Làìhónà
Jésù Súre fún ní Ọ̀kàn sí Ọ̀kan
Oṣù Kẹwa 2024


“Jésù Súre fún ní Ọ̀kàn sí Ọ̀kan,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹwa 2024, 26–27.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹwa 2024

Jésù Súre fún ní Ọ̀kàn sí Ọ̀kan

Àwọn Wòlíì nkọ́ àwọn ará Néfì

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Àwọn Wòlíì kọ́ àwọn ará Néfì nípa àwọn àmì ikú Jésù Krístì. Nígbàtí Ó kú, òkùnkùn wà ní ilẹ̀ náà fún ọjọ́ mẹ́ta. Lẹ́hìnnáà, àwọn ènìyàn gbọ́ ohùn Baba Ọ̀run tí Ó nsọ̀rọ̀ láti ọ̀run.

Jésù Krístì ṣè ìbẹ̀wò sí àwọn Ará Néfì

Baba Ọ̀run wípé, “Ẹ kíyèsí Àyànfẹ́ Ọmọ mi” (3 Nefi 11:7). Jésù farahàn sí àwọn Ará Néfì. Ó ti jínde! Ó kọ́ àwọn ará Néfì ní àwọn ohun púpọ̀. Jésù wí fún wọn láti ronúpìwàdà kí wọ́n sì tẹ̀lé Òun.

Jésù nwo àwọn aláìsàn sàn

Ó ní kí àwọn ènìyàn gbé àwọn wọnnì tí wọ́n nṣe àìsàn wá sọ̀dọ̀ Rẹ̀ láti gba ìwòsàn. Ó súre fún wọn.

Jésù nsúre fún àwọn ọmọdé

Bákannáà ó súre fún gbogbo àwọn ọmọdé ní ọ̀kan sí ọ̀kàn. Àwọn ángẹ́lì yí àwọn ọmọdé ká.

Kíkùn Ojú-ewé

Olùgbàlà Fẹ́ràn Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ọmọ Baba Ọ̀run

Kíkùn Ojú-ewé

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

Báwo ni ẹ ṣe nní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà?