Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 11


Jésù Krístì fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn Nífáì, bí àwọn ọpọ ènìyàn ṣe kó ara wọn jọ nínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, ó sì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn; ní ọ̀nà yĩ ni ó sì fi ara rẹ̀ hàn sí wọn.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 11 títí ó fi dé 26 ní àkópọ̀.

Orí 11

Bàbá jẹ́rĩ nípa Àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀—Krístì fi ara hàn ó sì kéde nípa ètùtù rẹ̀—Àwọn ènìyàn nã fi ọwọ́ bà ojú ọgbẹ́ tí ó wà lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ àti ni ìhà rẹ̀—Nwọ́n kígbe Hòsánnà—Ó ṣe ìkọ́ni nípa ìṣe àti ìlànà ìrìbọmi—Ẹ̀mí ìjà jẹ́ ti ẹ̀ṣù—Ẹ̀kọ́ Krístì ni kí gbogbo ènìyàn ó gbàgbọ́ kí a sì rì wọ́n bọmi, kí wọn ó sì gba Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn kó ara wọn jọ, nínú àwọn ènìyàn Nífáì, yíká tẹ́mpìlì èyítí ó wà ní ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; tí ẹnu sì nyà wọ́n tí wọ́n sì nṣe hà ní ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn, tí wọ́n sì nfi ìyípadà nlá àti ìyanu èyítí ó ti ṣẹ̀lẹ̀ han ara wọn.

2 Wọ́n sì nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú nípa Jésù Krístì yĩ, ẹnití a ti fúnni ní àmì nípa ikú rẹ̀.

3 Ó sì ṣe bí wọ́n ti nsọ̀rọ̀ báyĩ pẹ̀lú ara wọn, wọ́n gbọ́ ohùn kan bí èyítí ó jáde wá láti ọ̀run; wọ́n sì wò yíká kiri, nítorí tí wọn kò ní òye nípa ohùn nã tí wọ́n gbọ́; ohùn líle kọ́ nií sì íṣe, bẹ̃ sì ni kĩ ṣe ohùn kíkan; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àti l’áìṣírò ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó wọ̀ oókan àyà àwọn tí ó gbọ́ lọ, tóbẹ̃ tí kò sí ẹ̀yà ara wọn tí kò mú kí ó mì; bẹ̃ni, ó wọ inú ọkàn wọn lọ, ó sì mú kí ọkàn wọn ó gbiná.

4 Ó sì ṣe tí wọ́n tún gbọ́ ohùn nã, tí kò sì yé wọn.

5 Ní ìgbà kẹ́ta wọ́n tún gbọ́ ohùn nã, wọ́n sì ṣí etí wọn sílẹ̀ láti gbọ́ọ; wọ́n sì kọ ojú wọn sí ohùn nã, wọ́n sì tẹjúmọ́ ọ̀run níbití ohùn nã ti wá.

6 Ẹ sì kíyèsĩ, ní ìgbà kẹ́ta, ohùn nã tí wọ́n gbọ́ yé wọn; ó sì wí fún wọn pé:

7 Ẹ kíyèsí Àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití inú mi dùn sí gidigidi, nínú ẹnití mo ti ṣe orúkọ mi lógo—ẹ gbọ́ tirẹ̀.

8 Ó sì ṣe, bí òye sì ti yé wọn wọ́n sì tún gbé ojú wọn sókè sí ọ̀run; ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n rí Ọkùnrin kan tí ó nsọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run; ti a sì wọ̃ ní aṣọ funfun kan; ó sì sọ̀kalẹ̀ wá ó sì dúró lãrín wọn; ojú gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì yí síi, wọn kò sì la ẹnu wọn, àní láti bá ara wọn sọ̀rọ̀, wọn kò sì mọ́ ohun tĩ ṣe nítorí tí wọ́n rò wípé ángẹ́lì ni ó farahàn wọ́n.

9 Ó sì ṣe tí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn tí ó sì bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ wípé:

10 Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì, ẹnití àwọn wòlĩ jẹ́rĩ sí pé yíò wá sínú ayé.

11 Ẹ sì kíyèsĩ, èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé; èmi sì ti mu nínú ago kíkòrò tí Bàbá fi fún mi, èmi sì ti ṣe Bàbá lógo nípa gbígbé ẹ̀ṣẹ̀ aráyé rù ara mi, nínú èyítí èmi gba ìfẹ́ Bàbá lãyè nínú ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ wá.

12 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ṣubú lulẹ̀; nítorítí wọ́n rántí pé a ti sọọ́ tẹ́lẹ̀ lãrín wọn wípé Krístì yíò fi ara rẹ̀ hàn fún wọn lẹ́hìn tí ó bá ti gòkè re ọ̀run.

13 Ó sì ṣe tí Olúwa bá wọn sọ̀rọ̀ wípé:

14 Ẹ dìde kí ẹ sì wá sí ọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ó lè fi ọwọ́ yín sí ìhà mi, àti kí ẹ̀yin ó lè fi ọwọ́ yín sí ojú àpá ìṣó ni ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ wípé èmi ni Ọlọ́run Ísráẹ́lì, àti Ọlọ́run gbogbo ayé, ti a sì pa fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

15 Ó sì ṣe tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã jáde wá, wọ́n sì fi ọwọ́ wọn sí ìhà rẹ̀, wọ́n sì fi ọwọ́ wọn sí ojú àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀ àti ní ẹsẹ̀ rẹ̀; báyĩ ni wọ́n sì ṣe, tí wọ́n lọ ní ọ̀kọ̃kan títí gbogbo wọn fi lọ, tí wọ́n sì ríi pẹ̀lú ojú ara wọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn kàn, tí wọ́n sì mọ̀ dájúdájú tí wọ́n sì jẹ́rĩ síi pé òun ni ẹnití àwọn wòlĩ kọ nípa rẹ̀, pé ó nbọ̀ wá.

16 Nígbàtí gbogbo wọn sì ti jáde lọ tán tí wọ́n sì ti jẹ́rĩ síi fúnra wọn, wọ́n kígbe pẹ̀lú ohùn kan wípé:

17 Hòsánnà! Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ! Wọ́n sì wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ Jésù, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.

18 Ó sì ṣe tí ó bá Nífáì sọ̀rọ̀ (nítorítí Nífáì wà lãrín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã) ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó jáde wá.

19 Nífáì sì dìde ó sì jáde lọ, ó sì wólẹ̀ níwájú Olúwa ó sì fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀.

20 Olúwa sì pàṣẹ fún un pé kí ó dìde. Ó sì dìde ó sì dúró níwájú rẹ̀.

21 Olúwa sì wí fún un pé: mo fi agbára fún ọ kí ìwọ ó ri àwọn ènìyàn yĩ bọmi nígbàtí èmi bá tún ti gòkè lọ sí ọ̀run.

22 Olúwa sì tún pe àwọn míràn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ̃; ó sì fi agbára láti ṣe ìrìbọmi fún wọn. Ó sì wí fún wọn pé: Ní ọ̀nà yĩ ni ẹ̀yin yíò ṣe ìrìbọmi; kí àríyànjiyàn ó má sì ṣe wà lãrín yín.

23 Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ yín, tí ó sì nífẹ́ àti ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, ní ọ̀nà yĩ ni ẹ̀yin yíò sì rì wọ́n bọmi—Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò sọ̀kalẹ̀ lọ ẹ ó sì dúró nínú omi, ní orúkọ mi ni ẹ̀yin yíò sì rì wọn bọmi.

24 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin yíò sọ, ẹ ó pe orúkọ wọn, ẹ ó wípé:

25 Nítorítí mo ní àṣẹ láti ọwọ́ Jésù Krístì, mo rì ọ́ bọmi ní orúkọ Bàbá, àti ní ti Ọmọ, àti ní ti Ẹ̀mí Mímọ́, Àmin.

26 Nígbànã ni ẹ̀yin ó tẹ̀ wọ́n rì bọ inú omi nã, tí wọn ó sì tún jáde kúrò nínú omi nã.

27 Ní ọ̀nà yĩ ni ẹ̀yin yíò ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi; nítorí ẹ kíyèsĩ, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wípé Bàbá, àti Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ ọ̀kan; èmi sì wà nínú Bàbá, Bàbá sì wà nínú mi, Bàbá àti èmi sì jẹ́ ọkan.

28 Gẹ́gẹ́bí èmi sì ti pàṣẹ fún yín bẹ̃ni kí ẹ̀yin ó ṣe ìrìbọmi. Kí àríyànjiyàn ó má sì ṣe wà lãrín yín, bí ó ti wà ṣãjú àkokò yĩ; bẹ̃ni kí àríyànjiyàn ó má ṣe wà lãrín yín nípa àwọn ohun àfiyèsí tí ó wà nínú ẹ̀kọ́ mi, bí ó ti wà ṣãjú àkokò yĩ.

29 Nítorí lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, ẹnití ó bá ní ẹ̀mí asọ̀ kĩ ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti èṣù nií ṣe, ẹnití íṣe bàbá asọ̀, òun a sì máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú.

30 Ẹ kíyèsĩ, èyí kĩ íṣe ẹ̀kọ́ mi, láti rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan sí òmíràn; ṣùgbọ́n èyĩ ni ẹ̀kọ́ mi, pé kí a mú irú ohun wọnnì kúrò.

31 Ẹ kíyèsĩ, lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, èmi yíò sọ nípa ẹ̀kọ́ mi fún yín.

32 Èyí sì ni ẹ̀kọ́ mi, ó sì jẹ́ ẹ̀kọ́ èyítí Bàbá ti fi fún mi; èmi sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá, Bàbá sì jẹ́ ẹ̀rí nípa mi, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá àti èmi; èmi sì jẹ́rĩ síi pé Bàbá pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo, láti ronúpìwàdà, kí wọn ó sì gbàgbọ́ nínú mi.

33 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbàgbọ́ nínú mi, tí a sì rì bọmi, òun ni a ó gbàlà; àwọn ni ẹnití yíò sì jogún ìjọba Ọlọ́run.

34 Ẹnìkẹ́ni tí kò bá sì gbàgbọ́ nínú mi, tí a kò sì rì bọmi, ni yíò si jẹ́ ẹni ègbé.

35 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé èyí ni ẹ̀kọ́ mi, èmi sì jẹ́rĩ síi pé láti ọ̀dọ̀ Bàbá ni ó ti wá; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbàgbọ́ nínú mi, gbàgbọ́ nínú Bàbá pẹ̀lú; òun sì ni Bàbá yíò jẹ́rĩ nípa mi sí, nítorítí òun yíò bẹ̃ wò pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.

36 Báyĩ sì ni Bàbá yíò jẹ́rĩ nípa mi, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò sì jẹ́rĩ síi nípa Bàbá àti èmi; nítorí Bàbá, àti èmi, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ ọ̀kan.

37 Àti pẹ̀lú mo wí fún yín, ẹ níláti ronúpìwàdà, kí ẹ sì dàbí ọmọdé, kí a sì rì yin bọmi ní orúkọ mi, bíkòrí bẹ̃ ẹ̀yin kò lè rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà rárá.

38 Àti pẹ̀lú mo wí fún yín, ẹ níláti ronúpìwàdà, kí a sì rì yín bọmi ni órúkọ mi, kí ẹ sì dàbí ọmọdé, bí kò bá rí bẹ̃ ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run.

39 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé èyí ni ẹ̀kọ́ mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kọ́lé lé èyí kọ́lé lé orí àpáta mi, ẹnu-ọ̀nà ọrun àpãdì kì yíò sì lè borí wọn.

40 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ju èyí tàbí tí ó dín in kù, tí ó sì pẽ ní ẹ̀kọ́ mi, òun kannã ni ó wá nípa ibi, a kò sì kọ́ọ lé orí àpáta mi; ṣùgbọ́n ó kọ́lé sí órí ìpilẹ̀ iyanrìn, àwọn ẹnu-ọ̀nà ọrun àpãdì sì ṣí sílẹ̀ láti gba ẹni nã wọlé nígbàtí ìkún omi dé tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́ tí ó bìlù wọ́n.

41 Nítorínã, ẹ kọjá lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yí, kí ẹ sì kéde àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ, títí dé gbogbo ìkangun ayé.