Làìhónà
Néfì Rí Jésù Ọmọ-ọwọ́
Oṣù Kejìlá 2024


“Néfì Rí Jésù Ọmọ-ọwọ́,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2024, 26–27.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kejìlá 2024

Néfì Rí Jésù Ọmọ-ọwọ́

Léhì nkọ́ Néfì, Néfì sì ngbàdúrà

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Baba Néfì, Léhì, rí ìran kan nípa Jésù Krístì. Néfì nfẹ́ láti rí ìràn yí bákannáà. Ó gbàdúrà ó sì bèèrè láti rí ohun tí baba rẹ̀ rí.

Néfì rí Màríà nínú ìran kan.

Ẹ̀mí Mímọ́ fi irú ìran kannáà hàn Néfì. Néfì rí ọ̀dọ́mọbìrin kan tí a npè ní Màríà. Ẹ̀mí Mímọ́ wípé òun yíò jẹ́ ìyá Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run.

Néfì nrí Máríà àti Jésù ọmọ-ọwọ́ nínú ìran kan.

Néfì rí Jésù ọmọ-ọwọ́ pẹ̀lú Màríà. Ẹ̀mí Mímọ́ wípé Jésù yíò wá sí ilẹ̀-ayé láti ran àwọn ọmọ Baba Ọ̀run lọ́wọ́.

Néfì nkọ ìran rẹ̀ sílẹ̀; ọmọdébìrin nka àwọn ìwé mímọ́

Néfì rí ìgbésí ayé Jésù Krístì. Ó rí I tí ó nsìn tí Ó sì nkọ́ àwọn ènìyàn. Néfì kọ́ àwọn ohun púpọ̀ nípa Olùgbàlà. Ẹ lè kọ́ nípa Rẹ̀ bákannáà nípa kìka àwọn ìwé-mímọ́.

Kíkun Ojúewé

Ọdún Kérésìmesì jẹ́ nípa Jésù

Kíkùn Ojúwé

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

“Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa” (Isaiah 9:6).