Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 20


Orí 20

Jésù pèsè àkàrà àti wáìnì ní ọ̀nà ìyanu ó sì tún fi àmì májẹ̀mú nã fún àwọn ènìyàn nã—Àwọn ìyókù Jákọ́bù yíò wá sí ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, wọn yíò sì jogún àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà—Jésù ni wòlĩ nã bí Mósè, àwọn ará Nífáì sì ni àwọn irú-ọmọ wòlĩ nã—Àwọn tí íṣe ara àwọn ènìyàn Olúwa ni a ó kójọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kí wọn ó simi àdúrà gbígbà, àti fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ nã. Ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó má simi àdúrà gbígbà nínú ọkàn wọn.

2 Ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó dìde kí wọn ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn. Wọ́n sì dìde wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn.

3 Ó sì ṣe tí ó tún bù àkàrà ó sì súre síi, ó sì fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã kí wọn ó jẹ.

4 Nígbàtí wọn sì ti jẹ ó pàṣẹ fún wọn láti bù àkàrà nã, kí wọn ó sì fifún àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã.

5 Nígbàtí wọ́n sì ti fifún àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã tán ó fún wọn ní wáìnì kí wọn ó mu pẹ̀lú, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó fifún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pẹ̀lú.

6 Nísisìyí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã kò mú àkàrà tàbí wáìnì wá, bẹ̃ni àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã kò mú wá;

7 Ṣùgbọ́n nítõtọ́ ni ó fi àkàrà fún wọn jẹ, àti wáìnì fún wọn mu.

8 Ó sì wí fún wọn pé: Ẹnití ó bá jẹ àkàrà yìi jẹ nínú ara mi fún ànfãní ẹ̀mí rẹ̀; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì mu nínú wáìnì yĩ mu nínú ẹ̀jẹ̀ mi fún ànfãní ẹ̀mí rẹ̀; ebi kò sì ní pa ẹ̀mí rẹ̀ tàbí kí òùngbẹ ó gbẹẹ́, ṣùgbọ́n yíò yó.

9 Nísisìyí, nígbàtí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ti jẹ tí wọ́n sì ti mu tán, ẹ kíyèsĩ, wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́; wọ́n sì kígbe pẹ̀lú ohùn kan, wọ́n sì fi ògo fún Jésù, ẹnití wọ́n rí àti tí wọ́n gbọ́.

10 Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọ́n ti fi ògo fún Jésù tán, ó wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ nísisìyí èmi ti parí òfin èyítí Bàbá ti pa laṣẹ fún mi nípa àwọn ènìyàn yĩ, àwọn tí íṣe ìyókù ìdílé Ísráẹ́lì.

11 Ẹ̀yin rántí pé mo wí fún yín, tí mo sì wípé nígbàtí àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah yíò ṣẹ—ẹ kíyèsĩ a kọ wọ́n sílẹ̀, ẹ̀yin ní wọn níwájú yín, nítorínã ẹ gbé wọn yẹ̀wò—

12 Àti lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé nígbàtí a ó mú wọn ṣẹ, nígbànã ni ìmúṣẹ májẹ̀mú tí Bàbá ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, A! ìdílé Ísráẹ́lì.

13 Nígbànã sì ni àwọn ìyókù nã, tí a ti fọ́nká kiri orí ilẹ̀ ayé, ni a ó kó wọn jọ láti ila õrun àti láti ìwọ õrun, láti gúsù àti láti àríwá; a ó sì mú wọn wá sínú ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹnití ó ti rà wọ́n padà.

14 Bàbá sì ti pàṣẹ fún mi pé kí èmi ó fi ilẹ̀ yí fún yín, fún ìní yín.

15 Èmi sì wí fún yín, pé bí àwọn Kèfèrí kò bá ronúpìwàdà lẹ́hìn ìbùkún tí wọn yíò gbà, lẹ́hìn tí wọ́n ti fọ́n àwọn ènìyàn mi ká—

16 Nígbànã ni ẹ̀yin, tí íṣe ìyókù ìdílé Jákọ́bù, yíò kọjá lọ lãrín wọn; ẹ̀yin yíò sì wà ní ãrin nwọn àwọn tí yio pọ̀ púpọ̀; ẹ̀yin yíò sì wà lãrín wọn bí kìnìún lãrín àwọn ẹranko igbó, àti bí ọmọ kìnìún lãrín àwọn agbo àgùtàn, èyítí, bí ó bá kọjá lãrín wọn, yíò tẹ̀ wọn mọ́lẹ̀, yíò tún fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì sí ẹnití yíò gbà wọ́n là.

17 A ó gbé ọwọ́ yín sókè sí órí àwọn ọ̀tá yín, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sì ké kúrò.

18 Èmi yíò sì kó àwọn ènìyàn mi jọ bí ènìyàn tií kó àwọn ìtì rẹ̀ sí ilẹ̀ ilé.

19 Nítorítí èmi yíò ṣe àwọn ènìyàn mi àwọn ẹnití Bàbá ti bá dá májẹ̀mú, bẹ̃ni, èmi yíò ṣe ìwo yín ní irin, èmi yíò ṣe pátákó ẹsẹ̀ yín ní idẹ. Ẹ̀yin yíò sì fọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sí wẹ́wẹ́; èmi yíò sì yà ìkógun wọn sí mímọ́ fún Olúwa, àti ohun ìní wọn fún Olúwa gbogbo ayé. Ẹ sì kíyèsĩ, èmi ni ẹni nã tí ó ṣeé.

20 Yíò sì ṣe, ni Bàbá wí, tí idà ododo mi yíò wà lórí wọn ní ọjọ́ nã; àti pé bí wọn kò bá ronúpìwàdà, yíò ṣubú lé wọn lórí, ni Bàbá wí, bẹ̃ni, àní lé orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí.

21 Yíò sì ṣe tí èmi yíò fi ìdí àwọn ènìyàn mi múlẹ̀, A! ìdílé Ísráẹ́lì.

22 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ènìyàn yĩ ni èmi yíò fi ìdí wọn múlẹ̀ ní ilẹ̀ yĩ, sí ìmúṣẹ májẹ̀mú èyítí èmi dá pẹ̀lú baba yín Jákọ́bù; yíò sì jẹ́ Jerúsálẹ́mù Titun. Àwọn agbára ọ̀run yíò sì wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, àní èmi pãpã yíò wà lãrín yín.

23 Ẹ kíyèsĩ, èmi ni ẹni nã tí Mósè sọ nípa rẹ̀, wípé: Olúwa Ọlọ́run yín yíò sì gbé wòlĩ kan sókè fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yíò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo èyíkeyĩ tí yíò sọ fún yín. Yíò sì ṣe tí olúkúlùkù ọkàn tí kò bá gbọ́ ti wòlĩ nã, òun ni a ó ké kúrò nínú àwọn ènìyàn.

24 Lóotọ́ ni mo wí fún yín, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn wòlĩ láti Sámúẹ̀lì wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lée, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, ni ó jẹ̃rí nípa mi.

25 Ẹ sì kíyèsĩ, ẹyin ni àwọn ọmọ àwọn wòlĩ; irú-ọmọ ìdílé Ísráẹ́lì sì ni ẹ̀yin íṣe; àti ti májẹ̀mú èyítí Bàbá ti bá àwọn bàbá yín dá, nígbàtí ó wí fún Ábráhámù pé: Àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo ìbátan ayé.

26 Nígbàtí Bàbá ti jí mi dìde ni ó kọ́kọ́ rán mi sí ọ̀dọ̀ yín láti bùkúnfún yín nípasẹ̀ mímú olúkúlùkù yín kúrò nínú àwọn ìwà àìṣedẽdé yín; èyĩ sì rí bẹ̃ nítorípé ọmọ májẹ̀mú ni ẹ̀yin íṣe—

27 Àti lẹ́hìn tí a tí bùkún fún yín nígbànã ni Bàbá mú májẹ̀mú nã ṣẹ èyítí ó ti bá Ábráhámù dá tí ó wípé: Nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkúnfún gbogbo ìbátan ayé—sí ti fífúnni ní Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ mi sórí àwọn Kèfèrí, ìbùkún tí ó dà lórí àwọn Kèfèrí nã yíò mú wọn tóbi ju ènìyàn gbogbo, sí ti fífọn ká àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì.

28 Nwọn yíò sì jẹ́ pàṣán sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ yĩ. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nígbàtí wọn bá ti gba ẹ̀kún ìhìn-rere mi, nígbànã bí wọn ó bá sì sé ọkàn wọn le mọ́ mi, èmi yíò dá àwọn ìwà àìṣedẽdé wọn padà sórí wọn, ni Bàbá wí.

29 Èmi yíò sì rántí májẹ̀mú nã tí èmi ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi; èmi sì ti bá wọn dá májẹ̀mú pé èmi yíò kó wọn jọ ní àkokò tí ó tọ́ ní tèmi, tí èmi yíò tún padà fún wọn ní ilẹ̀ àwọn Bàbá wọn fún ìní wọn, èyítí íṣe ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, tí íṣe ilẹ̀ ìlérí nã fún wọn títí láé, ni Bàbá wí.

30 Yíò sì ṣe tí àkokò nã yíò dé, nígbàtí a ó wãsù ẹ̀kún ìhìn-rere mi fún wọn;

31 Wọn yíò sì gbà mí gbọ́, pé èmi ni Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, wọn yíò sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ mi.

32 Nígbànã ni àwọn àlóre yíò gbé òhùn sókè, pẹ̀lú ohùn kan ni wọn yíò sì kọrin; nítorítí wọn yíò ríi ní ojúkojú.

33 Nígbànã ni Bàbá yíò kó wọn jọ padà, tí yíò sì fi Jerúsálẹ́mù fún wọn ní ilẹ̀-ìní wọn.

34 Nígbànã ni wọn yíò búsí ayọ̀—Ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Bàbá ti tù àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù padà.

35 Bàbá ti fi apá rẹ̀ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo àwọn ìkangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Bàbá; Bàbá àti èmi sì jẹ́ ọ̀kan.

36 Àti nígbànã ni a ó múu ṣẹ èyítí a kọ wípé: Jí, tún jí, kí ó sì gbé agbára rẹ wọ̀, A! Síónì; gbé aṣọ arẹwà rẹ wọ̀, A! Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nítorí láti ìsisìyí lọ àwọn aláìkọlà àti àwọn aláìmọ́ kì yíò wọ inú rẹ mọ́.

37 Gbọn ekuru kúrò ní ara rẹ; dìde, joko, A! Jerúsálẹ́mù; tú ara rẹ kúrò nínú ìdè ọrùn rẹ, A! òndè ọmọbìnrin Síónì.

38 Nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Ẹ̀yin ti ta ara yín lọ́fe, a ó sì rà yín padà láìsanwó.

39 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé àwọn ènìyàn mi yíò mọ́ orúkọ mi; bẹ̃ni, ní ọjọ́ nã wọn yíò mọ̀ pé èmi ni ẹnití nsọ̀rọ̀.

40 Àti nígbànã ni wọn yíò wípé: Báwo ni ẹsẹ̀ ẹnití ó mú ìhìn-rere wá fún wọn ti dára tó lórí àwọn òkè gíga, ẹnití nkéde àlãfíà; tí ó sì mú ìhìn-rere wá fún àwọn ẹni dáradára, tí ó nkéde ìgbàlà; tí ó wí fún Síónì pé: Ọlọ́run rẹ njọba!

41 Àti nígbànã ni igbe kan yíò jáde wá pé: Ẹ fà sẹ́hìn, ẹ fà sẹ́hìn, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́kàn ohun àìmọ́; ẹ kúrò lãrín rẹ̀; ẹ jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin tí ngbé ohun-èlò Olúwa.

42 Nítorí ẹ̀yin kì yíò yára jáde, bẹ̃ni ẹ kì yíò fi ìsáré lọ; nítorítí Olúwa yíò ṣãjú yín, Ọlọ́run Ísráẹ́lì yíò sì tì yín lẹ́hìn.

43 Ẹ kíyèsĩ, ìránṣẹ́ mi yíò fi òye bá ni lò; a ó gbée ga, a ó sì bù ọlá fún un, òun yíò sì ga lọ́pọ̀lọpọ̀.

44 Gẹ́gẹ́bí ẹnu ti ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nípã rẹ—a bá ojú rẹ̀ jẹ́ ju ti ẹnìkẹ́ni lọ, àti ìrísí rẹ̀ ni a bàjẹ́ ju ti ọmọ ènìyàn lọ—

45 Bẹ̃ni yíò bùwọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè; àwọn ọba yíò pa ẹnu wọn mọ́ síi, nítorípé wọn yíò rí ohun tí a kò sọ fún wọn; wọn yíò sì ní òye nípa èyítí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀.

46 Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni yíò ṣẹ, àní gẹ́gẹ́bí Bàbá ti pàṣẹ fún mi. Nígbànã ni májẹ̀mú yĩ èyítí Bàbá ti dá pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò di mímúṣẹ; àti nígbànã ni àwọn ènìyàn mi yíò tún máa gbé inú Jerúsálẹ́mù, yíò sì jẹ́ ilẹ̀ ìní wọn.