Orí 3
Àwọn ará Nífáì púpọ̀ ṣí lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá—Nwọ́n kọ́ ilé amọ̀ líle nwọ́n sì kọ àwọn àkọsílẹ̀ púpọ̀—Ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni a yípadà tí a sì rìbọmi—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nií darí ènìyàn sí ìgbàlà—Nífáì ọmọ Hẹ́lámánì bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 49 sí 39 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kẹtàlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, kò sí ìjà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì àfi fún ìgbéraga díẹ̀ tí ó wà nínú ìjọ nã, èyítí ó mú kí ìyapa díẹ̀ wà lãrín àwọn ènìyàn nã, àwọn ohun wọ̀nyí ni nwọ́n sì ṣe àtúnṣe rẹ̀ nígbàtí ọdún kẹtàlélógójì nparí lọ.
2 Kò sì sí asọ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã nínú ọdún kẹrìnlélógójì; bákannã ni kò sì sí asọ̀ púpọ̀ nínú ọdún karundinlãdọta.
3 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlãdọ́ta, bẹ̃ni, asọ̀ púpọ̀ wà àti ìyapa púpọ̀; nínú èyítí àwọn tí ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà pọ̀ púpọ̀, tí nwọ́n sì lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá láti múu ní ìní.
4 Nwọ́n sì rin ìrìnàjò tí ó jìnà púpọ̀púpọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n dé ibití àwọn omi nlá-nlá àti àwọn odò púpọ̀púpọ̀ wà.
5 Bẹ̃ni, àní nwọ́n tàn ká gbogbo ilẹ̀ nã, sí ibikíbi tí nwọn kò í sọ di ahoro àti tí kò ní igi, nítorí àwọn tí nwọ́n ti ngbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀rí tí nwọ́n sì ti jogún ilẹ̀ nã.
6 Àti nísisìyí kò sí apá ilẹ̀ nã tí ó wà ní ahoro, bíkòṣe fún igi; ṣùgbọ́n nítorí bí ìparun àwọn ènìyàn tí ó ngbé ilẹ̀ nã tẹ́lẹ̀rí ti pọ̀ tó nwọn npẽ ní ahoro.
7 Nítorítí igi díẹ̀ ni ó sì wà lórí ilẹ̀ nã, bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ènìyàn nã tí ó jáde lọ di olùjáfáfá nínú lílo amọ̀ líle; nítorínã nwọ́n sì kọ́ ilé amọ̀ líle, nínú èyítí nwọ́n gbé.
8 Ó sì ṣe tí nwọ́n pọ̀ síi tí nwọ́n sì tàn kálẹ̀, nwọ́n sì kọjá lọ láti ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù lọ sí ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, nwọ́n sì tàn kálẹ̀ tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bò orí gbogbo ilẹ̀ ayé, láti òkun tí ó wà ní apá gũsù, títí dé òkun tí ó wà ní apá àríwá, láti òkun tí ó wà ní apá ìwọ oòrùn títí dé òkun tí ó wà ní apá ìlà oòrùn.
9 Àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá sì ngbé inú àgọ́, àti nínú àwọn ilé amọ̀ líle, nwọ́n sì jẹ́ kí igi èyíkéyĩ tí ó bá hù jáde nínú ilẹ̀ nã kí ó dàgbà, pé láìpẹ́ àwọn yíò ní igi láti kọ́ àwọn ilé wọn, bẹ̃ni, awọn ìlú-nlá nwọn, àti àwọn tẹ́mpìlì nwọn, àti àwọn sínágọ́gù nwọn, àti àwọn ibi-mímọ́ nwọn, àti onirũru àwọn ilé kíkọ́ nwọn.
10 Ó sì ṣe bí igi ti ṣe ọ̀wọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, nwọ́n sì kó púpọ̀ wọlé nípa ọ̀kọ̀-omi.
11 Báyĩ sì ni nwọ́n mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá láti lè kọ́ ìlú-nlá púpọ̀púpọ̀, pẹ̀lú igi àti pẹ̀lú amọ̀ líle.
12 Ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn Ámọ́nì, tí nwọ́n jẹ́ ará Lámánì nípa bíbí, sì lọ pẹ̀lú sínú ilẹ̀ yĩ.
13 Àti nísisìyí àwọn àkọsílẹ̀ tí nwọ́n kọ nípa àwọn ènìyàn yìi pọ̀ púpọ̀, láti ọwọ́ púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn yĩ, àwọn èyítí ó wà pàtó àti tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nípa nwọn.
14 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìdá kan nínú ọgọrun àwọn ìṣe àwọn ènìyàn yĩ, bẹ̃ni àkọsílẹ̀ nípa àwọn ará Lámánì, àti nípa àwọn ará Nífáì, àti àwọn ogun nwọn, àti ìjà, àti ìyapa, àti ìwãsù nwọn, àti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ nwọn, àti lílo ọkọ̀-omi nwọn àti kikan ọkọ-omi nwọn, àti kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì wọn, àti ti sinagọgu, àti àwọn ibi-mímọ́ nwọn, àti ìwà òdodo nwọn, àti ìwà búburú nwọn, àti ìwà ìpànìyàn nwọn, àti àwọn olè jíjà nwọn, àti àwọn ìkógun nwọn, àti onírurú ìwà ẽrí nwọn àti ìwà àgbèrè nwọn, ni kò lè gba inu iṣẹ́ yĩ.
15 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti àwọn àkọsílẹ̀ ní onírurú ni ó wà, tí àwọn ará Nífáì ní pàtàkì ti kọ sílẹ̀.
16 Tí nwọ́n sì ti fi lé ara nwọn lọ́wọ́ láti ọwọ́ àwọn ará Nífáì láti ìrán kan dé òmíràn, àní títí nwọ́n fi ṣubú sínú ìwàìrékọjá tí a sì ti pa nwọ́n, tí a ti ṣe ìkógun nwọn, tí a dọdẹ nwọn, ti a sì lé nwọn jáde, tí a pa nwọ́n, tí a sì tú nwọn ká lórí ilẹ̀ ayé, tí nwọ́n sì dàpọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì títí a kò fi pè nwọ́n ní ará Nífáì mọ́, tí nwọ́n sì di ènìyàn búburú, àti ẹhànnà ènìyàn, àti oníkà ènìyàn, bẹ̃ni, àní tí nwọ́n di àwọn ará Lámánì.
17 Àti nísisìyí èmi tún padà sí órí ọ̀rọ̀ mi; nítorínã, ohun tí èmi ti sọ ti rí bẹ̃ lẹ́hìn tí asọ̀ nlá, àti ìrúkèrúdò, àti ogun, àti ìyapa, ti wà lãrín àwọn ará Nífáì.
18 Ọdún kẹrìndínlãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ dópin;
19 Ó sì ṣe tí asọ̀ nlá sì tún wà nínú ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, àní ní ọdún kẹtàdínlãdọ́ta, àti ní ọdún kejìdínlãdọ́ta.
20 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ Hẹ́lámánì ṣe ìtẹ́ ìdajọ́ pẹ̀lú àìṣègbè àti ìṣòtítọ́; bẹ̃ni, ó gbìyànjú láti pa àwọn ìlànà, àti àwọn ìdajọ́ àti àwọn òfin Ọlọ́run mọ́; ó sì tẹramọ́ èyítí ó tọ́ níwájú Ọlọ́run; ó sì nrìn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà bàbá rẹ̀, tóbẹ̃ tí ó sì ṣe rere lórí ilẹ̀ nã.
21 Ó sì ṣe tí ó ní ọmọ méjì. Ó sọ ọmọ rẹ̀ èyítí í ṣe àkọ́bí ní Nífáì, èyítí ó kéré jù ni ó sì sọ ní Léhì. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà fún iṣẹ́ Olúwa.
22 Ó sì ṣe tí àwọn ogun àti àwọn asọ̀ bẹ̀rẹ̀sí dáwọ́dúró, ní díẹ̀díẹ̀, lãrín àwọn ènìyàn ará Nífáì, nígbàtí ọdún kejìdínlãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì fẹ́rẹ̀ dópin.
23 Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, àlãfíà sì wà nínú ilẹ̀ nã, àfi fún àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tí Gádíátónì olè nnì ti dá sílẹ̀ ní àwọn apá ilẹ̀ nã níbití àwọn ènìyàn ti tẹ̀dósí púpọ̀púpọ̀, èyítí kò hàn sí àwọn tí í ṣe olórí ìjọba nã ní àkokò nã; nítorínã ni a kò ṣe pa nwọ́n run tán ní ilẹ̀ nã.
24 Ó sì ṣe ní ọdún yĩ kannã ìlọsíwájú tí ó pọ̀ wà nínú ìjọ nã; tóbẹ̃ tí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún fi darapọ̀ mọ́ ìjọ nã tí nwọ́n ṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà.
25 Bẹ̃ ni ìlọsíwájú ìjọ nã sì pọ̀ tó, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún tí a dà lé orí àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí ẹnu ya àwọn olórí àlùfã àti àwọn olùkọ́ni rékọjá.
26 Ó sì ṣe tí iṣẹ́ Olúwa sì tẹ̀síwájú tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣe ìrìbọmi tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ ìjọ Ọlọ́run nã, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn, bẹ̃ni, àní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún.
27 Báyĩ ni àwa lè ríi pé alãnú ni Olúwa sí àwọn tí yíò pe orúkọ rẹ̀ mímọ́ pẹ̀lú òtítọ́-inú.
28 Bẹ̃ni, báyĩ ni àwa ríi pé ẹnu ọ̀nà ọ̀run ṣí sílẹ̀ sí ènìyàn gbogbo, àní sí àwọn tí yíò gba orúkọ Jésù Krístì gbọ́, ẹnití í ṣe Ọmọ Ọlọ́run.
29 Bẹ̃ni, àwa ríi pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ lè di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú, èyítí ó yè, tí ó sì ní agbára, tí yíò sì pín pátápátá gbogbo ẹ̀tàn àti ìkẹ́kùn àti ọgbọ́n àrékérekè èṣù nnì, tí yíò sì darí ẹnití ó gba Krístì gbọ́ ní ipa ọ̀nà èyítí ó há tí ó sì ṣe tẹ̃rẹ́ lórí ọ̀gbun ìbànújẹ́ ayérayé èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti gbé àwọn ènìyàn búburú mì—
30 Tí yíò sì mú ẹ̀mí nwọn, bẹ̃ni, ẹ̀mí àìkú nwọn, sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run nínú ìjọba ọ̀run, láti joko pẹ̀lú Ábráhámù, àti Ísãkì, àti pẹ̀lú Jákọ́bù àti pẹ̀lú àwọn bàbá wa mímọ́, tí nwọn kò sì ní jáde mọ́.
31 Àti nínú ọdún yĩ ayọ̀ sì wà nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti ní gbogbo agbègbè tí ó yĩ ka, àní ní gbogbo ilẹ̀ ti àwọn ará Nífáì ní ní ìní.
32 Ó sì ṣe tí àlãfíà àti ayọ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀ wà ní ìyókù ọdún kọkàndínlãdọ́ta nã; bẹ̃ni, àti pé àlãfíà àti ayọ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀ wà síbẹ̀ síi ní àkokò ãdọ́ta ọdún nã nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.
33 Àti pé ní ọdún kọkànlélãdọ́ta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ àlãfíà sì wà pẹ̀lú, àfi fún ìwà ìgbéraga èyítí ó bẹ̀rẹ̀sí wọ inú ìjọ nã—kì í ṣe nínú ìjọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ọkàn àwọn ènìyàn tí nwọn njẹ́wọ́ pé àwọn wà nínú ìjọ Ọlọ́run—
34 Nwọ́n sì gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga, àní ní inúnibíni sí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn. Nísisìyí èyí yĩ sì jẹ́ ohun búburú nlá, èyítí ó mú ki wọ́n ṣe inúnibíni púpọ̀ sí àwọn tí í ṣe onírẹ̀lẹ̀ nínú àwọn ènìyàn nã, àti kí nwọn ó la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọnjú kọjá.
35 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n gbàdúrà nwọ́n sì gba ãwẹ̀ nígbà-kũgbà, nwọ́n sì túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ síi, nwọ́n sì túbọ̀ dúró ṣinṣin síi nínú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì, títí ọkàn nwọn fi kún fún ayọ̀ àti ìtùnú, bẹ̃ni, àní títí dé ìwé-mímọ́ àti ìsọdimímọ́ ọkàn nwọn, ìsọdimímọ́ èyítí nbá nwọn nítorítí nwọn jọ̀wọ́ ọkàn nwọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run.
36 Ó sì ṣe tí ọdún kejìlélãdọ́ta parí ní àlãfíà pẹ̀lú, àfi fún ìgbéraga nlá èyítí ó ti wọ inú ọkàn àwọn ènìyàn nã lọ; èyí sì rí bẹ̃ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nwọn àti ìlọsíwájú nwọn ní ilẹ̀ nã; ó sì ndàgbà nínú nwọn lójojúmọ́.
37 Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàlélãdọta nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, Hẹ́lámánì sì kú, ọmọ rẹ̀ àkọ́bí Nífáì sì bẹ̀rẹ̀sí jọba ní ipò rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó nṣe ìtẹ́ ìdajọ́ pẹ̀lú àìṣègbè àti ìṣòtítọ́; bẹ̃ni, ó sì npa òfin Ọlọ́run mọ́, ó sì nrìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀.