Orí 5
Mọ́mọ́nì sì tún síwájú àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ara Nífáì nínú àwọn ogun ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìparun—Ìwé ti Mọ́mọ́nì yíò jáde wá láti dá gbogbo Isráẹ́lì lóju pe Jésù ni Krístì nã—Nitori àìgbágbọ́ wọn, a ó fọ́n àwọn ara Lámánì ká, Ẹmí yíò sì dẹ́kun wì wà pẹ̀lú wọn—Wọ́n yíò gba ìhìn-rere láti ọwọ́ àwọn Kèfèrí ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ní ìwọ̀n ọdún 375 sí 384 nínú ọjọ Olúwa wa.
1 O sì ṣe tí emí sì nlọ lãrín àwọn ara Nífáì, tí mo sì ronúpìwàdà ní ti ìbúra èyíti mo tí ṣe pé èmi kì yíò tún ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ; tí wọ́n sì tún fún mi ní àṣẹ lórí àwọn ẹgbẹ ọmọ ogun wọn, nítorítí wọn rí mi bí ẹnití ó lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ìpọ́njú wọn.
2 Ṣugbọn ẹ kíyèsĩ, mo wà laìní ìrètí, nítorítí mo mọ̀ ìdájọ́ Olúwa èyítí nbọ̀ lórí wọn; nítorítí wọn kò ronúpìwàdà kuro nínú àwọn àìṣedẽdé wọn, sugbọn wọn nfí idà jà fún ẹ̀mí ara wọn làìképè Ẹni nnì tí ó dá wọn.
3 O sì ṣe tí àwọn ara Lámánì wá láti kọlù wá nígbàtí àwa ti sálọ sí ìlú-nlá Jordánì; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, a lé wọn padà tí wọ̀n kò sì gbà ìlú nã ní àkókò nã.
4 O sì ṣe tí wọn tún wá kọlù wá, àwa sì mú ilu nla nã lọ́wọ́. Àwọn ilu-nla miràn sì wà pẹ̀lú tí àwọn ara Nífáì mú lọ́wọ́, àwọn èyítí àwọn ibi gíga wọn jẹ idilọwọ́ fun wọn tí wọn kò sì lè wọ̀ inú orílẹ̀-èdè tí o wà níwájú wa, láti pa àwọn tí ngbé inú ilẹ̀ wa run.
5 Sugbọn ó sì ṣe, ilẹ̀ èyíkéyĩ ti àwa bá tí là kọjá ti a kò kó àwọn tí ngbé inú ilẹ̀ nã wọlé, ní àwọn ara Lámánì parun, àti àwọn ìlú wọn, àti àwọn ìletò, àti àwọn ìlú-nlá ní wọ́n fi iná jó; báyĩ sì ni ọ̀rìn lé lọ̃dúnrún ọdún ó dín kan kọjá lọ.
6 O sì ṣe nínú ọ̀rìn lé lọ̃dúnrún ọdún tí àwọn ara Lámánì sì tún wá kọlù wa ní ogun, àwa sì dojúkọ wọ́n pẹ̀lú ìgboyà; ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ lásán, nítorítí iye wọn pọ̀ tóbẹ̃ tí wọ́n tẹ̀ àwọn ara Nífáì ni abẹ́ ẹsẹ̀ wọn.
7 O sì ṣe tí àwa tún sá, àwọn tí wọn sì yára jù àwọn ara Lámánì lọ sá àsálà, àwọn tí wọn kò sì yara to àwọn ara Lámánì ni wọn ké lulẹ̀ tí wọn sì pa wọ́n run.
8 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, emí, Mọ́mọ́nì, kò ní ìfẹ́ láti fòró ẹ̀mí àwọn ọmọ ènìyàn níti sísọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ àti ìpànìyàn èyítí mo fi ojú ara mi rí; sugbọn emí, nítorítí mo mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́dọ̀ dí mímọ̀ dájúdájú, àti pé ohun gbogbo tí ó pamọ́ níláti di fífihàn ní orí òrùlé—
9 Àti pẹ̀lú pé ìmọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí níláti wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù àwọn ènìyàn yĩ, àti sí ọ̀dọ̀ àwọn Kéfèrí, àwọn tí Olúwa ti sọ wípé wọn yíò fọ́n àwọn ènìyàn yĩ ká àti pe àwọn ènìyàn yĩ dàbí ohun asán ní ãrín wọn—nitorinã ni emí ṣe kọ àkọsílẹ̀ ní ìkékúrú níwọ̀nba, ní àìgbọdọ̀ kọ ní ẹkunrẹrẹ nípa àwọn ohun ti emí ti ri, nitori òfín tí emí ti gbà, àti pẹ̀lú kí ẹ̀yin ó má bã ní ìrora-ọkàn púpọ̀ jù nitori iwa búburú àwọn ènìyàn yĩ.
10 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ní èmi sọ fún irú-ọmọ wọn, àti pẹ̀lú fún àwọn Kèfèrí tí ó nãní ìdílé Ísráẹ́lì, tí ó ní òye àti ìmọ̀ nípa ibití ìbùkún wọn ti wá.
11 Nítorítí emí mọ̀ pe irú àwọn wọ̀nyí ni yíò kẹ́dùn ọkàn fún ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí yíò bá ìdíle Isráẹ́lì; bẹ̃ni, wọn yíò kẹ́dùn ọkàn fún ìparun àwọn ènìyàn yĩ; wọn yíò kẹ́dùn ọkàn nítorípé àwọn ènìyàn yĩ kò ronúpìwàdà kí wọn ó lè di gbígbà fun Jesu.
12 Nísisìyí àwọn ohun wọ̀nyí ni a kọ sí àwọn ìyókù ìdílé Jákọ́bù; a sì kọ wọn ní irú ọ̀nà yĩ, nítorípé Ọlọ́run mọ̀ pé ìwà búburú kò ní mú wọn jáde sí wọn; a ó sì gbé wọn pamọ́ nínú Olúwa kí wọn ó lè jáde wá ní àkókò tí ó yẹ nitirẹ̀.
13 Eyí sì ni àṣẹ ti èmi ti gba; ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò jáde wa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa, nígbàtí o bá ríi nínú ọgbọ́n rẹ̀ pé ó tọ́ láti ṣe bẹ̃.
14 Ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò sì tọ àwọn Jũ aláìgbàgbọ́ lọ, àti nítorí ìdí èyí ní wọn yíò lọ—kí a lè yi wọn lọ́kàn padà pé Jésù ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè; kí Bàbá ó lè mú ète nla rẹ̀ tí í ṣe ti áyérayé ṣẹ, nípasẹ̀ Àyànfẹ́ jùlọ rẹ̀, láti mú àwọn Jũ padà sí ipò wọn, tabi gbogbo ìdílé Isráẹ́lì, sí ilẹ̀ ìní wọn, èyítí Olúwa Ọlọ́run wọn ti fifún wọn sí ti ìmúṣẹ májẹ̀mú rẹ̀;
15 Àti pẹ̀lú kí irú ọmọ àwọn ènìyàn yĩ ó lè gba ìhìn-rere rẹ̀ gbọ́ sí i ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, èyítí yíò jáde tọ̀ wọn wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí; nítorítí á ó fọ́n àwọn ènìyàn yĩ ká, wọn yíò sì di aláwọ̀ dúdú, wọn yíò sì di elẽrí àti ẹlẹgbin ènìyàn, tayọ apejuwe èyíkèyi tí a tí rí ní ãrin wa, bẹ̃ni, àní èyítí ó ti wa lãrín àwọn ara Lamanì, èyĩ sì rí bẹ̃ nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ìwà ìbọ̀rìṣa wọn.
16 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Ẹ̀mí Olúwa ti dẹ́kun jíjà pẹ̀lú àwọn baba wọn; wọn sì wà ni àìní Krístì àti Ọlọ́run nínú ayé; a sì ngba wọn kiri bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
17 Nwọn jẹ onínúdídùn ènìyàn ní ìgbàkan rí, wọ́n sì ní Krístì gẹ́gẹ́bí olùṣọ́-àgùtàn wọn; bẹ̃ni, Ọlọ́run tí í ṣe Baba ní ó sì ndari wọn.
18 Ṣugbọn nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, Sátánì ní ó ndari wọn kakiri, àní gẹgẹbi iyangbo tí di gbigba kiri níwájú afẹ́fẹ́, tabi bí ọkọ̀ omi tí di bíbì síwá-sẹ́hin nínú ìru omi, èyítí kò ní igbokun ọkọ̀, tabi ìdákọ̀ró, tabi ohunkóhun tí a ó fí tù ú; àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ó ti rí, bẹ̃ ni wọn rí.
19 Ẹ sì kíyèsĩ, Olúwa ti fi ìbùkún wọn pamọ́, èyítí wọn iba gbà ní ilẹ nã, fún àwọn Kèfèrí tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní.
20 Ṣùgbọn ẹ kíyèsĩ, yíò sì ṣe ti a o lé wọn tí a o sì fọ́n wọn ka láti ọwọ àwọn Kèfèrí; lẹ́hìntí a bá sì ti lé wọn tí a sì ti fọn wọn ka láti ọwọ àwọn Kèfèrí, ẹ kíyèsĩ, nígbànã ni Olúwa yíò ranti májẹ̀mú nã èyítí ó da pẹ̀lu Ábráhámù àti pẹ̀lú gbogbo ìdílé Isráẹ́lì.
21 Àti pẹ̀lú Olúwa yíò ranti àwọn àdúrà àwọn olódodo, èyítí wọ́n tí gbé sókè síi fún wọn.
22 Àti nígbànã, A! ẹ̀yin Kèfèrí, báwo ni ẹyin yíò se lè duro níwájú agbara Ọlọ́run, àfi kí ẹ̀yin ó ronúpìwàdà kí ẹ sì yípadà kúrò nínú ọ̀nà ibi yín?
23 Njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ọwọ́ Ọlọ́run ni ẹyin wà bí? Njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ó ní gbogbo agbara, àti pé ní àṣẹ nlá rẹ̀ ayé yíò di kíká pọ̀ bí ìwé tí a ká?
24 Nitorinã, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì rẹ̀ ara yín sílẹ̀ níwájú rẹ̀, kí òn ó má bã jáde wá ní àìṣègbè sí yín—kí ìyókù iru-ọmọ Jákọ́bù kan ó má bã kọjá lọ ní ãrín yín bí kìnìún, kí ó sì ya yín pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí kò sì sí ẹnití yíò gbà yín là.