Ìwé ti Énọ́sì
Ori 1
Énọ́sì gbàdúrà gidigidi ó sì gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—Ohùn Olúwa wá sí ọkàn rẹ̀, tí ó nṣèlérí ìgbàlà fún àwọn ará Lámánì ní ọjọ́ iwájú—Àwọn ara Nífáì wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Lámánì padà—Énọ́sì yọ̀ nínú Olùràpadà rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 420 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Kíyèsĩ, ó sì ṣe, tí èmi, Énọ́sì, nínú ìmọ̀ wípé bàbá mi jẹ́ ẹni tí ó tọ́—nítorítí ó kọ́ mi nínú èdè rẹ̀, pẹ̀lú nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa—ìbùkún sì ni fún orúkọ Ọlọ́run mi fún èyí—
2 Èmi ó sì sọ fún nyín ti ìjàkadì tí èmi jà níwájú Ọlọ́run, kí èmi tó gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi.
3 Kíyèsĩ, mo lọ dọdẹ ẹranko nínú igbó; àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sábà máa ngbọ́ tí bàbá mi nsọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àti ayọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, sì wọ ọkàn mi lọ.
4 Ẹ̀mí mi si kébi; mo sì kúnlẹ̀ níwájú Ẹlẹ́da mi, mo sì kígbe pẽ nínú ọ̀pọ̀ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ tí ó lágbára fún ẹ̀mí ara mi; àti ní gbogbo ọjọ́ ni èmi kígbe pè é; bẹ̃ni, nígbàtí alẹ́ sì lẹ́, èmi sì tún gbé ohùn mi sókè tí ó fi dé àwọn ọ̀run.
5 Ohùn kan sì tọ̀ mí wá, tí ó wípé: Énọ́sì, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, a ó sì bùkún ọ.
6 Èmi, Énọ́sì sì mọ̀ wípé Ọlọ́run kò lè purọ́; nítorí-èyi, a ti gbá ẹ̀bi mi lọ.
7 Mo sì wípé: Olúwa, báwo ni a ṣe ṣe èyĩ?
8 Ó sì wí fún mi pé: Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, ẹnití ìwọ kò gbọ́ tàbí rí rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sì kọjá lọ kí ó tó di pé yíò fi ara rẹ̀ hàn ní ẹran ara; nítorí ìdí èyí, máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.
9 Nísisìyí, ó sì ṣe, nígbàtí èmi ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo bẹ̀rẹ̀sí ní ìfẹ́ fún àlãfíà àwọn arákùnrin mi, àwọn ará Nífáì; nítorí-èyi, èmí gbé gbogbo ẹ̀mí mi ka iwájú Ọlọ́run nítorí nwọn.
10 Nígbàtí mo sì ngbìyànjú nínú ẹ̀mi báyĩ, kíyèsĩ, ohùn Olúwa tún tọ̀ mí wá, wípé: Èmi yíò bẹ àwọn arákùnrin rẹ wò, gẹ́gẹ́bí àìsimi wọn nípa pípa àwọn òfin mi mọ́. Mo ti fún nwọn ní ilẹ̀ yí, ó sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́; èmi kò sì ní fi ré, bíkòṣepé nípasẹ̀ ìwà àìṣedẽdé; nítorí-èyi, èmi yíò bẹ àwọn arákùnrin rẹ wò gẹ́gẹ́bí èyí tí mo ti sọ; ìwà ìrékọjá nwọn ni èmi yíò si mú wá pẹ̀lú ìbànújẹ́ sí orí ara nwọn.
11 Àti lẹ́hìn tí èmi, Énọ́sì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ìgbàgbọ́ mi bẹ̀rẹ̀ sì fi ẹsẹ̀múlẹ̀ nínú Olúwa; èmi sì gbàdúrà síi pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìgbìyànjú pípẹ́ fún àwọn arákùnrin mi, àwọn ará Lámánì.
12 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi ti gbàdúrà tí mo sì ti ṣiṣẹ́ láìsinmi, Olúwa sì wí fún mi pé: Èmi yíò fifún ọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ.
13 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, èyí ni ìfẹ́-inú mi tí mo fẹ́ kí ó ṣe—pé bí ó bá lè ri bẹ̃, ti àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, bá ṣubú sí inú ìwà ìrékọjá, tí a sì pa wọ́n run lọ́nàkọnà, àti, tí a kò sì pa àwọn ará Lámání run, pé kí Olúwa Ọlọ́run ṣe ìtọ́jú ìwé ìrántí àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì; pãpã bí ó tilẹ̀ jẹ́ nípa agbára ọwọ́ rẹ̀ mímọ́, kí a lè múu jáde ní ìgbà kan ní ọjọ́ iwájú sí àwọn ará Lámánì, pé, bóyá, a o lè mú nwọn wá sínú ìgbàlà—
14 Nítorípé lọ́wọ́lọ́wọ́ gbogbo ìgbìyànjú wá jẹ́ asán ní mímú nwọn padà sí inú ìgbàgbọ́ òdodo. Nwọ́n sì búra nínú ìbínú nwọn pé, bí ó bá ṣeéṣe, nwọn yíò pa ìwé ìrántí wa àti àwa run, àti gbogbo àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn bàbá wa.
15 Nítorí-èyi, nítorítí mo mọ̀ wípé ó rọrùn fún Olúwa Ọlọ́run láti pa àwọn ìwé ìrántí wa mọ́, mo kígbe pẽ l’áìsimi, nítorítí òun ti sọ fún mi wípé: Ohunkóhun tí ìwọ yíò bá bẽrè pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí o sì gbàgbọ́ pé ìwọ yíò rí gbà ní orúkọ Krístì, ìwọ yíò rí gbà.
16 Èmi sì ní ìgbàgbọ́, mo sì kígbe pe Ọlọ́run pé kí ó pa àwọn ìwé ìrántí nã mọ́; Òun sì bá mi dá májẹ̀mú pé Òun yíò mú wọn jáde sí àwọn ará Lámánì ní àkokò tí ó yẹ níti rẹ̀.
17 Èmi, Énọ́sì, sì mọ̀ wípé yíò rí gẹ́gẹ́bí májẹ̀mú tí ó ti dá; nítorínã, ẹ̀mí mi simi.
18 Olúwa sì wí fún mi pé: Àwọn bábá rẹ nã ti bẽrè ohun yĩ lọ́wọ́ mi; yíò sì rí fún nwọn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn; nítorítí ìgbàgbọ́ nwọn dàbí ti yín.
19 Àti nísisìyí, ó sì ṣe, tí èmi Énọ́sì nlọ kiri lãrín àwọn ará Nífáì, tí mò nsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tí nbọ̀wá, tí mo sì njẹ́rĩ sí àwọn ohun tí mo ti gbọ́ àti èyítí mo ti rí.
20 Mo sì jẹ́rĩ pé àwọn ará Nífáì fi tọkàn-tọkàn wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Lámánì padà sínú ìgbàgbọ́ òtítọ́ nínú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n lãlã wa já sí asán; ikorira wọn kò yẹ̀, ìwà búburú nwọn sì ndarí nwọn tí wọ́n fi di ẹhànnà, ònrorò àti ẹnití òngbẹ ẹ̀jẹ̀ ngbẹ, nwọn kún fún ìwà ìbọ̀rìṣà àti ẽrí; ti nwọn sì njẹ ẹranko tí npẹran jẹ; tí nwọn ngbé inú àwọn àgọ́, tí nwọ́n sì nrìn kiri nínú aginjù nínú ìbàntẹ́, tí nwọn sì fá orí nwọn; nwọ́n sì já fáfá nínú lílo ọrún, àti simetà àti ãké. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn kò sì jẹ ohun míràn àfi ẹran tútù; nwọ́n sì nlépa àti pa wa run láìdẹ́kun.
21 Ó sì ṣe, tí àwọn ará Nífáì sì dáko, nwọ́n sì gbin oríṣiríṣi irúgbìn, pẹ̀lú èso, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀wọ́ agbo ẹran, àti ọ̀wọ́ onírurú màlũ, àti ewúrẹ́, àti ewúrẹ́ igbó, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin.
22 Àwọn wòlĩ tí ó pọ̀ púpọ̀ si wà lãrín wa. Àwọn ènìyàn nã sì jẹ́ ọlọ́rùn-líle ènìyàn, tí òyè kò sì yé nwọn.
23 Kò sì sí ohun míràn bí kò ṣe ọ̀pọ̀ ìrorò, ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ ogun àti ìjà, àti ìparun, àti rírán nwọn létí ikú láìdẹ́kun, àti àkokò ayé àìnípẹ̀kun, àti ìdájọ́ àti agbára Ọlọ́run, àti gbogbo nkan wọ̀nyí—nta wọ́n jí láìdẹ́kun, kí nwọ́n lè wà nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Mo ní kò sí èyítí ó yàtọ̀ sí ohun wọ̀nyí, àti ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere, tí ó lè mú kí nwọn má ṣègbé ní kánkán. Báyĩ ni èmi sì ṣe kọ ìwé nípa wọn.
24 Mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì nínú ìgbésí ayé mi.
25 Ó sì ṣe nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ sĩ darúgbó, tí ọgọ̃rún àti ãdọ́rin àti mẹ́sán ọdún ti kọjá lọ láti ìgbà tí bàbá wa Léhì ti fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀.
26 Mo sì ríi pé ọjọ́ súnmọ́ tí èmi yíò lọ sínú sàrẽ mi, lẹ́hìn tí agbára Ọlọ́run sì ti ràdọ̀bò mí pé mo níláti wãsù, àti sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn yĩ, kí èmi sì kéde ọ̀rọ̀ nã gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyítí ó wà nínú Krístì. Èmi sì ti kéde rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi, mo sì ti yọ̀ nínú rẹ̀ ju ti ayé yĩ.
27 Èmi yíò sì lọ sí ibi ìsimi mi láìpẹ́, èyítí ó wà pẹ̀lú Olùràpadà mi; nítorítí èmi mọ̀ pé nínú rẹ̀ ni èmi yíò simi. Èmi sì yọ̀ nínú ọjọ́ nã tí ara mi yíò gbé àìkú wọ̀, tí yíò sì dúró ní iwájú rẹ̀; nígbànã ni èmi yíò rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú inúdídùn, òun yíò sì wí fún mi pé: Wá sí ọ̀dọ̀ mi, ìwọ alábùkún-fún, a ti pèsè ãyè sílẹ̀ fún ọ nínú ilé Bàbá mi. Àmin.