìwé kan nínú ìwé-ìdarí Ọjọ́-ìsinmi tí ó kéde ẹ̀kọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni kan lórí ìṣúná-owó ẹni. Èmi kò ṣetán láti padà sí ìjọ, ṣùgbọ́n mo ní ìfámọ́ra sí ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ méjìlá náà. Pẹ̀lú ìgbìyànjú látọ̀dọ̀ arábìnrin mi àti ọkọ rẹ̀, mo forúkọ sílẹ̀, ní ìrètí láti kọ́ bí èmi ó ṣe máa ṣe ìṣúná-owó nìkan àti láti san gbèsè kúrò. Àwọn kíláàsì, bákannáà, yí mi padà níti-ẹ̀mí.

Mo ní ìyàlẹ́nu nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ti-ẹ̀mí ní àwọn ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ti kíláàsì, ṣùgbọ́n nínú kíláàsì kẹ́ta, mo ní ìbonimọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára ti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ pé mo wà nílé mo sì ngbọ́ àwọn òtítọ́ titun tí mo ti mọ̀. Mo kúrò ní kíláàsì mo sì wakọ̀ tààrà lọ rí Priscilla. Nínú omijé, mo bì í léèrè, “Báwo ni mo ṣe lè gba ìmọ̀lára yí si nínú ayé mi?” Ó ṣètò fún àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere láti bẹ̀rẹ̀ sí nkọ́ mi.

Àwọn ọmọ kíláàsì ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni mi nwá síbi àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere wọ́n sì tímílẹ́hìn. Wọ́n ṣé ohun tó nípá pípẹ́ lórí ẹ̀mí mi wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ láti mú ẹ̀rí mi gbèrú nípa ìhìnrere ati àwọn wòlíì òde-òní.

Ní àkokò tí ó gbà mí láti parí ẹ̀kọ́ náà, mo ṣe onírurú àwọn ìyípadà ti ara àti ti ẹ̀mí. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ titun kan pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ rere kan, mo sì san ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn owó-yíyá kúrò.

Ṣùgbọ́n jinlẹ̀jinlẹ̀, àwọn ìbùkún dídùn tí ó wá látinú ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú dídá ìbáṣọ̀rẹ́ dídára sílẹ̀, gbígbèrú ìbáṣepọ̀ rere pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù olùgbani-níyànjú, wíwá ẹ̀rí idamẹwa, gbígba ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, jíjẹ́ rirólágbára, àti rírí àwọn ọmọ mi àgbà méjì tí wọ́n ṣe ìrìbọmi.

Ipá ọ̀nà mi sí ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ṣì nfarahàn, ṣùgbọ́n fún ìrìnàjò mi tó kù, èmi yíò ṣìkẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ náà tí mo ti kọ́ àti àwọn ìbáṣọ̀rẹ́ tí mo ti ṣe.

“Mo kúrò ní Kíláàsì Kọ̀ọ̀kan Níní Ìmọ̀lára Ìfẹ́ni”

Nígbàtí ó bẹ Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì ní Ìlú Nlá Salt Lake , Utah, wo pẹ̀lú ọmọdékùnrin ọmọ ọdún mẹwa rẹ̀, ní Oṣù Kejìlá 2016, Katie Funk gbèrò ara rẹ̀ bí “olùtura aláìgbàgbọ́.” Ó fi Ìjọ sílẹ̀ ní ọmọ ọdún mẹrindínlógún, ó dí ìyá àdánìkanwà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó bẹ̀rẹ̀ sí nya tàtúù, ó sì gbèrú si ní kọfí mímú. Ṣùgbọ́n nígbà ìbẹ̀wò Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì, Vincent nímọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́ ó sì bèèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ bí òun bá lè gba àwọn ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere.

Bíótilẹ̀jẹ́pé iṣẹ́ rẹ̀ méjì, ọgọ́rin wákàtí iṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, Katie ṣàṣàrò ìhìnrere pẹ̀lú Vincent, ní ṣíṣé ìwákiri àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè rẹ̀ ní àárín àwọn ìbẹ̀wọ̀ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Ní ìgbà ooru ti 2017, ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé Ìjọ, níbití ó ti kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Ìjọ.

“Mo damọ̀ pé àwọn nkan tó lè ràn mí lọ́wọ́ ni,” ni ó sọ. “Bóyá èmi kò ní nílò láti ṣiṣẹ́ méjì tàbí gbáralé àwọn òbí mi fún ìyókù ayé mi.”

Katie pe ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní “ìfúnnilókun líle ti ara àti ti ẹ̀mí,” kìí ṣe nítorí ohun tí ó kọ́ lásán ṣùgbọ́n bákannáà nítorí bí ẹgbẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni rẹ̀ ṣe tẹ́wọ́ gbà á tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí i.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. “Ọ̀rọ̀ látẹnu Àjọ Ààrẹ Kínní,” nínú Ìṣúná Araẹni fún Ìgbẹ́kẹ́lé-araẹni (2016), i.