Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45


Ìpín 45

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí ìjọ, ní Kirtland, Ohio, 7 Oṣù Kejì 1831. Ní kíkọ ọ̀rọ̀ ìṣaájú sí àkọ̀sílẹ̀ fún ìfihàn yìí, Ìtàn ti Joseph Smith sọ pé “ní àkókò yìí fún ìjọ …ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ìrohìn tí kìí ṣe òtítọ́…àti àwọn ìtan òmùgọ̀, ní wọ́n di títẹ̀ jade…tí wọn sì npín káàkiri,… láti dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ní ṣíṣe ìwádìí iṣẹ́ náà, tàbí láti gba ìgbàgbọ́ náà mọ́ra…. Ṣùgbọ́n sí ayọ̀ àwọn Enìyàn Mímọ́,… mo gba àwọn nkan tí ó tẹ̀lé wọ̀nyí.”

1–5, Krístì ni alágbàwí wa pẹ̀lú Bàbá; 6–10, Ìhìnrere jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti tún ọ̀nà ṣe níwájú Olúwa; 11–15, Enọkù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ni Olúwa gbà sí ọ̀dọ̀ òun Tìkára Rẹ̀; 16–23, Krístì sọ àwọn àmì bíbọ̀ Rẹ̀ di mímọ̀ bí a ṣe fí fúnni ní orí Òkè Ólífì; 24–38, Ìhìnrere ni a ó mú padàbọ̀ sípò, àkókò àwọn Kèfèrí yíò sì kún, àti pé àìsàn ìsọdahoro yíò bo orí ilẹ̀; 39–47, Àwọn àmì, àwọn ìyanu, àti Àjínde yíò wà pẹ̀lú Bíbọ̀ Ẹ̀kejì; 48–53, Krístì yíò dúró ní orí Òkè Ólífì, àti pé àwọn Júù yíò rí àpá ní àwọn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Rẹ̀; 54–59, Olúwa yíò jọba ní àkókò Ẹgbẹ̀rún ọdún; 60–62, A fún Wòlíì ní ẹ̀kọ́ láti bẹ̀rẹ̀ itúmọ̀ Májẹ̀mú Titun, nípasẹ̀ èyítí a ó sọ ìwífúnni pàtàkì di mímọ̀; 63–75, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a pa láṣẹ lati kó ara wọn jọ kí wọ́n ó sì kọ́ Jerúsálẹmù Titun, sí èyítí àwọn ènìyàn láti gbogbo orílẹ èdè yíò wá.

1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi, ẹ̀yin ẹnití a ti fi ìjọba fún; ẹ fetísílẹ̀ kí ẹ sì fi etí fún ẹni náà tí Ó fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run àti gbogbo ọ̀wọ́ ogun tí ó wà nínú rẹ̀, àti nípasẹ̀ ẹnití a dá ohun gbogbo tí ó wà láàyè, àti tí ó nrìn, àti tí ó jẹ́ ẹ̀dá.

2 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí pé, ẹ fetísílẹ̀ sí ohùn mi, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ikú yío lée yín bá; ní wákàtí náà tí ẹ̀yin kò rò tẹ́lẹ̀ tí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yíò kọjá, àti tí ìkórè yíó parí, tí a kì yío sì gba ẹ̀mí yín là.

3 Ẹ tẹ́tí sí ẹni náà tí ó jẹ́ alágbàwí pẹ̀lú Bàbá, ẹni tí ó nbẹ̀bẹ̀ fún ọ̀rọ̀ yín níwáju rẹ̀—

4 Wípé: Bàbá, kíyèsí àwọn ìjìyà àti ikú ẹni náà tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan, ẹni náà tí inú rẹ dùn sí gidigidi; kíyèsí ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ èyí tí a ta sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ẹni náà tí ìwọ fi fúnni kí á lè ṣe ìwọ fúnraàrẹ logo;

5 Nítorínáà, Bàbá, dá àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí sí tí wọ́n gbàgbọ́ nínú orúkọ mi, pé kí wọ́n ó lè wá sí ọ̀dọ̀ mi kí wọ́n ó sì ní ìyè àìlópin.

6 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi, àti ẹ̀yin alàgbà ẹ jùmọ̀ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ohùn mi ní ìgbà tí a npè ní òní, kí ẹ má sì ṣe sé ọkàn yín le;

7 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín pé èmi ni Alfà àti Omégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé—ìmọ́lẹ̀ tí ó ntàn nínú òkùnkùn tí òkùnkùn kò sì mọ̀ ọ́.

8 Èmi wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tèmi, àwọn tèmi kò sì gbà mí; ṣùgbọ́n iye àwọn tí wọ́n gba mí ni èmi fi agbára fún láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu, àti láti di ọmọ Ọlọ́run; àti àní àwọn tí wọ́n gba orúkọ mi gbọ́ ni mo fi agbára fún láti gba ìyè ayérayé.

9 Àti àní bẹ́ẹ̀ni èmi ti rán májẹ̀mú ayérayé tèmi sí inú ayé, láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí ayé, àti láti jẹ́ òdiwọ̀n fún àwọn ènìyàn mi, àti fún àwọn Kèfèrí láti lépa rẹ̀, àti láti jẹ́ ìránṣẹ́ níwájú mi láti tún ọ̀nà ṣe níwájú mi.

10 Nítorínáà, ẹ wá sí inú rẹ̀, àti pẹ̀lú ẹní tí ó nbọ̀ ni èmi yíò sọ̀rọ̀ bíi pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ìgbàanì, èmi yíò sì fí ìsọ̀rọ̀ tí ó ní agbára hàn fún yín.

11 Nítorínáà, ẹ fetísílẹ̀ lápapọ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èmi ó fi hàn yín àní ọgbọ́n mi—ọgbọ́n Ẹni náà tí ẹ̀yin sọ pé òun ni Ọlọ́run Enọ́kù, àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

12 Ẹni tí a yà nípa kúrò ní ayé, àti tí a gbà sí ọ̀dọ̀ èmi tìkára mi—ìlú nlá kan tí a fi pamọ́ títí di ọjọ́ tí òdodo yíò dé—ọjọ́ náà èyí tí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ ti wá kiri, àti tí wọn kò sì rí i nítorí ìwa búburú àti àwọn ìwà ìríra;

13 Àti tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò àti arìnrìnàjò ni àwọn jẹ́ ní orí ilẹ̀ ayé;

14 Ṣùgbọ́n wọ́n gba ìlérí kan pé àwọn yíò wáa rí àti pé àwọn yíò ríi nínú ẹran ara àwọn.

15 Nítorínáà, ẹ fetísílẹ̀ èmi yíò sì ṣe àsàrò pẹ̀lú yín, èmi yíò sì báa yín sọ̀rọ̀ àti àsọtẹ́lẹ̀, bíi sí àwọn ènìyàn ní ìgbàanì.

16 Àti pé èmi yíò fi í hàn kedere bí mo ṣe fi í hàn fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi nígbàtí mo dúró níwájú wọn nínú ẹran ara, tí mo sì bá wọ̀n sọ̀rọ̀, wípé: Bí ẹ̀yin ṣe béèrè lọ́wọ́ mi nípa àwọn àmì bíbọ̀ mi, ní ọjọ́ tí èmi yíò dé nínú ògo mi nínú àwọ̀ sánmọ̀, láti mú àwọn ìlérí tí mo ti ṣe fún àwọn bàbá yín ṣẹ,

17 Nítorí bí ẹ̀yin ti ṣe wo àìsí ẹ̀mí yín nínú ara yín fún ìgbà pípẹ́ láti jẹ́ ìdè, èmi yíò fi hàn fún yín bí ọjọ́ ìràpadà yíò ṣe dé, àti bákannáà ìmúpadàbọ̀sípò Israẹlì tí ó ti fọ́nká.

18 Àti nísisìyí ẹ kíyèsí tẹ́mpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù, èyí tí ẹ̀yin npè ní ilé Ọlọ́run, àwọn ọ̀tá yín sì wí pé ilé yìí kì yíò wó láéláé.

19 Ṣùgbọ́n, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ìsọdahoro yíò wá sí orí ìran yìí bíi olè ní òru, a ó sì pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí run a ó sì fọ́n wọn ká lààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo.

20 Àti pé tẹ́mpìlì yìí èyítí ẹ̀yin rí nísisìyí ni a ó wó lulẹ̀ tí a kì yíò sì fi òkúta kan sílẹ̀ tí yíò dúró ní orí òmíràn.

21 Yíò sì ṣe, pé ìran àwọn Júù yìí kì yíò kọjá lọ títí tí olukúlùkù ìsọdahoro èyí tí èmi ti sọ fún yín nípa wọn yíò fi wá sí ìmúṣẹ.

22 Ẹ̀yin wípé ẹ mọ̀ pé òpin ayé dé tán; ẹ̀yin wí bákannáà pé ẹ mọ̀ pé àwọn ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ;

23 Àti nínú èyí ẹ̀yin wí ní tòótọ́, nítorí bẹ́ẹ̀ni ó rí; ṣùgbọ́n àwọn nkan wọ̀nyí tí èmi ti sọ fún yín kì yíò kọjá lọ títí tí ohun gbogbo yíò fi di mímúṣẹ.

24 Àti pé èyí ni èmi ti sọ fún yín nípa Jérúsálẹ́mù; àti nígbàtí ọjọ́ náà yíò dé, ni a ó fọ́n ìyókù káàkiri lààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo;

25 Ṣùgbọ́n a ó kó wọn jọ pọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi; ṣùgbọ́n wọn yíò dúró títí tí àkókò àwọn Kèfèrí yíò fi di mímúṣẹ.

26 Àti ní ọjọ́ náà ni a ó gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìró àwọn ogun, gbogbo ayé yíò sì wà ní ìrúkèrúdò, àti pé àyà àwọn ènìyàn yíò já wọn kulẹ̀, wọn yíò sì wí pé Krístì ti fa bíbọ̀ rẹ̀ sẹ́hìn títí di òpin ilẹ̀ ayé.

27 Àti pé ìfẹ́ àwọn ènìyàn yíò di tútù, ìwà búburú yíò sì di púpọ̀.

28 Àti nígbàtí àkókò àwọn Kèfèrí bá sì dé, ìmọ́lẹ̀ kan yíò tàn wá lààrin àwọn tí wọ́n jókòó nínú òkùnkùn, yíò sì jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi;

29 Ṣùgbọ́n wọn kò gbà á; nítorí wọn kò wòye ìmọ́lẹ̀ náà, wọ́n sì yí ọkàn wọn kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí àwọn ìlànà ti àwọn ènìyàn.

30 Àti pé nínú ìran náà ni àkókò àwọn Kèfèrí yíò di mímúṣẹ.

31 Àwọn ènìyàn yíò sì wà ní ìdúró ní ìran náà, tí wọn kì yíò kọjá lọ títí tí wọn yíò fi rí àkúnwọ́sílẹ̀ ìbáwí; nítórí àìsàn ìsọdahoro yíò gba ilẹ̀ náà.

32 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi yíò dúró ní àwọn ibi mímọ́, a kì yíò sì ṣí wọ́n nípò padà; ṣùgbọ́n lààrin àwọn ènìyàn búburú, àwọn ènìyàn yíò gbé ohùn wọn sókè wọn yíò sì fi Ọlọ́run bú, wọn yíò sì kú.

33 Ilẹ̀ ríri yíò sì wà bákannáà káàkiri ní onírúurú ibi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọdahoro; síbẹ̀ àwọn ènìyàn yíò sé ọkàn wọn le lòdì sí mi, àti pé wọn yíò gbé idà, ọ̀kan sí òmíràn, wọn yíò sì pa ara wọn.

34 Àti nísisìyí, nígbàtí èmi Olúwa ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi, wọ́n dààmú.

35 Èmi sì wí fún wọn: Ẹ máṣe dààmú, nítorí, nígbàtí gbogbo nkan wọ̀nyí yíó bá ṣe, kí ẹ̀yin kí ó le mọ̀ pé gbogbo ìlérí tí a ṣe fún yín ni yíò di mímúṣẹ.

36 Àti nígbàtí ìmọ́lẹ̀ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn, yíò wà pẹ̀lú wọn bí òwe èyí tí èmi yíò fi hàn yín—

37 Ẹ̀yin ẹ wòó kí ẹ sì kíyèsí àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́, kí ẹ sì rí wọ́n pẹ̀lú ojú yin, ẹ̀yin sì wí pé nígbàtí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí yọ ẹ̀ka jáde, àti tí ewé wọ́n ba sì ṣẹ̀ṣẹ̀ rú, pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti súnmọ́ itòsí.

38 Àní bẹ́ẹ̀ ni yíò rí ní ọjọ́ náà nígbàtí wọn yíò rí àwọn nkan wọ̀nyí, nígbànáà ni wọn yíò mọ̀ pé wákàtí náà súnmọ́ ìtòsí.

39 Yíò sì ṣe pé ẹni tí ó bá bẹ̀rù mi yíò má a fi ojú sọ́nà fún ọjọ́ nlá Olúwa lati dé, àní fún àwọn àmì bíbọ̀ Ọ̀mọ Ènìyàn.

40 Wọn yíò sì rí àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu, nítorí a ó fi hàn wọ́n lókè ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ nísàlẹ̀.

41 Wọn yíò sì rí ẹ̀jẹ̀, àti iná, àti àwọn rírú èéfín.

42 Àti pé ṣaájú kí ọjọ́ Olúwa náà tó dé, a ó sọ òòrùn di òkùnkùn, ati òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, àti àwọn ìràwọ̀ yíò já bọ́ láti ọ̀run.

43 Àwọn ìyókù ni a ó sì kó jọ pọ̀ sí ibí yìí;

44 Àti nígbànáà ni wọn yíò wá mi, àti, kíyèsíi, èmi yíò wá; wọn yíò sì rí mi ninú àwọ sánmọ̀ ti ọ̀run, ní wíwọ̀ ní aṣọ agbára àti ògò nlá; pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹ́lì mímọ́; ẹni tí kò bá sì ṣọ́nà fún mi ni a ó ké kúrò.

45 Ṣùgbọ́n ṣaájú kí apá Olúwa ó tó ṣubú, ángẹ́lì Olúwa kan yíò ti fọn ìpè rẹ̀, àti pé àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n ti sùn yíò jáde wá láti pàdé mi ní àwọ sánmọ̀.

46 Nítorínáà, bí ẹ̀yin bá ti sùn ní àlãfíà alábùkún fún ni ẹ̀yin, nítorí bí ẹ̀yin ṣe wò mí nísisìyí tí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni, àní bẹ́ẹ̀ni ẹ̀yin yíò wá sí ọ̀dọ̀ mi, àwọn ọ̀kàn yín yíò sì yè, àti pé ìgbàlà yín yíò jẹ́ pípé; àwọn ẹni mímọ́ yíò sì jade wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.

47 Nígbànáà ni apá Olúwa yíò ṣubú sí orí àwọn orílẹ̀-èdè.

48 Àti nígbànáà ni Olúwa yíò gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ lé orí òkè yìí, yíò sì pín sí méjì, ilẹ̀ ayé yíò sì wárìrì, yíò sì ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́ síhĩn àti sọ́hũn, àti àwọn ọ̀run pẹ̀lú yíò sì mì.

49 Olúwa yíò sì fọ ohùn rẹ̀, gbogbo òpin ilẹ̀ ayé ni wọn yíò sì gbọ́ ọ; àti pé àwọn orílẹ̀-èdè náà yíò ṣọ̀fọ̀, àwọn tí wọ́n ti rẹ́rĩn yíò sì rí àìmọ̀kan wọn.

50 Àjálú yíò sì bo olùṣe ẹlẹ́yà, àti àwọn ẹlẹ́gàn ni a ó parun; àti àwọn tí wọ́n nṣọ́ àìṣedéédé ni a ó ké kúrò a ó sì kó wọn sínú iná.

51 Àti nígbànáà ni àwọn Júù yíò bojú wò mi wọn yíò sì wí pé: Kíni àwọn ọgbẹ́ tí ó wà ní àwọn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ wọ̀nyí?

52 Nígbànáà ni wọn yíò mọ̀ pé èmi ni Olúwa; nítorí èmi yíò wí fún wọn: Àwọn ọgbẹ́ wọ̀nyí jẹ́ àwọn ọgbẹ́ èyí tí a ti ṣámi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi. Èmi ni ẹni náà tí a gbé sókè. Èmi ni Jésù tí a kàn mọ́ àgbélèbú. Èmi ni Ọmọ Ọlọ́run.

53 Àti nígbànáà ni wọn yíò sì sunkún nítorí àwọn àìṣedéédé wọn; nígbànáà ni wọn yíò pohùnréré ẹkún nítorípé wọ́n ti ṣe inúnibíni Ọba wọn.

54 Àti nígbànáà ni àwọn abọ̀rìṣà orílẹ̀-èdè yío di ríràpadà, àti pé àwọn tí wọn kò mọ òfin yíò nípa nínú àjínde àkọ́kọ́; yíò sì ṣeé faradà fún wọn.

55 A ó sì gbé Sátánì dè, pé kí òun má lè rí ààyè nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn.

56 Àti ní ọjọ́ náà, nígbàtí èmi yíò dé nínú ògo mi, ni òwe náà yíò wá sí ìmúṣẹ èyí tí mo sọ nípa àwọn wúndíá mẹ́wàá.

57 Nítorí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n tí wọ́n sì ti gba òtítọ́, àti tí wọ́n ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe amọ̀nà wọn, tí a kò sì tíì tàn wọ́n jẹ—lõtọ́ ni mo wí fún yín, a kì yíò ké wọn lulẹ̀ kí á sì sọ wọ́n sínú iná, ṣùgbọ́n wọn yíò dúró ní ọjọ́ náà.

58 A ó sì fi ilẹ̀ ayé fún wọn bíi ogún ìní; wọn yíò sì máa pọ̀ síi àti ní agbára síi, àti àwọn ọmọ wọn yíò dàgbà sókè sínú ìgbàlà láì lẹ́ṣẹ̀.

59 Nítorí Olúwa yíò wà ní ààrin wọn, àti ògo rẹ̀ yíò wà ní orí wọn, òun yíò sì jẹ́ ọba wọn àti aṣòfin wọn.

60 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, a kì yíò fi fún ọ láti mọ̀ síwájú síi nípa ìpín yìí, títí tí Májẹ̀mú Titun yíó fi di títúmọ̀, àti nínú rẹ̀ ni a ó sọ gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí di mímọ̀;

61 Nítorínáà èmi fi fún ọ pé ìwọ lè máa túmọ̀ rẹ̀ nísisìyí, kí ìwọ ó lè múrasílẹ̀ fún àwọn ohun tí ó nbọ̀.

62 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún ọ, pé àwọn ohun nlá ndúró dè ọ́;

63 Ẹ̀yin gbọ́ ìró àwọn ogun ní àwọn ilẹ̀ òkẽrè; ṣùgbọ́n, kíyèsíi, mo wí fún yín, wọ́n súnmọ́ itòsí, àní ní àwọn ẹnu ọ̀nà yín, àti pé ní àwọn ọdún tí kò pọ̀ púpọ̀ sí àkókò yìí ẹ̀yin yíò gbọ́ ìró ogun ní àwọn ilẹ̀ tiyín.

64 Nítorínáà èmi, Olúwa, ti wí, ẹ kó ara yín jọ kúrò ní àwọn ilẹ̀ ilà oòrùn, ẹ kó ara yín jọ papọ̀ ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi; ẹ jáde lọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè ìwọ oòrùn, ẹ pe àwọn olùgbé ibẹ̀ lati ronúpìwàdà, àti pé níwọ̀nbí wọ́n bá ronúpìwàdà, ẹ kọ́ àwọn ìjọ fún mi.

65 Àti pẹ̀lú ọkàn kan àti pẹ̀lú inú kan, ẹ kó àwọn ọrọ̀ yín jọ kí ẹ̀yin ó lè ra ogún kan èyi tí a ó yàn fún yín níkẹhìn.

66 A ó sì pè é ní Jérúsálẹ́mù Titun, ilẹ̀ àlãfíà, ìlú nlá ibi ìsádi, ibi ààbò fún àwọn ẹni-mímọ́ ti Ọlọ́run Gíga Jùlọ;

67 Ògo Olúwa yíò sì wà níbẹ̀, àti pé ẹ̀rù Olúwa yíò wà níbẹ̀ bákannáà, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn èníyàn búburú kì yíò wá sí inú rẹ̀, a ó sì pè é ní Síónì.

68 Yíò sì ṣe lààrin àwọn ènìyàn búburú, pé olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá gbé idà rẹ̀ sókè sí aládũgbò rẹ̀ ni ó gbọ́dọ̀ sá lọ sí Síónì fún ààbò.

69 A ó sì kó wọn jọ pọ̀ sí ibẹ̀ láti ọ̀kọ̀ọ̀kan orílẹ̀-èdè ni abẹ́ ọ̀run; wọn yíò sì jẹ́ àwọn ènìyàn kan ṣoṣo tí kì yíò wà ní ogun jíjà ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn.

70 Àti pé àwọn ènìyàn búburú yíó sọ lààrin ara wọn: Ẹ má ṣe jẹ́ kí á lọ sí òkè lati jagun dojú kọ Síónì, nítorí àwọn olùgbé Síónì banilẹ́rù; nítorínáà a kì yíò lè dúró.

71 Yíò sì ṣe pé àwọn olódodo ni a ó kó jọ pọ̀ láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yíò sì wá sí Síónì, ní kíkọ àwọn orin àyọ ayérayé.

72 Àti nísisìyí mo wí fún yín, ẹ pa àwọn nkan wọ̀nyí mọ́ kúrò ní lílọ sí òkèèrè sí àgbáyé títí di ìgbà tí yíò tọ́ ní ojú mi, pé kí ẹ̀yin ó lè ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ yìí ní ojú àwọn èníyàn, àti ní ojú àwọn ọ̀tá yín, pé kí wọn ó má lè mọ àwọn iṣẹ́ yín títí tí ẹ̀yin yíò fi ṣe àṣeyọrí ohun èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín;

73 Pé nígbàtí wọn yíò bá mọ̀ ọ́, kí wọn ó lè gbèrò àwọn nkan wọ̀nyí.

74 Nítorí nígbàtí Olúwa yíò farahàn Òun yíò ní ẹ̀rù fún wọn, kí ẹ̀rù ó lè bà wọn, àti pé wọn yíò dúró sí ibi tí ó jìnnà wọn yíò sì wárìrì.

75 Ẹ̀rù yío sì ba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nítorí ẹ̀rù Olúwa, àti agbára ipá rẹ̀. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.