Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 14


Orí 14

Isaiah sọ̀rọ̀ bĩ Messia—A sọ síwájú nípa ìrẹnisílẹ̀ àti ìjìyà Messia nã—Ó fi ẹ̀mí rẹ rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ó sì nṣe onílàjà fún àwọn olùrékọja—Fi Isaiah 53 wee. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Bẹ̃ni, njẹ́ Isaiah kò ha wípé: Tani ó ti gba ìhìn wa gbọ́, àti pé tani ẹnití a fi apá Olúwa hàn sí?

2 Nítorítí yíò dàgbà níwájú rẹ gẹ́gẹ́bí ọ̀jẹ́lẹ́ ewéko, àti gẹ́gẹ́bí gbòngbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ; ìrísí rẹ̀ kò dára, bẹ̃ni kò ní ẹwà; nígbàtí àwa yíò bá sì ríi, kò sí ẹwà tí àwa kò bá fi fẹ́ ẹ.

3 A kẹ́gàn rẹ, a sì kọ̃ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn; ẹni ọ̀pọ̀ ìrora-ọkàn, tí ó sì mọ́ ìbànújẹ́; àwa sì fi ojú wa pamọ́ kúrò lára rẹ̀; a kẹ́gàn rẹ̀, àwa kò sì kà á sí.

4 Lõótọ́, ó ti faradà ìbànújẹ́ wa, ó sì ti gbé ìrora-ọkàn wa lọ; síbẹ̀ àwa kà á sí ẹnití a nà, ẹnití Ọlọ́run fìyàjẹ, tí a sì pọ́n lójú.

5 Ṣùgbọ́n a ṣáa lọ́gbẹ́ nítorí ìrékọjá wa, a pã lára nítorí àìṣedẽdé wa; ìbáwí àlãfíà wa wà lára rẹ̀, àti nípa ínà a rẹ̀ ni a fi mú wa lára dá.

6 Gbogbo wa, bí àgùtàn, ni a ti ṣáko lọ; olúkúlùkù wa sì tẹ̀lé ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti mú àìṣedẽdé wa gbogbo pàdé lára rẹ̀.

7 A jẹ ẹ́ ní ìyà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a múu wá bí ọ̀dọ́-àgùtàn fún pípa, àti bí àgùtàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́rùn rẹ̀, bẹ̃ni, kò ya ẹnu rẹ̀.

8 A múu jáde kúrò nínú tũbú, àti kúrò nínú ìdájọ́; tani yíò sì sọ nípa ìran rẹ̀? Nítorítí a ti kée kúrò ní ilẹ̀ alãyè; nítorí ìrékọjá àwọn ènìyàn mi ní a ṣe lũ.

9 Ó sì ṣe ibojì rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú, pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ rẹ ní ìgbà ikú rẹ̀; nítorípé ko hu ìwà ibi, bẹ̃ni kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.

10 Síbẹ̀ ó wu Olúwa láti pã lára; ó ti fi sínú ìbànújẹ́; nígbàtí ìwọ o fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, òun yíò rí irú-ọmọ rẹ̀, yíò mú ọjọ́ rẹ̀ gùn, ìfẹ́ Olúwa yíò lọ dẽdé ní ọwọ́ rẹ̀.

11 Òun yíò rí lãlã ẹ̀mí rẹ̀, yíò sì tẹ́ẹ lọ́run; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yíò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre; nítorítí òun yíò ru àìṣedẽdé nwọn.

12 Nítorínã ni èmi yíò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni-nlá, òun yíò sì bá àwọn alágbára pín ìkógun; nítorítí òun ti tú ẹ̀mí rẹ jáde títí dé ikú, a sì kà á mọ́ àwọn olùrékọjá; òun sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe alágbàwí fún àwọn olùrékọjá.