Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 132


Ìpín 132

Ìfihàn tí a fifúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Nauvoo, Illinois, tí a kọ sílẹ̀ 12 Oṣù Keje 1843, tí ó jẹmọ́ májẹ̀mú titun àti àìlópin, pẹ̀lú jíjẹ́ ayérayé ti májẹ̀mú ìgbéyàwó àti ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ níní ìyàwó ju ẹyọ kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfihàn náà jẹ́ kíkọ sílẹ̀ ní 1843, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ díẹ̀ tí wọ́n fi ara hàn nínú ìfihàn yìí ti jẹ́ mímọ̀ nípasẹ̀ Wòlíì láti 1831. Wo Ìkéde Lábẹ́ Àsẹ 1.

1–6, Ìgbéga ológo ni a lè jèrè nípasẹ̀ májẹ̀mú titun àti àìlópin; 7–14, Àwọn ìlànà àti àwọn àjọsọ májẹ̀mú náà ni a gbé kalẹ̀; 15–20, Ìgbéyàwó sẹ̀lẹ́stíà àti wíwà papọ̀ ẹbí títílọ fi agbára fún àwọn ènìyàn láti di ọlọ́run; 21–25, Ọ̀nà híhá àti tóóró ndarí sí ìyè ayérayé; 26–27, A fi òfin fúnni nípa sísọ ọ̀rọ̀ àìtọ́ tako Ẹ̀mí Mímọ́; 28–39, Àwọn ìlérí ti pípọ̀síi àti ìgbéga ológo ti ayérayé ni a ṣe fún àwọn wòlíì àti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní gbogbo àwọn ìgbà; 40–47, Joseph Smith ni a fún ní agbára láti dè àti láti fi èdídí dì ni ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run; 48–50, Olúwa fi èdídí di ìgbéga ológo tirẹ̀ sí orí rẹ̀; 51–57, Emma Smith ni a gbà ní ìmọràn láti jẹ́ olõtọ́ àti ẹni tí ó ṣe é gbọ́kànlé; 58–66, Àwọn òfin tí ó nṣe àkóso ìgbéyàwó ju ẹyọkan lọ ni a gbé kalẹ̀.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún ìwọ ìránṣẹ́ mi Joseph, pé níwọ̀nbí ìwọ ṣe béèrè lọ́wọ́ mi láti mọ̀ àti ní òye báwo ni èmi, Olúwa, ṣe dá àwọn ìránṣẹ́ mi láre Ábrahamù, Ìsaakì, àti Jákọbù, àti bákannáà Mósè, Dáfídì àti Sólómonì, àwọn ìránṣẹ́ mi, nípa ti ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ àti ẹ̀kọ́ níní àwọn ìyàwó púpọ̀ àti àwọn àlè—

2 Kíyèsíi, sì wòó, èmi ní Olúwa Ọlọ́run rẹ, èmi yíò sì dá ọ lóhùn nípa ọ̀rọ̀ yìí.

3 Nítorínáà, pèsè ọkàn rẹ sílẹ̀ láti gbà àti láti gbọ́ràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà èyítí èmi ṣetán láti fifún ọ; nítórí gbogbo àwọn wọnnì tí a fi òfin yìí hàn sí ni wọn gbọdọ̀ gbọ́ràn sí òun kannáà.

4 Nítorí kíyèsíi, èmi fi májẹ̀mú titun àti àìlópin kan hàn sí yín; bí ẹ̀yin kò bá sì dúró nínú májẹ̀mú náà, nígbànáà ẹyin di dídálẹ́bi; nítorí kò sí ẹnití ó le kọ májẹ̀mú yìí tí a ó sì gbà láàyè láti wọlé sínú ògo mi.

5 Nítorí gbogbo ẹnití ó bá fẹ́ ìbùkún kan ní ọwọ́ mi yíò dúró nínú òfin náà èyítí a ti yàn fún ìbùkún náà, àti àwọn àjọsọ ibẹ̀, bí a ṣe fi kalẹ̀ láti ìṣaájú ìpìlẹ̀sẹ̀ ayé.

6 Bí ó sì ti jẹ mọ́ májẹ̀mú titun àti àìlópin, a gbé e kalẹ̀ fún ẹ̀kún ògo mi; ẹnití ó bá sì gba ẹ̀kún ti ibẹ̀ gbọdọ̀ àti níláti wà nínú òfin náà, tàbí oun yíò di dídá lẹ́bi, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

7 Àti pé lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé àwọn àjọsọ ti òfin yìí ni ìwọ̀nyí: Gbogbo àwọn májẹ̀mú, àwọn àdéhùn, àwọn ìbáṣepọ̀, àwọn ojúṣe, àwọn ìbúra, àwọn ìlérí, àwọn ìṣe, àwọn ìfarakọ́ra, àwọn ẹgbẹ́, tàbí àwọn àfojúsọ́nà, èyí tí a kò ṣe kí a sì wọ inú rẹ̀ àti kí a fi èdídí dì nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí, lati ọwọ́ ẹni náà tí a fi òróró yàn, méjéjì bẹ́ẹ̀ fún àkókò yìí àti fún gbogbo ayérayé, àti pé èyí pẹ̀lú jẹ́ mímọ́ jùlọ, nípa ìfihàn àti àṣẹ nípasẹ̀ àrinà ti ẹni àmì òróró mi, ẹnití èmi ti yàn ní orí ilẹ̀ ayé láti di agbára yìí mú (èmi sì ti yan sí ìránṣẹ́ mi Joseph láti di agbára yìí mú ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, kò sì tíì sí ju ẹyọ ẹnìkan lọ rí láé ní orí ilẹ̀ ayé ní àkókò kan ní orí ẹnití a fi agbára àti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlúfã yìí lé), wọn kì yíò ní agbára, ìwà rere, tàbí ipá nínú àti lẹ́hìn àjínde kúrò ninú òkú; nítorí gbogbo àwọn àdéhùn tí a kò ṣe sínú òpin yí ni wọ́n ní òpin nígbàtí àwọn ènìyàn bá kú.

8 Kíyèsíi, ilé ti èmi jẹ́ ilé ètò, ni Olúwa Ọlọ́run wí, kìí sì ṣe ilé ìdàrúdàpọ̀ kan.

9 Njẹ́ èmi yíò ha gba ẹbọ-ọrẹ kan, ni Olúwa wí, tí a ko ṣe ní orúkọ mi?

10 Tàbí njẹ́ èmi yíò ha gbàá ní ọwọ́ yín èyíinì tí èmi kò yàn?

11 Njẹ́ èmi yíò ha sì yàn fún yín, ni Olúwa wí, bíkòṣe pé ó jẹ́ nípa òfin, àní bí èmi àti Bàbá mi ṣe yàn fún yín, ṣaájú kí ayé ó tó wà?

12 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín; èmi sì fi òfin yìí fún yín—pé ẹnikẹ́ni kì yíò wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá bíkòṣe nípasẹ̀ mi tàbí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, èyítí í ṣe òfin mi, ni Olúwa wí.

13 Àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ayé, bóyá ó jẹ́ yíyàn láti ọwọ́ ènìyàn, nípasẹ̀ àwọn ìtẹ́, tàbí àwọn ilẹ̀ ọba, tàbí àwọn agbára, tàbí àwọn ohun ti ó ní orúkọ, ohunkóhun tí wọ́n lè jẹ́, tí wọn kìí ṣe nípasẹ̀ mi tàbí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, ni Olúwa wí, ni a ó bì lulẹ̀, kì yíò sì dúró lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn bá kú, bóyá nínú tàbí lẹ́hìn àjínde, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

14 Nítorí èyíkéyìí àwọn ohun tí ó bá ṣẹkù jẹ́ nípasẹ̀ mi; àti èyíkéyìí àwọn ohun tí wọn kìí ṣe nípasẹ̀ mi ni a ó mì tìtì tí a ó sì parun.

15 Nítorínáà, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ ìyàwó fún ara rẹ̀ nínú ayé, tí kò sì fẹ́ ẹ nípasẹ̀ mi tàbí nipasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, àti tí ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ̀ níwọ̀n bí òun ti pẹ́ tó ní ayé àti obìnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mú àti ìgbéyàwó wọn kò ní agbára nígbàtí wọ́n bá kú, àti nígbàtí wọ́n bá jade kúrò ní ayé; nítorínáà, wọn kò ní àsopọ̀ nípa òfin kankan nígbàtí wọn bá jade kúrò ní ayé.

16 Nitorínáà, nígbàtí wọ́n bá jade kúrò ní ayé wọn kì yíò gbéyàwó tàbí kí á fi fúnni ní ìgbéyàwó; ṣùgbọ́n yíyàn bí àwọn ángẹ́lì ní ọ̀run, àwọn ángẹ́lì tí wọ́n njíṣẹ́ ìránṣẹ́, láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn wọnnì tí a kàyẹ fún ògo tí ó pọ̀ rékọjá, àti tí ó tayọ, tí ó sì ní ìwúwo ayérayé.

17 Nítorí àwọn ángẹ́ì wọ̀nyìí kò dúró nínú òfin mi; nítorínáà, a kì yíò lè mú wọn gbòrò, ṣùgbọ́n wọn yío dúró ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, láì ní ìgbéga, ní ipò ìgbalà wọn, dé gbogbo ayérayé; àti láti ìgbà náà lọ wọn kìí ṣe ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run láé àti títí láé.

18 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ ìyàwó kan, tí òun sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ̀ fún àkókò yìí àti fún gbogbo ayérayé, bí májẹ̀mú náà kò bá jẹ́ nípasẹ̀ mi tàbí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, èyítí í ṣe òfin mi, àti tí kò jẹ́ fífi èdídí dì nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí, nípa ẹni náà tí èmi ti ta òróró sí tí mo sì ti yàn sí agbára yìí, nígbànáà kò jẹ́ àmúyẹ tàbí ní agbára nígbàtí wọ́n bá jade nínú ayé, nítorítí a kò so wọ́n pọ̀ nípasẹ̀ mi, ni Olúwa wí; tàbí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, nígbàtí wọ́n bá jade nínú ayé wọn kì yíò lè gbàá níbẹ̀, nítorípé àwọn ángẹ́lì àti àwọn ọlọ́run ni a nyàn níbẹ̀, nípasẹ̀ ẹniti wọn kì yíò lè kọjá; wọn kò lè, nítorínàà, jogún ògo mi; nítorí ilé mi jẹ́ ilé ti ètò, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

19 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ ìyàwó kan nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, èyítí í ṣe òfin mi, àti nípasẹ̀ májẹ̀mú titun àti àìlópin, tí a sì fi èdídí dìí sí wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí, nípasẹ̀ ẹni náà tí a ta òróró sí, fún ẹnití èmi ti yan agbára yìí àti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà yìí; a ó sì wí fún wọn—Ẹ̀yin yíò jade wá ní àjínde èkínní; àti bí ó bá jẹ́ lẹ́hìn àjínde èkínní, ní àjínde èyí tí ó tẹ̀lée; ẹ̀yin yíò sì jogún àwọn ìtẹ́, àwọn ìjọba, àwọn ilẹ̀ ọba, àti àwọn agbára, àwọn ilẹ̀ ọlọ́lá, gbogbo àwọn ibi gígá àti àwọn ibi jíjìn—nígbànáà ni a ó kọọ́ sínú Ìwé Ìyè ti Ọdọ́ Àgùtàn, pé òun kì yíò pànìyàn nípasẹ̀ títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, bí ẹ̀yin bá sì dúró nínú májẹ̀mú mi tí ẹ kò sì pànìyàn nípasẹ̀ títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn nínú ohun gbogbo èyíkéyìí tí ìránṣẹ́ mi ti gbé lé wọn lọ́wọ́, ní àkókò yìí, àti la gbogbo ayérayé já; ipá rẹ̀ yíò sì jẹ́ kíkún nígbàtí wọn bá jade nínú ayé; wọn yíò sì kọjá nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì, àti àwọn ọlọ́run, èyítí a fi síbẹ̀, sí ìgbéga àti ògo wọn nínú ohun gbogbo, bí a ṣe fi èdídí dìí sí orí wọn, ògo èyítí yíò jẹ́ ẹ̀kún àti títẹ̀síwájù ti àwọn ìrú ọmọ láé àti títí láé.

20 Nígbànáà ni wọn yíò jẹ́ àwọn ọlọ́run, nítorítí wọn kò ní òpin; nítorínáà ni wọ́n yíò wà láti àìlópin dé àìlópin, nítorítí wọ́n wà títí lọ; nígbànáà ní wọn yíò wà ní orí ohun gbogbo, nítorítí ohun gbogbo wà ní ìkáwọ́ wọn. Nígbànáà ni wọn yíò jẹ́ àwọn ọlọ́run, nítorítí wọ́n ní gbogbo agbára, àwọn ángẹ́lì sì wà ní ìkáwọ́ wọn.

21 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, bíkòṣe pé ẹ̀yin dúró nínú òfin mi ẹ̀yin kì yíò lè gba ògo yìí.

22 Nítorí híhá ni ẹnu ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú-ọ̀nà tí ó lọ sí ìgbéga àti ìtẹ̀síwájú àwọn ìgbé ayé, díẹ̀ sì ni àwọn tí wọn wá a rí, nítorítí ẹ̀yin kò gbà mí nínú ayé bẹ́ẹ̀ni ẹ̀yin kò mọ̀ mí.

23 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá gbà mí nínú ayé, nígbànáà ni ẹ̀yin yíò mọ̀ mí, ẹ̀yin yíò sì gba ìgbéga yín pé ní ibití èmi gbé wà kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ bákannáà.

24 Èyí ni àwọn ìyè ayérayé—láti mọ Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n àti tòótọ́ kanṣoṣo, àti Jésù Krístì, ẹnití òun ti rán. Èmi ni ẹni náà. Nítorínáà, ẹ gbà òfin mi.

25 Gbòòrò ni ẹnu ọ̀nà náà, fífẹ̀ sì ni ọ̀nà tí ó lọ sí àwọn ikú; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọ́n tí wọ́n nwọlé sí ibẹ̀, nítorítí wọn kò gbà mí, bẹ́ẹ̀ni wọn kò dúró nínú òfin mi.

26 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ ìyàwó kan ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ mi, tí a sì fi èdídí dì wọ́n nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìlérí, ní ìbámu sí àṣẹ mi, àti tí ọkùnrin tàbí obìnrin yìí dá èyíkéyìí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìrékọjá ti májẹ̀mú titun àti àìlópin nínú ohunkóhun, àti gbogbo onírúurú àwọn ìwa ìsọ̀rọ̀ òdì sí ohun mímọ́, bí wọn kò bá sì dá ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn nípasẹ̀ títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, síbẹ̀ wọn yíò jade wá ní àjínde ìkínní, wọ́n yío sì wọlé sínú ìgbéga wọn; ṣùgbọ́n a ó pa wọ́n run nínú ara, a ó sì jọ̀wọ́ wọn fún ìjẹníyà ti Sátánì títí di ọjọ́ ìràpadà, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

27 Ọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí kì yíò jẹ́ dídáríjì nínú ayé tàbí ní òde ayé, wà nínú dídá ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn nínú èyítí ẹ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, àti tí ẹ̀yin fi ọwọ́ sí ikú mi, lẹ́hìn tí ẹ̀yin ti gba májẹ̀mú titun àti àìlópin mi, ni Olúwa Ọlọ́run wí; ẹnití kò bá sì dúró nínú òfin yìí kì yíò lè wọlé sínú ògo mi bí ó ti wù kí ó rí, ṣùgbọ́n a ó fi gégũn, ni Olúwa wí.

28 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, èmi yíò sì fún ọ ní òfin ti Oyè Àlùfáà Mímọ́ mi, bí èmi àti Bàbá mi ṣe yàn án saájú kí ayé ó tó wà.

29 Ábráhámù gba ohun gbogbo, èyíkéyìí tí òun gbà, nípasẹ̀ ìfihàn àti àṣẹ, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, ni Olúwa wí, òun sì ti wọlé sínú ìgbéga rẹ̀ ó sì jókòó sí orí ìtẹ́ rẹ̀.

30 Ábráhámù gba àwọn ìlérí nípa irú ọmọ rẹ̀, àti irú ọmọ inú rẹ̀—láti inú ẹnití ìwọ ti wá, ní dídárúkọ, ìránṣẹ́ mi Joseph—èyítí yíó tẹ̀síwájú níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà nínú ayé; àti nípa Ábráhámù àti irú ọmọ rẹ̀, ní ode ayé wọn yíò tẹ̀síwájú; nínú ayé àti ní ode ayé ni wọn yíò tẹ̀síwájú ní àìní ònkà bíi àwọn ìràwọ̀; tàbí, bí ìwọ bá ka ìyanrìn ní etí òkùn tí ìwọ kì yíò sì lè kà iye wọn.

31 Ìlérí yìí jẹ́ tiyín pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti Ábráhámù, ìlérí yìí ni a sì ṣe fún Ábráhámù; àti nípasẹ̀ òfin yìí ni títẹ̀síwajú ti àwọn iṣẹ́ Bàbá mi, nípasẹ̀ èyí ti òun ṣe ara rẹ̀ logo.

32 Ẹ lọ, nítorínáà, kí ẹ sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti Ábráhámù; ẹ wọlé sínú òfin mi a ó sì gbà yín là.

33 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá wọlé sínú òfin mi ẹ̀yin kì yíò lè gba ìlérí ti Bàbá mi, èyítí òun ṣe fún Ábráhámù.

34 Ọlọ́run pàṣẹ fún Ábráhámù, Sáraì sì fi Hágárì fún Ábráhámù lati fẹ́ ní ìyàwó. Kínni ìdí rẹ̀ tí òun fi ṣe é? Nítorítí èyí ni òfin; àti láti ọ̀dọ̀ Hágárì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn dìde. Èyí, nítorínáà, nṣe ìmúṣẹ, lààrin àwọn ohun míràn, àwọn ìlérí náà.

35 Njẹ́ Ábráhámù, nígbànáà, wà lábẹ́ ìdálẹ́bi? Lõtọ́ ni mo wí fún yín, Rárá; nítorí èmi, Olúwa, pàṣẹ̀ rẹ̀.

36 Ábráhámù ni a pàṣẹ fún láti fi ọmọ rẹ̀ Isákì rúbọ; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti kọọ́: Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn. Ábráhámù, bí ó ti wù kí ó rí, kò kọ̀, a sì kàá fún un sí ìṣòdodo.

37 Àbráhámù gba àwọn àlè, wọ́n sì bí àwọn ọmọ fún un; a sì kàá fún un sí ìṣòdodo, nítorítí a fi wọ́n fún un, òun sì dúró nínú òfin mi; bí Ísákì pẹ̀lú àti Jákọ́bù kò ṣe ṣe àwọn ohun míràn bíkòṣe èyítí a pàṣẹ fún wọn; àti nítorítí wọn kò ṣe àwọn ohun míràn bíkòṣe èyítí a pàṣẹ fún wọn, wọ́n ti wọlé sínú ìgbéga wọn, gẹ́gẹ́bí àwọn ìlérí, wọ́n sì jókòó ní orí àwọn ìtẹ́, wọn kìí sìí ṣe àwọn ángẹ́lì ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ ọlọ́run.

38 Dáfídì pẹ̀lú gba àwọn ìyàwó púpọ̀ àti àwọn àlè, àti bákannáà Solomónì àti Mósè àwọn ìránṣẹ́ mi, bíi ti àwọn ìránṣẹ́ mí púpọ̀ míràn bákannáà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá títí di àkókò yìí; wọn kò sì dẹ́ṣẹ̀ nínú ohun kan bíkòṣe nínú àwọn ohun wọnnì èyítí wọ́n kò gbà láti ọ̀dọ̀ mi.

39 Àwọn ìyàwó àti àwọn àlè Dáfídì ni a fi fún un nípasẹ̀ mi, láti ọwọ́ Nátánì, ìránṣẹ́ mi, àti àwọn wòlíì míràn tí wọ́n ní àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára yìí; òun kò sì dẹ́ṣẹ̀ sími nínú ọ̀kankan àwọn ohun wọ̀nyìí bíkòṣe nínú ọ̀rọ̀ Ùríayà àti ìyàwó rẹ̀; àti, nítorínáà òun ti ṣubú kúrò ní ìgbéga rẹ̀, òun sì gba ìpín rẹ̀; òun kì yíò sì jogún wọn kọjá òde ayé, nítorí èmi ti fi wọ́n fún ẹlòmíràn, ni Olúwa wí.

40 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, èmi sì fi fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, ipò iṣẹ́ kan, mo sì mú ohun gbogbo padàbọ̀ sípò. Béèrè ohun tí o fẹ́, a ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi.

41 Bí ìwọ sì ti béèrè nípa ìwà panságà, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, bí ọkùnrin kan bá gba ìyàwó nínú májẹ́mú titun àti àìlópin, bí òun bá sì wà pẹ̀lú ọkùnrin míràn, tí èmi kò sì yàn fún un nípasẹ̀ àmi òróró mímọ́, ó ti hu ìwà panságà a ó sì paá run.

42 Bí òun kò bá sí nínú májẹ̀mú titun àti àìlópin, tí òun sì wà pẹ̀lú ọkùnrin míràn, òun ti hu ìwà panságà.

43 Àti bí ọkọ rẹ̀ bá wà pẹ̀lú obìnrin míràn, tí òun sì wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ kan, òun ti sẹ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ó sì ti hu ìwà panságà.

44 Àti bí obìnrin náà kò bá hu ìwà panságà, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀ àti tí kò sẹ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀, tí òun sì mọ̀ èyí, tí èmi sì fi èyí hàn sí ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, nígbànáà ni ìwọ yíò ní agbára, nípasẹ̀ agbára ti Oyè Àlùfáà Mímọ́ mi, láti mú òun kí o sì fi í fún ọkùnrin èyí tí kò hu ìwà panságà ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ olõtọ́; nítorí a ó fi òun ṣe alákóso ní orí ọ̀pọ̀lọpọ̀.

45 Nítorí mo ti fún ọ ní àwọn kọ́kọ́rọ́ àti agbára oyè àlùfáà náà, nípasẹ̀ èyí tí mo mú ohun gbogbo padàbọ̀ sípò, àti tí mo sọ ohun gbogbo di mímọ̀ sí ọ ní àkókò tí ó tọ́.

46 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo sì wí fún ọ, pé ohunkóhun tí ìwọ̀ bá fi èdídí dì ní ilẹ̀ ayé ni a ó fi èdídí dì ní ọ̀run; àti ohunkóhun tí ìwọ bá dè ní ilẹ̀ ayé, ní orúkọ mi àti nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, ní Olúwa wí, òun yíò jẹ́ dídè fún ayérayé nínú àwọn ọ̀run; àti ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá fi jì ní ilẹ̀ ayé ni yíò jẹ́ fífijì fún ayérayé nínú àwọn ọ̀run; àti ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá dìmú ní ilẹ̀ ayé yíó jẹ́ dídìmú ni ọ̀run.

47 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí, ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá bùkún ni èmi yíò bùkún, àti ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá fi bú ni èmi yíò fi bú, ni Olúwa wí; nítorí èmi, Olúwa, èmi ni Ọlọ́run rẹ.

48 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, pé ohunkóhun tí ìwọ bá fúnni ní ilẹ̀ ayé, àti ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá fi èyíkéyìí fún ní ilẹ̀ ayé, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi àti gẹ́gẹ́bí òfin mi, èyí ni a ó bẹ̀wò pẹ̀lú àwọn ìbùkún kìí sìí ṣe àwọn ìfibú, àti pẹ̀lú agbára mi, ni Olúwa wí, yíò sì jẹ́ láì ní ìdálẹ́bi ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run.

49 Nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, èmi yíò sì wà pẹ́lú rẹ àní títí dé òpin ayé, àti títí gbogbo ayérayé; nítorí lõtọ́ èmi fi èdídí di ìgbéga rẹ sí orí rẹ, mo sì pèsè ìtẹ́ kan fún ọ nínú ìjọba Bàbá mi, pẹ̀lú Ábráhámù bàbá rẹ.

50 Kíyèsíi, èmi ti rí àwọn ẹbọ rẹ, èmi yíò sì ṣe ìdáríjì gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ; èmi ti rí àwọn ẹbọ rẹ ní ìgbọ́ràn sí èyíinì tí èmi ti wí fún ọ. Lọ, nítorínáà, èmi sì ti ṣe ọ̀nà kan fún àbáyọ rẹ, bí mo ṣe gba ẹbọ-ọrẹ Ábráhámù ti ọmọ rẹ̀ Ísákì.

51 Lõtọ́, ni mo wí fún ọ: Òfin kan ni mo fi fún ìránṣẹ́-bìnrin mi, Emma Smith, ìyawó rẹ, ẹnití èmi ti fi fún ọ, pé kí òun ó dá ara rẹ̀ dúró àti kí ó máṣe kópa nínú èyíti mo pàṣẹ fún ọ láti ṣe fún òun; nítorí èmi ti ṣe é, ni Olúwa wí, láti dán gbogbo yín wò, bí mo ti ṣe sí Ábráhámù, àti pé kí èmi ó lè béèrè ẹbọ-ọrẹ kan ní ọwọ́ rẹ, nípasẹ̀ májẹ̀mú àti ẹbọ.

52 Sì jẹ́kí ìránṣẹ́-binrin mi, Emma Smith, ó gba gbogbo àwọn wọnnì tí a ti fi fún ìránṣẹ́ mi Joseph, àti tí wọ́n jẹ́ oníwà rere àti àìlẽrí níwájú mi; àti àwọn wọnnì tí wọn jẹ́ elẽrí, tí wọ́n sì ti sọ pé àwọn jẹ́ aláìlẽrí, ni a ó parun, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

53 Nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ yíò sì gbọ́ràn sí ohùn mi; èmi sì fi fún ìránṣẹ́ mi Joseph pé a ó sọ òun di alákóso ní orí àwọn ohun púpọ̀; nítorí òun ti jẹ́ olõtọ́ ní orí àwọn ohun díẹ̀, àti láti ìsisìyí lọ èmi yíò fún un ní okun.

54 Mo sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́-bìnrin mi, Emma Smith, láti dúró tì àti fi ara mọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph, kìí sìí ṣe sí ẹnikẹ́ni míràn. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá dúró nínú òfin yìí a ó pa á run, ni Olúwa wí; nítorí èmi ni Oluwa Ọlọ́run rẹ, èmi yíò sì pa á run bí òun kò bá dúró nínú òfin mi.

55 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá dúró nínú òfin yìí, nígbànáà ni ìránṣẹ́ mi Joseph yíò ṣe ohun bogbo fún un, àní bí òun ṣe wí tẹ́lẹ̀; èmi ó sì bùkún fún un èmi o sì mú kí oun di púpọ̀ síi àti fún un ní ìlọ́po ọgọ́rũn nínú ayé yìí, ti àwọn bàbá àti àwọn ìyá, àwọn arakùnrin àti àwọn arabìnrin, àwọn ilé àti àwọn ilẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ, àwọn adé ti ìye ayérayé nínú àwọn ayé ayérayé.

56 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí, kí ìránṣẹ́-bìnrin mi dárí jì ìránṣẹ́ mi Joseph àwọn ìrékọjá rẹ̀; àti nígbànáà ni a ó dárí àwọn ìrékọjá tirẹ̀ jì í, nípasẹ̀ èyí tí òun ti dẹ́ṣẹ̀ símí; àti pé èmi, Olúwa Ọlọ́run rẹ, yíò bùkún fún un, yíó sì mú kí ó di púpọ̀ síi, yíó sì mú kí ọkàn rẹ̀ kí ó yọ̀.

57 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí, kí ìránṣẹ́ mi Joseph kí ó máṣe fi àwọn ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀kọ́ kí ọ̀tá kan má wá kí ó sì pa á run; nítorí Sátánì ndọdẹ láti parun; nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun sì jẹ́ ìránṣẹ́ mi; sì kíyèsíi, sì wòó, èmi wà pẹ̀lú rẹ̀, bí èmi ṣe wà pẹ̀lú Ábráhámù, baba rẹ, àní sí ìgbéga àti ògo rẹ̀.

58 Nísisìyí, nípa òfin ti oyè àlùfáà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan wà tí ó jẹ mọ́ ọ.

59 Lõtọ́, bí a bá pe ọkùnrin kan nípasẹ̀ Bàbá mi, bíi ti Áárónì, nípasẹ̀ ohùn mi, àti nípa ohùn ti ẹni náà tí ó rán mi, èmi sì ti bùn un ní ẹ̀bun ti àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára ti oyè àlùfáà yìí, bí òun bá ṣe ohunkóhun ní orúkọ mi, àti gẹ́gẹ́bí òfin mi àti nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, òun kì yíò dẹ́ṣẹ̀, èmi yíò sì dáa láre.

60 Ẹ máṣe jẹ́kí ẹnikẹ́ni, nítorínáà, ṣe òfintótó ìránṣẹ́ mi Joseph; nítorí èmi yíò dáa láre; nítorí òun yíò rú ẹbọ èyítí mo béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún àwọn ìrékọjá rẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí.

61 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, bí ó ṣe jẹ mọ́ òfin ti oyè àlùfáà—bí ẹnikan bá fẹ́ wúndíá kan ní ìyàwó, àti tí ó sì ní ìfẹ́ láti fẹ́ òmíràn, àti tí àkọ́kọ́ fun un ní ìyọ̃da rẹ̀, bí òun bá sì fẹ́ èkejì, tí wọ́n sì jẹ́ wúndíá, àti tí wọ́n kò jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí ọ̀kùnrin míràn, nígbànáà ni a dáa láre; òun kò lè dá ẹ̀ṣẹ̀ ìwà panságà nítorí a fi wọ́n fún un; nítorí òun kò lè dá ẹ̀ṣẹ̀ panságà pẹ̀lú èyíinì tí ó jẹ́ tirẹ̀ àti tí kìí ṣe ti ẹnikẹ́ni míràn.

62 Bí òun bá sì ní àwọn wúndíá mẹ́wã tí a fi fún un nípasẹ̀ òfin yìí, òun kì yíò dá ẹ̀ṣẹ̀ panságà, nítorí wọ́n jẹ́ tirẹ̀, a sì ti fi wọ́n fún un; nítorínáà òun gba ìdáláre.

63 Ṣùgbọ́n bí ọ̀kan tàbí òmíràn nínú àwọn wúndíá mẹwã náà, lẹ́hìn tí a fẹ́ ẹ bí ìyàwó, bá wà pẹ̀lú ọkùnrin míràn, òun ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panságà, a ó sì paárun; nítorí a fi wọ́n fún un kí wọn ó le di púpọ̀ síi kí wọn ó sì gbilẹ̀ ní ayé, gẹ́gẹ́bí òfin mi, àti láti mú ìlérí ṣẹ èyítí a fifúnmi nípasẹ̀ Bàbá mi saájú ìpilẹ̀ ayé, àti fún ìgbéga wọn nínú àwọn ayérayé, kí wọ́n ó lè bí àwọn ẹ̀mí ènìyàn; nítorí nínú èyí ni iṣẹ́ Bàbá mi tẹ̀síwájú, kí á lè ṣe òun logo.

64 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnikan bá ní ìyàwó kan, ẹnití ó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára yìí, tí òun sì kọ́ ọ ní òfin ti oyè àlùfáà mi, bí ó ṣe jẹ mọ́ àwọn nkan wọ̀nyìí, nígbànáà ni obìnrin náà yíò gbàgbọ́ yío sì mójútó òun, tàbí a ó paárun, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí; nítorí èmi yíò pa á run; nítorí èmi yíò gbe orúkọ mi ga ní orí gbogbo àwọn wọnnì tí ó gba àti dúró nínú òfin mi.

65 Nítorínáà, yíò bá òfin mu nínú mi, bí obìnrin náà kò bá gba òfin yìí, fún ọkùnrin láti gba gbogbo ohunkóhun tí èmi, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, yíò fi fún un, nítorítí òbinrin náà kò gbàgbọ́ tí kò sì mójútó o gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi; àti nígbànáà obìnrin náà di arúfin; a sì dá ọkùnrin náà sí lọ́wọ́ òfin ti Sáráì, ẹnití ó ṣe àmójútó Ábráhámù gẹ́gẹ́bí òfin nígbàtí mo pàṣẹ fún Ábráhámù láti mú Hágárì bí ìyàwó.

66 Àti nísisìyí, bí ó ṣe jẹ mọ́ òfin yìí, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, èmi yíò fi púpọ̀ hàn síi fún ọ, lẹ́hìnwá; nítorínáà, jẹ́kí èyí tó fún àkókò yìí. Kíyèsíi, èmi ni Álfà àti Òmégà. Àmín.