Àwọn òfin Álmà sí ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì.
Èyítí a kọ sí àwọn orí 36 àti 37.
Orí 36
Álmà jẹ́rĩ sí Hẹ́lámánì nípa ti ìyílókànpadà rẹ̀ lẹ́hìn tí ó rí ángẹ́lì kan—Ó jìyà ìrora ẹni-ìdálẹ́bi; ó képe orúkọ Jésù, a sì bí nipa ti Ọlọ́run lẹ́hìnnã—Ayọ̀ dídùn kún ọkan rẹ̀—Ó rí àjọ àìníye àwọn ángẹ́lì tí nwọ́n n yin Ọlọ́run—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí nwọn di ẹni-ìyílọ́kànpadà ni wọ́n ti tọ́wò ti wọ́n sì ti rí bí òun ti tọ́wò tí ó sì ti rí. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Ọmọ mi, fi etí sí ọ̀rọ̀ mi; nítorítí èmi ṣe ìbúra pẹ̀lú rẹ, pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ìwọ yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ yĩ.
2 Èmi fẹ́ kí ìwọ kí ó ṣe gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, ní ti rírántí ìgbèkùn àwọn bàbá wa; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, tí kò sì sí ẹnití ó lè kó nwọn yọ bí kò ṣe Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù; òun sì kó nwọn yọ kúrò nínú ìpọ́njú nwọn gbogbo nítõtọ́.
3 Àti nísisìyí, A! ọmọ mi, Hẹ́lámánì, kíyèsĩ, ìwọ wà ní èwe rẹ, nítorínã, mo bẹ̀ ọ́ pé kí ìwọ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ kí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorítí èmi mọ̀ wípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run yíò rí ìrànlọ́wọ́ nínú gbogbo àdánwò wọn; àti lãlã wọn, àti ìpọ́njú wọn, tí a ó sì gbé e sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.
4 Àti pẹ̀lú pé èmi kò fẹ́ kí ìwọ rò pé èmi mọ̀ ohun yĩ fúnra mi—kĩ ṣe nípasẹ̀ ti ayé yĩ, bíkòṣe nípasẹ̀ ti ẹ̀mí, kĩ ṣe nípasẹ̀ ti ara bíkòṣe nípasẹ̀ ti Ọlọ́run.
5 Nísisìyí, kíyèsĩ, èmi wí fún ọ́, tí a kò bá bí mi nípa ti Ọlọ́run, èmi kì bá tí mọ̀ àwọn nkan wọ̀nyí; ṣùgbọ́n Ọlọ́run, láti ẹnu àwọn ángẹ́lì rẹ̀ mímọ́, ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ fún mi, kĩ ṣe nítorí wíwà ní yíyẹ mi;
6 Nítorítí èmi nlọ kiri pẹ̀lú àwọn ọmọ Mòsíà, tí à npète láti pa ìjọ-Ọlọ́run run; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Ọlọ́run rán ángẹ́lì rẹ̀ mímọ́ láti dá wa dúró lójú ọ̀nà ìrìn-àjò wa.
7 Sì kíyèsĩ, ó bá wa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn èyítí ó dàbí sísán àrá, gbogbo ilẹ̀ sì mì lábẹ́ ẹsẹ̀ wa; àwa sì ṣùbú lulẹ̀, nítorítí ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá sí orí wa.
8 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohùn nã sọ fún mi pé: Dìde. Èmi sì dìde dúró, mo sì rí ángẹ́lì nã.
9 Òun sì wí fún mi pé: Bí ìwọ kò bá fẹ́ ìparun ara rẹ, dáwọ́dúró ìlépa láti pa ìjọ-Ọlọ́run run.
10 Ó sì ṣe tí èmi ṣubú lulẹ̀; èyí sì jẹ́ fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta tí èmi kò fi lè la ẹnu mi, bẹ̃ nã ni èmi kò lè gbé apá tàbí ẹsẹ̀ mi.
11 Ángẹ́lì nã sì tún bá mi sọ̀rọ̀ síwájú síi, èyítí àwọn arákùnrin mi gbọ́, ṣùgbọ́n tí èmi kò gbọ́ nwọn; nítorípé nígbàtí èmi gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí—Bí ìwọ kò bá fẹ́ ìparun ara à rẹ̀, dáwọ́dúró lílépa láti pa ìjọ-Ọlọ́run run—Ẹ̀rù nlá bà mí pẹ̀lú ìyàlẹ́nú pé bóyá a ó pa mi run, tí èmi sì ṣubú lulẹ̀ tí èmi kò sì gbọ́ ohun kankan mọ́.
12 Ṣùgbọ́n oró ayérayé gbò mí, nítorítí ìforó bá ọkàn mi èyítí ó ga jùlọ tí ó sì gbò ó pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.
13 Bẹ̃ni, èmi rántí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé mi, fun eyiti a dami lóró pẹ̀lú ìrora ọ̀run-àpãdì; bẹ̃ni, èmi ríi pé mo ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run mi, tí èmi kò sì tún pa àwọn òfin rẹ̀ mímọ́ mọ́.
14 Bẹ̃ni, tí èmi sì ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, tàbí kí a wípé mo ti dári wọn lọ sí ìparun; bẹ̃ni, àti ní kúkúrú, púpọ̀ ni àìṣedẽdé mí ti jẹ́, tí èrò wíwá síwájú Ọlọ́run mi gbò ẹ̀mí mi pẹ̀lú ìbẹ̀rù tí a kò lè máa sọ.
15 A!, èmi rõ, wípé, ìbá ṣeéṣe kí a lé mi kúrò, kí èmi sì di aláìsí ní ẹ̀mí àti ní ara, kí a máa lè mú mi wá dúró níwájú Ọlọ́run mi, fún ìdájọ́ lórí àwọn ìṣe mi.
16 Àti nísisìyí, fún ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta ni èmi fi wà ní gbígbò, àní pẹ̀lú ìrora ẹni-ìdálẹ́bi.
17 Ó sì ṣe bí oró yĩ ṣe ngbò mí, bí mo sì ṣe wà nínú ìforó ọkàn nípa ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi púpọ̀, kíyèsĩ, mo rántí pẹ̀lú pé mo gbọ́ tí bàbá mi ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn nã nípa bíbọ̀wá ẹnìkan tí à npè ní Jésù Krístì, tí íṣe Ọmọ Ọlọ́run, láti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgbáyé.
18 Nísisìyí, nígbàtí ọkàn mi tẹ̀ mọ́ èrò yĩ, mo kígbe nínú ọkàn mi pé: A! Jésù, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run, ṣãnú fún mi, tí mo wà nínú ipò ìkorò òrõró, ti a si yi mi ka pẹlũ ẹ̀wọ̀n ainipẹkun ti ikú.
19 Àti, nísisìyí, kíyèsĩ, nígbàtí mo ronú nípa èyí, èmi kò rántí àwọn ìrora mi mọ́; bẹ̃ ni, ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi kò gbò mí mọ́.
20 Àti, a!, irú ayọ̀ wo, àti pé irú ìmọ́lẹ̀ wo ni èmi rí; bẹ̃ni, ọkan mi kún fún ayọ̀ èyítí ó pọ̀ púpọ̀ bí ìrora èyítí mo ní ṣãjú!
21 Bẹ̃ni, èmi wí fún ọ, ìwọ ọmọ mi, pé kò sí ohun tí ó lè tayọ ìkorò ìrora mi. Bẹ̃ni, èmi sì tún wí fún ọ́, ìwọ ọmọ mi, pé ní ìdà kejì, kò sí ohun tí ó lè tayọ adùn àti ayọ̀ tí mo ní.
22 Bẹ̃ni, èmi rò pé mo rí, àní gẹ́gẹ́bí bàbá wa Léhì ti ríi, tí ó rí Ọlọ́run tí ó jókõ lórí ìtẹ́-ọba rẹ̀, tí àjọ àìníye àwọn ángẹ́lì sì yíi ká ní ìwà kíkọrin àti yíyin Ọlọ́run nwọn; bẹ̃ni, ọkàn mi sì fẹ́ láti wà níbẹ̀.
23 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, apá àti ẹsẹ̀ mi sì tún mókun, èmi sì dúró lórí ẹsẹ̀ mi, tí mo sì fi han àwọn ènìyàn nã pé a ti bí mi nípa ti Ọlọ́run.
24 Bẹ̃ni, láti ìgbà nã lọ àti títí di ìsisìyí pẹ̀lú, èmi ti ṣiṣẹ́ láìsinmi, kí èmi kí ó lè mú àwọn ọkàn wá sí ìronúpìwàdà; kí èmi kí ó lè mú nwọn tó wò nínú ọ̀pọ̀ ayọ̀ nínú èyítí èmi ti tọ́ wò; kí a lè bí wọn nípa ti Ọlọ́run pẹ̀lú, kí nwọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.
25 Bẹ̃ni, àti nísisìyí kíyèsĩ, A! ọmọ mi, Olúwa ti fún mi ní ọ̀pọ̀ ayọ̀ nlá nínú èrè iṣẹ́ mi;
26 Nítorí tí ọ̀rọ̀ èyítí òun ti fi fún mí, kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ti bí nípa ti Ọlọ́run, tí nwọ́n sì ti tọ wò gẹ́gẹ́bí èmi ti tọ wò, tí wọ́n sì ti rí ní ójúkojú gẹ́gẹ́bí èmi ti rí; nítorínã nwọn mọ̀ nípa àwọn ohun wọnyi tí èmi ti sọ nípa nwọn, gẹ́gẹ́bí èmi ṣe mọ̀; ìmọ̀ tí èmi ní jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
27 Èmi sì ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú àdánwò àti ìyọnu onírũrú, bẹ̃ni, àti onírũrú ìpọ́njú; bẹ̃ni, Ọlọ́run ti yọ mí kúrò nínú ìdè, àti kúrò nínú ikú; bẹ̃ni, èmi sì gbẹ́kẹ̀ mi lé e, òun yíò sì kó mi yọ síbẹ̀.
28 Èmi sì mọ̀ wípé òun yíò gbé mi dìde ní ọjọ́ ìkẹhìn, láti gbé pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo; bẹ̃ni, èmi yíò sì máa yìn ín títí láé, nítorítí ó ti mú àwọn bàbá wa jáde kúrò ní Égíptì, ó sì ti gbé àwọn ará Égíptì mì nínú Òkun Pupa; òun sì darí nwọn nípa agbára rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìlérí nã; bẹ̃ni, òun sì ti kó nwọn yọ kúrò nínú oko-ẹrú àti ìgbèkùn láti ìgbà dé ìgbà.
29 Bẹ̃ni, òun sì tún mú àwọn bàbá wa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; òun sì tún ti gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú àti ìgbèkùn, nípa agbára rẹ̀ àìlópin, láti ìgbàdé ìgbà, àní títí di àkokò yĩ; èmi a sì máa rántí àkokò ìgbèkùn nwọn; bẹ̃ni, ó sì yẹ kí ẹ̀yin nã máa rántí àkokò ìgbèkùn nwọn, gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe.
30 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọmọ mi, èyí nìkan kọ́; nítorítí ó yẹ kí ìwọ mọ̀, gẹ́gẹ́bí èmi ti mọ̀, pé níwọ̀n ìgbà tí ìwọ bá pa òfin Ọlọ́run mọ́ ìwọ yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; ó sì yẹ kí ìwọ mọ̀ pẹ̀lú, pé níwọ̀n ìgbàtí ìwọ kò bá pa òfin Ọlọ́run mọ́, a ó ke ọ́ kúrò níwájú rẹ̀. Nísisìyí èyí jẹ́ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀.