Ìpín 11
Ìfihàn tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí arákùnrin rẹ̀ Hyrum Smith, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Karũn 1829. Ìfihàn yìí jẹ́ èyí tí a gbà nípa lílo Urimù àti Tummimù ní ìdáhùn sí àdúrà àti ìbéèrè Joseph. Ìtàn ti Joseph Smith dáa lábàá pé a gba ìfihàn yìí lẹ́hìn ìmúpadàbọ̀sípò Oyè Àlufáà ti Aaronì.
1–6, Àwọn òṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà yíò jẹ èrè ìgbàlà; 7–14, Wá ọgbọ́n, kígbe ironúpìwàdà, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ẹ̀mì, 15–22, Pa àwọn òfin mọ́, kí o sì ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Olúwa; 23–27, Má ṣe sẹ́ ẹ̀mí ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀; 28–30, Àwọn tí wọ́n gba Krísti di ọmọ Ọlọ́run.
1 Iṣẹ́ títóbi ati yíyanilẹ́nu kan ti fẹ́ jáde wá ní àárin àwọn ọmọ ènìyàn.
2 Kíyèsíi, èmi ni Ọlọ́run; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, èyí tí ó jẹ́ alààyè ati alágbára, ó mú ju idà olójú méjì lọ, sí pípín lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ti oríkèé àti mùndùnmúndùn; nítorínáà tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi.
3 Kíyèsíi, oko náà ti funfun tán fún ìkórè; nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kórè ẹ jẹ́ kí ó fi dòjé rẹ̀ pẹ̀lú agbára rẹ̀, kí ó sì kórè nígbatí ọjọ́ sì wà, kí òun baà lè fi pamọ́ fún ìgbàlà àìlópin ti ẹ̀mí rẹ̀ ní ìjọba Ọlọ́run.
4 Bẹ́ẹ̀ni, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dòjé rẹ̀ gún un tí ó sì kórè, ẹni náà ni Ọlọ́run pè.
5 Nítorínáà, bí ìwọ bá béèrè ní ọwọ́ mi, ìwọ yíò rí gbà; bí ìwọ bá kan ìlẹ̀kùn, a ó ṣí i fún ọ.
6 Nísisìyí, bí ìwọ ti béèrè, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì lépa lati mú jáde wá ati lati ṣe àgbékalẹ̀ ipa ọ̀nà Síónì.
7 Ma ṣe lépa fún ọrọ̀ ṣugbọ́n fún ọgbọ́n; àti, kíyèsíi, àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ni a ó ṣí fún ọ, àti nígbànáà ni a ó sọ ìwọ di ọlọ́rọ̀. Kíyèsíi, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìyè àìnípẹ̀kun ni ọlọ́rọ̀.
8 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, àní bí ìwọ ṣe fẹ́ lati ọwọ́ mi bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a ó ṣe é fún ọ; àti, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ yíó jẹ́ ohun èlò fún ṣíṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere ní ìran yìí.
9 Maṣe sọ ohunkohun bíkòṣe ironúpìwàdà fún ìran yìí. Pa àwọn òfin mi mọ́, kí o sì ṣe ìrànlọ́wọ́ lati mú iṣẹ́ mi jáde wá, gẹgẹ́bí àwọn òfin mi, ìwọ yíò sì di alábùkúnfún.
10 Kíyèsíi, ìwọ ní ẹ̀bùn kan, tàbí ìwọ yíò ní ẹ̀bùn kan bí ìwọ bá fẹ́ lati ọwọ́ mi nínú ìgbàgbọ́, pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, ní gbígbàgbọ́ nínú agbára Jésu Krísti, tàbí nínú agbára mi èyí tí ó nbá ọ sọ̀rọ̀;
11 Nítorí, kíyèsíi, èmi ni ẹnití ó sọ̀rọ̀; èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ntàn nínú òkùnkùn, àti pé nípa agbára mi èmi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí fún ọ.
12 Àti nísisìyí, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú Ẹ̀mì náà èyí tí ó ndarí lati ṣe rere—bẹ́ẹ̀ni, láti ṣe títọ́, láti rìn ní ìtẹríba, láti dájọ́ ní òdodo; èyí sì ni Ẹ̀mí mi.
13 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, èmi yíò fún ọ lára Ẹ̀mí mi, èyí tí yíò fi òye fun iyè inú rẹ, tí yíò sì fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ.
14 Àti pé nígbànáà ni ìwọ yíò mọ̀, tàbí nípa èyí ni ìwọ yíò mọ gbogbo ohun èyíkéyìí tí ìwọ bá fẹ́ lati ọ̀dọ̀ mi, èyítí ó níí ṣe pẹ̀lú awọn ohun ti òdodo, nínú ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú mi pé ìwọ yíò rí gbà.
15 Kíyèsíi, mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò níláti rò pé a ti pè ọ́ láti wàásù títí tí a ó fi pè ọ́.
16 Dúró fún ìgbà díẹ̀ síi, títí tí ìwọ yíò fi ní ọ̀rọ̀ mi, àpáta mi, ìjọ mi, àti ìhìnrere mi, kí ìwọ lè mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú nípa ẹ̀kọ́ mi.
17 Àti nígbanáà, kíyèsíi, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rẹ, bẹ́ẹ̀ni, àní gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ ni a ó ṣe é fún ọ.
18 Pa àwọn òfin mi mọ́; pa ẹnu rẹ mọ́; bẹ ẹ̀bẹ̀ sí Ẹ̀mí mi;
19 Bẹ́ẹ̀ni, fi ara mọ́ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, kí ìwọ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú wá sí ìmọ́lẹ̀ àwọn ohun wọnnì nípa èyí tí a ti sọ—bẹ́ẹ̀ni, ṣíṣe ìtumọ̀ iṣẹ́ mi; ní sùúrù títí ìwọ yíò fi ṣe é yọrí.
20 Kíyèsíi, èyí ni iṣẹ́ rẹ, láti pa àwọn òfin mi mọ́, bẹ́ẹ̀ni, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, iyè àti okun.
21 Máṣe lépa láti kéde ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n lépa lati gba ọ̀rọ̀ mi, àti nígbànáà ni okùn ahọ́n rẹ yíò tú; nígbànáà, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ yíò ní Ẹ̀mí mi àti ọ̀rọ̀ mi, bẹ́ẹ̀ni, agbára Ọlọ́run sí àìṣiyèméjì àwọn ènìyàn.
22 Ṣùgbọ́n nísisìyí pa ẹnu rẹ mọ́; ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ mi èyí tí ó ti jade lọ sí ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, àti bákannáà ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ mi èyí tí yíò jade wá ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn, tàbí èyí tí a nṣe ìtumọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ni, títí tí ìwọ yíò fi gba gbogbo ohun tí èmi yíò fi fún àwọn ọmọ ènìyàn ní ìran yìí, àti pé nígbànáà ni a ó fi ohun gbogbo tí ó kù kún un.
23 Kíyèsíi ìwọ ni Hyrum, ọmọ mi; lépa ìjọba Ọlọ́run, ohun gbogbo ni a ó sì fi kún un gẹ́gẹ́bí èyìínì tí ó tọ́.
24 Kọ́ sí orí àpáta mi, èyí tí ṣe ìhìnrere mi.
25 Má ṣe sẹ́ ẹ̀mí ìfihàn, tàbí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, nítorí ègbé ni fún ẹnití ó bá sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí.
26 Nítorínáà, fi pamọ́ sí inú ọkàn rẹ títí di ìgbà náà tí, nínú ọgbọ́n mi, ìwọ yíò fi jáde lọ.
27 Kíyèsíi, èmi nsọ̀rọ̀ sí gbogbo ènìyàn tí ó ní ìfẹ́ inú rere, tí wọn sì ti fi dòjé wọn láti kórè.
28 Kíyèsíi, èmi ni Jésu Krísti, Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ìyè àti ìmọ́lẹ̀ ayé.
29 Èmi kannáà ni ẹnití ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi tí àwọn tèmi kò sì gbà mí;
30 Ṣùgbọ́n lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà mi, àwọn náà ni èmi yíò fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run, àní fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú orúkọ mi. Amin.