Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 34


Orí 34

Ámúlẹ́kì ṣe ìjẹ́rìsí pé ọ̀rọ̀ nã wà nínú Krístì sí ìgbàlà—Àfi bí a bá ṣe ètùtù, gbogbo ènìyàn ni yíò ṣègbé. Gbogbo òfin Mósè ni ó tọ́ka sí ìfirúbọ Ọmọ Ọlọ́run—Ìlànà ìràpadà ti ayérayé dúró lórí ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà—Ẹ máa gbàdúrà fún ìbùkún lórí ohun ara àti ti ẹ̀mí—Ayé yĩ ni àkokò fún ènìyàn láti múrasílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run—Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà nyín pẹ̀lú ìbẹ̀rù níwájú Ọlọ́run. Ní ìwọ ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún nwọn, ó jókõ lélẹ, Ámúlẹ́kì sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́, ó wípé:

2 Ẹ̀yin arákùnrin mi, mo lérò pé ó ṣòro pé kí ẹ̀yin ó wà nínú àìmọ̀ ní ti àwọn ohun tí a ti sọ nípa bíbọ̀ Krístì, ẹnití a ṣe ìkọ́ni-lẹ̃kọ́ nípa rẹ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run nií ṣe; bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé nwọ́n ti ṣe ìkọ́ni-lẹ́kọ̃ àwọn nkan wọ̀nyí fún nyín lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ẹ̀yin tó yapa kúrò lọ́dọ̀ wa.

3 Àti bi ẹ̀yin ṣe fẹ́ kí arákùnrin mi àyànfẹ́ jẹ́ kí ẹ mọ́ ohun tí ẹ̀yin níláti ṣe, nítorí ìpọ́njú nyín; òun sì ti bá nyín sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti múra ọkàn nyín sílẹ̀; bẹ̃ni, òun sì ti gbà nyín níyànjú pé kí ẹ ní ìgbàgbọ́ àti sũrù—

4 Bẹ̃ni, àní pé kí ẹ̀yin kí ó ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ tí ẹ ó fi gbin ọ̀rọ̀ nã sínú ọkàn nyín, kí ẹ̀yin fi lè ṣe àgbéyẹ̀wò dídára rẹ̀.

5 Àwa sì ti rí i pé ìbẽrè pàtàkì tí ó wà nínú ọkàn nyín ni pé bóyá ọ̀rọ̀ nã jẹ́ ti Ọmọ Ọlọ́run, tàbí bóyá kò ní sí Krístì kankan.

6 Ẹ̀yin sì tún ríi pé arákùnrin mi ti fií hàn nyín, ní ọ̀nà tí ó pọ̀, pé ọ̀rọ̀ nã wà nínú Krístì sí ìgbàlà.

7 Arákùnrin mi ti sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́sì, pé ìràpadà a máa wá nípasẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run, àti pẹ̀lú, ó ti sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Sénọ́kì; òun sì tún ti fi ọ̀rọ̀ lọ Mósè, láti fihàn pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí íṣe.

8 Àti nísisìyí, kíyèsĩ èmi yíò jẹ́rĩ fúnrami pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí íṣe. Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín pé èmi mọ̀ pé Krístì nbọ̀wá sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, láti gbé gbogbo ìwàìrékọjá àwọn ènìyàn rẹ̀ wọ ara rẹ̀, àti pé òun yíò sì jẹ́ ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgbáyé; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó ti wí i.

9 Nítorítí ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí ẹnìkan ó ṣe ètùtù; nítorí gẹ́gẹ́bí ìlànà nlá ti Ọlọ́run Ayérayé ètùtù gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣíṣe, bíkòjẹ́ bẹ̃ gbogbo ènìyàn yíò ṣègbé; bẹ̃ni, ọlọ́ríkunkun ni gbogbo nwọn í ṣe; bẹ̃ni, gbogbo nwọn ti ṣubú, nwọ́n sì ti sọnù, nwọn ó sì ṣègbé àfi nípasẹ̀ ètùtù nã èyítí ó tọ̀nà ní ṣíṣe.

10 Nítorítí ó tọ̀nà pé kí ìrúbọ nlá kan tĩ ṣe àṣekẹ́hìn kí ó wà; bẹ̃ni, kĩ ṣe ìrúbọ tí a fi ènìyàn ṣe, tàbí ti ẹranko, tàbí ti ẹyẹkẹ́yẹ; nítorítí ko le jẹ́ ìrúbọ tí ènìyàn ṣe; ṣùgbọ́n ó níláti jẹ́ ìrúbọ tí íṣe èyí tí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin àti ti ayérayé.

11 Nísisìyí kò sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ rúbọ tí yíò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Nísisìyí, bí ẹnìkan bá pànìyàn, ẹ kíyèsĩ, njẹ́ òfin wa, èyítí ó tọ́, yíò ha gba ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ bí? Èmi wí fún nyín, Rárá.

12 Ṣùgbọ́n òfin ni pé kí a gba ẹ̀mí ẹnití ó pànìyàn; nítorínã kò sí ohun nã lẹ́hìn ètùtù èyítí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin nnì tí ó lè ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

13 Nítorínã, ó tọ̀nà pé kí ìrúbọ nlá kan tĩ ṣe àṣekẹ́hìn kí ó wà, lẹ́hìn nã sì ni ìtàjẹ̀sílẹ̀ yíò dópin, tàbí pé yíò jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí ìtàjẹ̀sílẹ̀ ẹranko dópin; ìgbànã ni òfin Mósè yíò wá sí ìmúṣẹ; bẹ̃ni, gbogbo rẹ̀ ni yíò wá sí ìmúṣẹ, pẹ̀lú èyítí ó kéré jùlọ, tí kò sì sí nínú nwọn tí yíò rékọjá láìmúṣẹ.

14 Ẹ sì kíyèsĩ, èyí ni gbogbo ìtumọ̀ òfin nã, èyítí ó kére jùlọ nínú rẹ̀ ntọ́ka sí ìrúbọ nlá nnì tĩ ṣe àṣekẹ́hìn; ìrúbọ nlá tĩ ṣe àṣekẹ́hìn nã ni yíò sì jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ̃ni, èyítí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin àti ayérayé.

15 Ní ọ̀nà yĩ ni òun yíò sì fi ìgbàlà fún gbogbo ẹnití ó bá gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; èyí sì ni èrèdí fún ìrúbọ àṣekẹ́hìn yĩ, láti mú ọ̀pọ̀ ãnú jáde wá, èyítí ó borí àìṣègbè, tí ó sì fún ọmọ ènìyàn ní ọ̀nà tí nwọn yíò fi ní ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà.

16 Báyĩ sì ni ãnú yíò ṣe san gbèsè fún àìsègbè, tí yíò sì fi ọwọ́ ãbò rẹ̀ yí nwọn ká, nígbàtí ẹnití kò bá ní ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà yíò di ẹnití a ó fi gbogbo òfin tí ó rọ̀ mọ́ àìṣègbè mú; nítorínã ẹnití ó bá ní ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà nìkan ni a ó fun ní ìlàna ìràpadà títóbi àti ti ayérayé nnì.

17 Nítorínã kí Ọlọ́run fi fũn yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, kí ẹ̀yin kí ó lè bẹrẹ sĩ lo ìgbàgbọ́ nyín sí ti ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin kí ó lè bẹ̀rẹ̀sí képe orúkọ rẹ̀ mímọ́, kí òun kí ó sì ṣãnú fún nyín;

18 Bẹ̃ni, ẹ kígbe pè é fún ãnú; nítorítí ó lágbára láti gbàlà.

19 Bẹ̃ni, ẹ rẹ ara nyín sílẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú àdúrà síi.

20 Ẹ kígbe pè é nígbàtí ẹ̀yin bá wà nínú oko nyín, bẹ̃ni, lórí gbogbo ẹran-ọ̀sìn nyín.

21 Ẹ kígbe pẽ nínú ilé nyín, bẹ̃ni lórí gbogbo agbo-ilé nyín, ní òwúrọ̀, ọ̀sán àti àṣálẹ́.

22 Bẹ̃ni, ẹ kígbe pè é fún ìdojúkọ agbára àwọn ọ̀tá nyín.

23 Bẹ̃ni, ẹ kígbe pè é fún ìdojúkọ èṣù, ẹnití í ṣe ọ̀tá fún gbogbo òdodo.

24 Ẹ kígbe pè é lórí ohun-ọ̀gbìn oko nyín, kí ẹ̀yin lè ṣe rere nípasẹ̀ nwọn.

25 Ẹ kígbe lórí àwọn àgbo-ẹran inú pápá nyín, kí wọ́n lè pọ̀ síi.

26 Ṣùgbọ́n èyí nìkan kọ́; ẹ̀yin gbọ́dọ̀ kó àníyàn ọkàn nyín jáde nínú iyàrá nyín làti ibi ìkọ̀kọ̀ nyín, àti nínú aginjù nyín.

27 Bẹ̃ni, nígbàtí ẹ̀yin kò bá sì kígbe pe Olúwa, ẹ jẹ́ kí ọkàn nyín kún, kí ó sì fà síi ninu àdúrà láìsimi fún àlãfíà nyín, àti pẹ̀lú fún àlãfíà àwọn tí nwọ́n yí nyín ká.

28 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo wí fún nyín, ẹ má rò pé gbogbo rẹ̀ ní èyí; nítorípé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, bí ẹ̀yin bá ṣe àìbìkítà fún àwọn aláìní, àti àwọn ti wọn wa ni ìhòhò, tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ àwọn aláìsàn àti àwọn tí ojú npọ́n wò, kí ẹ sì fifún ni nínú ohun ìní nyín, bí ẹ bá ní, fún àwọn tí ó ṣe aláìní—èmi wí fún nyín, tí ẹ̀yin kò bá ṣe èyíkéyĩ nínú àwọn nkan wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, asán ni àdúrà nyín íṣe, kò sì já mọ́ nkankan, ẹ̀yin sì dàbí àwọn àgàbàgebè, tí nwọn a máa sẹ́ ìgbàgbọ́ nnì.

29 Nítorínã, bí ẹ̀yin kò bá rántí láti máa fi ìfẹ́ lò, ẹ̀yin dàbí ìdàrọ́, èyítí àwọn tí ndá fàdákà dànù, (nítorítí kò wúlò fún ohunkóhun) tí ó sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ ènìyàn.

30 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, ó wù mí pé lẹ́hìn tí ẹ ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí, níwọ̀n ìgbàtí àwọn ìwé-mímọ́ ti jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ dìde kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀sí so èso sí ti ìrònúpìwàdà.

31 Bẹ̃ni, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó dìde, kí ẹ má sì sé ọkàn nyín le mọ́; nítorí ẹ kíyèsĩ, èyí ni àkokò àti ọjọ́ ìgbàlà nyín; àti nítorínã, bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà, tí ẹ kò sì sé ọkàn nyín le, lójúkannã ni Ọlọ́run yíò fún nyín ní ìpín nínú ìlànà ìràpadà títóbi àti ti ayérayé nnì.

32 Nítorí ẹ kíyèsĩ, ìgbésí-ayé yĩ jẹ́ àkọkò tí ènìyàn níláti múrasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run pàdé; bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, ọjọ́ ìgbésí-ayé yĩ ni ọjọ́ tí ènìyàn níláti ṣe iṣẹ́ wọn.

33 Àti nísisìyí, bí èmi sì ti wí fún nyín ṣãjú, bí ẹ̀yin ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí, nítorínã, mo bẹ̀ nyín pé kí ẹ ṣíwọ́ ìfònídóní-fọ̀ladọ́la nípa ọjọ́ ìrònúpìwàdà nyín di ìgbà òpin; nítorípé lẹ́hin ọjọ́ ìgbésí-ayé yĩ, èyítí a fún wa láti múrasílẹ̀ fún ayérayé, ẹ kíyèsĩ, bí àwa kò bá lo àkokò wa ní ọ̀nà tí ó dára ní ìgbésí-ayẹ́ wa, ìgbà àṣálẹ́ nã yíò sì dé nínú èyítí a kò lè ṣiṣẹ́ kankan.

34 Ẹ̀yin kò lè wípé, nígbàtí ẹ bá bọ́ sínú ipò búburú nnì, pé èmi yíò ronúpìwàdà, pé èmi yíò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Rárá, ẹ̀yin kò lè wí báyĩ; nítorípé ẹ̀mí kannã nnì, èyítí ó ngbé inú ara nyín ní àkókò tí ẹ̀yin bá jáde kúrò nínú ayé yĩ, ẹ̀mí kannã nnì, yíò ní ágbára láti gbé inú nyín nínú ayé ayérayé nã.

35 Ẹ sì kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá ṣe ìfònídóní-fọ̀ladọ́la nípa ọjọ́ ìrònúpìwàdà nyín àní títí ẹ ó fi kú, ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti fi ara nyín sí ábẹ́ ẹ̀mí tí íṣe ti èṣù, òun sì ti dè nyín mọ́ ara rẹ̀; nítorínã, Ẹ̀mí tí íṣe ti Olúwa ti fi nyín sílẹ̀, kò sì ní àyè mọ́ nínú nyín, èṣù ni ó sì ní gbogbo agbára lórí nyín; èyí sì ni ipò ìgbẹ̀hìn tí àwọn ènìyàn búburú yíò wà.

36 Èyĩ ni èmi sì mọ̀, nítorípé Olúwa ti sọ wípé òun kò lè gbé inú tẹ́mpìlì àìmọ́, ṣùgbọ́n nínú ọkàn àwọn olódodo ni ó ngbé; bẹ̃ni, òun sì tún sọ pẹ̀lú pé àwọn olódodo yíò jókõ nínú ìjọba rẹ̀, tí nwọn kò sì ní jáde mọ́; ṣùgbọ́n tí a ó sọ aṣọ nwọn di funfun nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn nã.

37 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí àwọn nkan wọ̀nyí, àti pé kí ẹ̀yin kí ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà nyín pẹ̀lú ìbẹ̀rù níwájú Ọlọ́run, kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe sẹ́ bíbọ̀wá Krístì mọ́;

38 Pé kí ẹ̀yin máṣe bá Ẹ̀mí Mímọ́ ja ìjàkadì mọ́, ṣùgbọ́n pé kí ẹ̀yin kí ó gbã, kí ẹ sì gba orúkọ Krístì sí ayé nyín; pé kí ẹ̀yin kí ó rẹ ara nyín sílẹ̀ àní búrú-búrú, kí ẹ sì máa sin Ọlọ́run, ní ibi èyíówù tí ẹ lè wà, ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́; kí ẹ sì máa gbé ìgbé ayé ìmõre ní ojõjúmọ́, fún ọ̀pọ̀ ãnú àti ìbùkún tí ó ndà sí órí yín.

39 Bẹ̃ni, èmi sì tún gbà nyín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé kí ẹ máa ṣọ́ra nínú àdúrà láìsimi, pé kí a máṣe ti ipasẹ̀ àdánwò èṣù darí nyín kúrò, pé kí òun má bã lè borí nyín, pé kí ẹ̀yin má bã wà lábẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹhìn; nítorí ẹ kíyèsĩ, òun kò lè san ohun rere kan fún nyín.

40 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi ìbá gbà nyín níyànjú pé kí ẹ ní sũrù, àti pé kí ẹ faradà onírurú ìpọ́njú; pé kí ẹ máṣe bú àwọn wọnnì tí nwọ́n lée nyín jáde nítorí ipò tálákà tí ẹ̀yin wà, èyítí ó tayọ, kí ẹ̀yin ó má bã di ẹlẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn nã;

41 Ṣùgbọ́n pé kí ẹ̀yin kí ó ní sũrù, kí ẹ sì faradà àwọn ìpọ́njú nnì, pẹ̀lú ìrètí nlá pé ní ọjọ́ kan ẹ̀yin yíò sinmi kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú nyín.